Iya Ibeji Omo Arayele mú ijó jó bí wọ́n ṣe ṣí ilé àti ṣọ́ọ̀bù tí Pásítọ̀ kọ́ fun n'Ibadan

Iya Ibeji omo arayele

Oríṣun àwòrán, Facebok/Agbala Gabriel Global PAGE

Agba oṣere tiata Yoruba, Adenike Adegboye, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Iya Ibeji omo araye le ti di onile tuntun.

Ile tuntun naa, ti Pasitọ ijọ Agbala Gabriel kọ fun ni wọn ṣajọyọ ṣiṣi rẹ lọjọ Ẹti niluu Ibadan.

Gẹgẹ bii ohun ti pasitọ naa sọ, aarin oṣu kan pere ni wọn kọ ile fun Iya Ibeji.

Eyi lo waye lẹyin ti pasitọ ọhun ati oṣere tiata Yoruba, to tun jẹ oloju aanu, Foluke Daramola da si ọrọ aisan iya ibeji.

Ile ilẹ oniyara mẹta naa lo tun ni yara igbalejo nla ati ile idana.

Awọn ohun meremere to wa ninu ile alarabara naa ree

Yara igbalejo naa si ni wọn ko aga to rẹwa si, ti asọ alarabara si wa loju ferese rẹ, eyi to mu ko rẹwa si.

Ile tuntun naa si ni wọn ti kun ni ọda awọ eeru ati funfun eyi to mu ko rẹwa pupọ.

Bakan naa ni isẹ ti n lọ lati mọ ogiri yika ile naa, ki aabo le wa fun mama agba ọhun.

Geeti onirin ti wọn yoo gbe sẹnu ọna fẹnsi ile ọhun si ti wa nilẹ lati ri ni kete ti mimọ ogiri ọhun ba pari tan.

Koda, wọn ti gbẹ kanga jingodo sinu ile naa, ti wọn si ti fa omi wọ inu ile ọhun ati si ayika ile naa.

Gbogbo eyi si lo wa lati mu ki igbe aye rọrun fun agba osere tiata naa, ti ara rẹ ko da, ti ko si le rin daadaa.

Pasitọ Agbala Gabriel ati Iya Ibeji Omo Arayele

Oríṣun àwòrán, Agbala Gabriel/Facebook

Iya Ibeji Omo Arayele fi gbogbo ogo fun Ọlọrun pe o di onile laarin osu kan

Nigba to n sọrọ lori ile tuntun naa, Iya Ibeji Omo Arayele to mu ijo jo lasiko ayẹyẹ ile sisi naa, wa n fi gbogbo ogo fun Ọlọrun to fun oun nile naa.

Agba osere tiata naa si tun mọ riri Pasitọ Agbala Gabriel ti Ọlọrun lo lati gba lọwọ ipọnju ati ẹdun ọkan, to si sọ yẹyẹ rẹ di ayẹyẹ.

Iya Ibeji Ọmọ Arayele ti ko le dide ni oju kan tẹlẹ, lo ti n gbe ẹsẹ pẹlu irin to fi n rin, to si ti n lọ yika agbala ile naa.

Bakan naa ni ọmọ rẹ, Ronke kunlẹ, to si n dupẹ lọwọ Ọlọrun ati Pasitọ agbala Gabriel to sọ mama rẹ di onile lori.

Bẹẹ ba gbagbe, lẹyin ti BBC Yoruba gbe iroyin sita pe agba osere tiata naa n saisan ni osu kan sẹyin, ni Pasitọ agbala Gabriel tẹwọ gba ipe mama naa.

Laarin osu kan si lo kọ ile alarinrin ọhun fun mama yii.

Ronke, ọmọ Iya Ibeji Arayele wa ninu Sọọbu mama rẹ

Oríṣun àwòrán, Agbala Gabriel/Facebook

Awọn ọja ti wa ninu sọọbu itaja Iya Ibeji

Kii se ilegbe nikan ni Pasitọ agbala Gabriel kọ fun Iya Ibeji Omo Araye to jẹ agba osere tiata.

