Wọ́n sin akẹ́kọ̀ọ́ iléẹ̀kọ́ Chrisland tó kú, òbí rẹ̀ ń bèèrè fún ìdájọ́ òdodo

Whitney Adeniran ati mama rẹ

Oríṣun àwòrán, Bambabycare

Baba Whitney naa fikun un pe Ọjọ Keji, Osu Kẹta ni wọn maa sin ọmọ naa.

Amọ ileeṣẹ ọlọpaa ko i tii sọrọ lori iṣẹlẹ naa.

Fidio to wa lori ayelujara ṣafihan bi iya ọmọ naa ṣe barajẹ nibi isinku ọmọ naa.

Iya rẹ gbadura fun un pe yoo sun ire amọ o barajẹ lọpọlọpọ, to si n bere ni iboji naa pe kini oun ṣe nibẹ.

Gbogbo ẹbi ati ara to wa nibẹ ni wọn ṣugba rẹ, ti wọn si n rọ lẹkun.

‘’Ìwádìí fihàn pé ọmọ mi, Whitney Adeniran, gan mọ́ná ni’’

Abilekọ Blessing Adediran to jẹ iya ọmọ ileẹkọ Chrisland yii ti salaye pe iwadii ile iwosan ti ṣafihan ohun to pa ọmọ naa.

Akẹkọọ Whitney Adeniran ni iroyin gbe pe o ku lasiko ti ileẹkọ rẹ Chrisland n ṣe ayẹyẹ ere idaraya inter-house Sport ni papakọ iṣere ni Agege nipinlẹ Eko.

Iya Whitney loju ẹrọ ayelujara sọ wi pe esi ayẹwo ti wọn ṣe ti ṣafihan iku to pa ọmọ naa.

O ni ayẹwo naa fihan pe niṣe ni ọmọ naa gan mọ ina.

Abilekọ Adeniran ni igbeṣẹ to kan ni ki ileẹjọ bẹrẹ lori bi ọmọ naa ṣe ku.

‘’Ọmọ mi gan mọ ina ni, mi o si ti mọ ohun ti mo fẹ ṣe lati bi ọṣẹ meji bayii’’

‘’Ibanujẹ ọkan lo jẹ fun mi pe ileẹkọ naa n parọ pe niiṣe ni ara ọmọ mi ko da, ni o ṣe ku.’’

Aworan

Oríṣun àwòrán, Collage

Ibi ti ọrọ de duro lori iku Whitney Adeniran

Whitney ẹni ọdun mejila lo dagbare fun aye ni Ọjọ Kẹsan an, Oṣu Keji, ọdun 2023 nibi ti ileẹkọ rẹ ti n ṣe ayẹyẹ ere idaraya.

Baba ọmọ naa sọ fun BBC pe niṣe ni ọmọ naa gan mọ ina amọ ileẹkọ Chrisland kọ pe kii ṣe ohun to waye niyẹn.

Ninu atẹjade ti ileẹkọ naa fi lede ni wọn ti sọ pe niṣe ni ọmọ naa fo ṣanlẹ to si ku nitori ara rẹ ko ya.

Amọ baba ọmọ naa ni irọ ni wọn n pa, ti oun si ni ẹri pe niṣe ni ọmọ naa gan mọ ina.

Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ ti wọn si ni iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.

Bakan naa ni kọmiṣọnna fun eto ẹkọ nipinlẹ Eko, Folasade Adefisayo paṣẹ ki ileẹkọ naa wa ni titi pa titi iwadii yoo fi pari lori iṣẹlẹ naa.