"Àlàyé rèé lórí bí wọn ṣe yìnbọn pa aya mi ní àgọ́ ìdìbò rẹ̀"

Aworan Elizabeth Owie

Oríṣun àwòrán, Ijoba ipinle Edo

Àkọlé àwòrán, Aworan Elizabeth Owie

Ètò ìdìbò sípò Ààrẹ àti sáwọn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní ìlú Abuja ti wá, tó sì ti parí lẹ́yìn tí àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ilẹ̀ Nàìjíríà, INEC ti kéde ẹni tó jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò náà.

Àmọ́ fún ìdílé Owie, ètò ìdìbò náà dá ọgbẹ́ ọkàn sílẹ̀, tí kò lè tán sí ìgbé ayé wọn títí láé.

Ọ̀pọ̀ ìròyìn ló fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ètò ìdìbò náà lọ ní ìrọwọ́ rọsẹ̀ àmọ́ àwọn àwòrán àti fídíò kan ṣàfihàn pé làásìgbò wáyé ní àwọn agbègbè kan lásìkò ìbò náà.

Lára irú ibi tí wàhálà bẹ́ẹ̀ ti wáyé ni ìlú Benin ní ìpínlẹ̀ Edo.

Elizabeth Owie, ẹni ọdún méjìlélógójì gbéra nílé rẹ̀ láti lọ dìbò lọ́jọ́ Àbámẹ́ta ni agbègbè Ogheghe, ìjọba ìbílẹ̀ Ikpoba Okha, ìlú Benin, ìpínlẹ̀ Edo.

Àmọ́ kò padà sí ilé rẹ̀ láàyè, bí ọta ìbọn ṣe ba a, tó sì ṣekú pa á.

Ọkọ Elizabeth, Owie Osadebamwen salaye fún BBC bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé, tó fi di ẹni tí kò láya mọ́ lójijì.

Ó ní ọmọkùnrin mẹ́ta ni àwọn ti bí, tí ìgbéyàwó náà kò bá sì pé ọdún mẹ́wàá nínú oṣù Kẹsàn-án ọdún yìí, tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà kò bá wáyé.

Elizabeth ati Owie Osadebamwen

Oríṣun àwòrán, Owie Osadebamwen

Àkọlé àwòrán, Elizabeth ati Owie Osadebamwen

"Igi lẹ́yìn ọgbà mi ní, kìí ṣe ìyàwó lásán, ẹni bí ọkàn mi ní"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Ní nǹkan bíi aago mẹ́jọ sí aago mẹ́sàn-án òwúrọ̀ ni ìyàwó mi kúrò nílé láti lọ dìbò àmọ́ àwọn òṣìṣẹ́ INEC kò tètè dé ibùdó ìdìbò wọn, èyí tó mú kí ètò ìdìbò náà pẹ́ kó tó bẹ̀rẹ̀.

Ó ṣàlàyé pé gbogbo ètò náà ń lọ ní ìrọwọ́ rọsẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́ dé alẹ́ nígbà tí àwọn agbébọn yawọ ibùdó ìdìbò náà.

"Mo pe ìyàwó mi ní nǹkan bíi aago mẹ́ta ọ̀sán àmọ́ kò gbe fóònù rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹlòmíràn tí mo pè ní ìyàwó mi wà ní ẹ̀gbẹ́ òun."

"Ó pè mí padà ní nǹkan bíi aago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́ pé òun rí ìpè mi àti pé òun kò ní pẹ́ máa padà bọ̀ wá sílé nítorí òun ti ṣetán.

Osadebamwen ṣàlàyé pé bíi aago méje ìrọ̀lẹ́ ni òun gba ìpè láti ọ̀dọ̀ àbúrò òun pé ẹ̀jẹ̀ ń jáde lára ìyàwó òun, wí pé wọ́n ń yìbọn ní ibùdó ìdìbò wọn.

Ó ní lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni òun gbé ọkọ̀ láti lọ síbẹ̀ àmọ́ ohun tí òun bá, ba òun lọ́kàn jẹ́ nítorí inú àgbàrá ẹ̀jẹ̀ ni òun ti bá ìyàwó òun.

"Ilé ìwòsàn méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kọ̀ láti gba ìyàwó láti ṣe ìtọ́jú rẹ̀, tó sì ti kú nígbà tí mo fi gbe dé ilé ìwòsàn kẹta."

Ó ní òun kò ì tíì gbàgbọ́ pé ìyàwó òun ti fi òun sílẹ̀ náà nìyẹn nítorí òun pẹ̀lú rẹ ní àwọn tí jọ wà láti bíi ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn.

"Igi lẹ́yìn ọgbà mi ní ìyàwó mi, kìí ṣe ìyàwó lásán, ẹni bí ọkàn mi ní, Owie sọ fún BBC.

Godwin Obaseki ṣàbẹ̀wò sáwọn ẹbí Elizabeth.

Oríṣun àwòrán, Ijoba ipinle Edo

Àkọlé àwòrán, Godwin Obaseki ṣàbẹ̀wò sáwọn ẹbí Elizabeth.

Gómìnà Obaseki ṣàbẹ̀wò sí ẹbí Elizabeth

Lẹ́yìn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, gómìnà ìpínlẹ̀ Edo, Godwin Obaseki ṣàbẹ̀wò sáwọn ẹbí Elizabeth.

Obaseki ní ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún òun pé ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí tún le máa wáyé lásìkò ìbò níbi tí orílẹ̀ èdè yìí ti làjú dé báyìí.

Ó wá bá àwọn ẹbí náà kẹ́dùn lórí àdánù wọn.

Bákan náà ni Obaseki tún ṣàbẹ̀wò sí ẹbí àwọn Festus Idahosa, tí òun náà pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lásìkò ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Ọkọ Elizabeth àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ló wà níkàlẹ̀ láti gbàlejò gómìnà náà.

Obaseki sọ àrídájú rẹ̀ pé àwọn ọlọ́pàá ti ń ṣiṣẹ́ láti ṣàwárí àwọn tó wà nídìí ìkọlù náà.

Godwin Obaseki ṣàbẹ̀wò sáwọn ẹbí Elizabeth.

Oríṣun àwòrán, Ijoba ipinle Edo

Àkọlé àwòrán, Godwin Obaseki ṣàbẹ̀wò sáwọn ẹbí Elizabeth.

Èèyàn méjì ló kú ní àgọ́ ìdìbò tí ìkọlù ti wáyé, ìwádìí ti ń lọ lọ́wọ́ - ọlọ́pàá

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Edo, Chidi Nwauzor sọ fún BBC pé ènìyàn méjì ló pàdánù ẹ̀mí wọn lásìkò tí ìkọlù náà wáyé.

Bákan náà ló ní ènìyàn kan ṣì wà ní ilé ìwòsàn níbi tó ti ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ nítorí ìbọn tó bà á.

Nwauzor ní Festus Idahosa, Elizabeth Owie àti ẹnìkan ni ìbọn bà lásìkò ìkọlù náà.

Ó ní ìwádìí ti ń lọ lọ́wọ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.