Bakan naa, ojisẹ Ọlọrun yii tun yọ sọọbu sita lara ile naa fun mama agba yii, to si tun si tun ko ọpọ ọja kun inu rẹ.

Lara awọn ọja to wa ninu sọọbu naa ni awọn ọti ẹlẹrindodo lorisirisi ati awọn ọja atẹ ti ẹnikọọkan nilo ninu ile lojumọ.

Bakan naa ni wọn gbe ẹrọ asọnkandiyinyin sinu sọọbu naa, eyi ti mama naa yoo ma ko awọn ohun mimu ẹlẹrindodo ati omi si lati ta.

Koda, ọkọ ileesẹ kan to n se omi inu ọra ati onike lo wa ja ọpọlọpọ omi onike sinu sọọbu naa, ti iya ibeji yoo maa ta.

Eyi si fi idaniloju han pe Iya Ibeji Omo Arayele ko ni rahun owo lati na mọ, ti yoo si maa ri owo se itọju ara rẹ ati lati jẹun oojọ.

Bi ọrọ ile naa ṣe bẹrẹ ree:

Ti ẹ ko ba gbagbe, ọrọ iya ibeji milẹ titi lori ayelujara lẹyin ifọrọwerọ ti ileeṣẹ BBC Yoruba ṣe fun un latari aisan to n ba finra.

Inu ifọrọwerọ ọhun ni agba oṣere naa ti ṣalaye ohun ti oju rẹ ri atawọn iya to n ba finra.

Lara awọn idojukọ ti Iya Ibeji mẹnuba ni bi ko ṣe nile lori ti ko si tun si owo lati ṣetọju aisan naa.

Ninu ifọrọwerọ ọhun naa ni ọkan lara awọn ọmọ rẹ ti rawọ ẹbẹ si awọn araalu, to fi mọ awọn ololufẹ rẹ ki wọn ṣaanu fun.

Pẹlu omije loju ni Iya Ibeji fi ke si awọn eeyan ki wọn gba oun ninu iṣoro naa to n dojukọ latari aisan ati ainile lori.

Ifọrọwerọ pẹlu BBC ọhun lo waye lẹyin ti Foluke Daramọla kede lori ikanni Instagram rẹ pe Iya Ibeji n ṣaisan, ati pe o nilo itọju.

Ipa ti Foluke ati Pasitọ ijọ Agbala Gabriel ko

Ni kete ti ifọrọwerọ Iya Ibeji pẹlu BBC Yoruba fa ori ayelujara ya ni Foluke Daramola dide, to si ke si awọn oloju aanu lati ran Iya Ibeji lọwọ.

Lara awọn oloju aanu to wo fodio Iya Ibeji lori ikanni BBC Yoruba ni Pasitọ ijọ Agbala Gabriel.

Pasitọ ijọ Agbala Gabrie ṣeleri lati kọ ile fun Iya Ibeji, o si mu ọrọ rẹ ṣẹ.

Gbogbo bi pasitọ naa ṣe lọ ra ilẹ, to si bẹrẹ ile naa kikọ ni BBC Yoruba n wo o.

Bo tilẹ jẹ pe ọrọ ibi ti ile naa wa da fakinfa silẹ laarin Foluke Daramola, pasitọ Agbala Gabriel atawọn ololufẹ rẹ kan Foluke kan, amọ ọrọ naa yanju.

Lẹyinorẹyin, Pasitọ ijọ Agbala Gabriel atawọn oloju aanu to lọwọ si ile naa pari rẹ, wọn si ti ṣi bayii, koda Iya Ibeji ti ko sinu ile ọhun.

Ọpọ awọn ọmọ ijọ Pasitọ ijọ Agbala Gabriel, mọlẹbi, ara adugbo ati ololufẹ Iya Ibeji omo araye le lo peju sibi ayẹyẹ iṣile naa.