Nigeria Presidential Results: Ṣé lóòtọ́ọ́ ní wọ́n ṣe èrú ìbò fún Peter Obi àti Atiku lásìkò ìbò ààrẹ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Chiagozie Nwonwu & Chiagozie Nwonwu
- Role, BBC News, Lagos
Lẹyin ti wọn kede Bola Tinubu gẹgẹ bi aarẹ tuntun fún orilẹ-ede yii, ọpọ eeyan papajulọ awọn ẹgbẹ oselu alatako, lo sọ wi pe eto idibo to gbe Tinubu wọle kò bojumu, ti o si kun fun ọpọlọpọ aiṣedeede.
Awọn ẹgbẹ oselu alatako naa wa ke si ajọ eleto idibo, INEC, lati wọgile abajade eto idibo naa nitori awọn igbesẹ to saaju bi wọn ṣe kede Tinubu lodi si ofin to rọ mọ eto idibo.
Bakan naa ni wọn n sọ ajọ INEC mọ mọ yi ibo lati gbe Bola Tinubu.
Ajọ to n sakoso eto idibo, INEC ni irọ ni awọn ẹsun ti wọn fi kan ajọ naa, ti ẹgbẹ oṣelu APC naa si n kin ajọ naa lẹyin.
- Wo ìtàn ayé Bola Tinubu tó di ààrẹ tuntun ní Nàíjíríà
- Wo ohun márùn ún tó le yípadà tí Tinubu bá dépò ààrẹ
- Wo àwọn èsì ìbò tó gbé Bola Tinubu wọlé bíi ààrẹ Nàíjíríà
- Ẹ wo èsì ìdìbò àwọn Sẹ́nátọ̀ àti Aṣojúṣòfin tó gbégbá orókè ní Nàìjíríà báyìí..-
- ''Èsì ìdíbò kíkà ọdún 2023 yóò tẹ̀síwájú, kìí ṣe tí 1999 tí ẹ dàrú '' - APC
Amọ titi di akoko yii, awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ oselu alatako naa ko tii gbe ẹri to daju silẹ lati ti ẹsun wọn lẹyin.
Ẹgbẹ oṣelu to ṣe ipo kẹta, Labour Party, ti ni ohun yoo gba ile ẹjọ lọ, ṣugbọn a ko ti mọ ni kikun, awọn ẹri ti wọn fẹ ẹ gbe lọ silẹ ẹjọ.
Aiṣedeede ẹrọ BVAS to yẹ ki wọn lo lati dibo jẹ ki awuyewuye pọ si lori esi ibo naa nitori ẹrọ naa ni yoo mu ko nira fun ẹnikẹni lati se eru ibo.
Bakan naa,ọpọ awọn esi idibo to yẹ ni wọn ko fi ransẹ si oju opo itakun agbaye ajọ INEC, ti wọn n pe ni Portal, eyi ti yoo safihan awọn ibudo ti eto idibo ti waye.
Aifi abajade esi idibo lati awọn yara idibo sori ẹrọ IREV ni oju opo itakun agbaye naa lo mú ọpọlọpọ awuyewuye wa.
Bakan naa, laarọ ọjọ idibo, ẹnikan to lokiki lori ẹrọ ayelujara sọ wi pe awọn kan fẹ lo imọ ẹrọ lati yi abajade esi idibo oun to ṣi oluworan to too milliọnu kan ole diẹ.
Iwadii ile iṣe BBC fihan pe ẹda oju opo ile iṣe ajọ INEC ni ẹni ọhun tọka si, ti ileeṣe INEC si fìdi rẹ mulẹ pe nkankan ko ṣe oju opo oun.
Nigbat ajọ INEC ko jalẹ lati fi awọn esi idibo sita,ẹgbẹ alatako mẹrin lo kọkọ ṣe ifẹhonuhan nígbà tí ẹgbẹ oṣelu LP, PDP ati ẹgbẹ oṣelu meji miran fẹsun iwa ibajẹ kan ajọ INEC nitori ko si esi ibo ni oju opo IREV rẹ eleyi to lodi si ofin ti ajọ INEC ń tẹle.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ofin INEC ni wọn gbọdọ ya aworan awọn abajade esi idibo ni awọn yara idibo to too 175,000 ti awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu gbọdọ fọwọsi lẹyin ti wọn ti ka ibo tan kí wọn si fi sori ẹrọ IREV ni kete ti wọn ba ti ka ibo na tan..
Nigba ti oun fi aidunu rẹ han igba keji aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP Ifeanyi Okowa ati igba kejì aarẹ ẹgbẹ oṣelu LP Yusuf Datti ninu ifọrọwerọ ti wọn ṣe pẹlu awọn akọroyin ni,aiṣedeede ajọ INEC fi han pe wọn didi padi apopọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu APC lati ṣe madaru ibo nii.
Okowo ni ti ko ba ribe ó yẹ kí ajọ INEC sun eto idibo siwaju nitori aiṣedeede ẹrọ BVAS rẹ,o ni ajọ INEC ti gbabode ti wọn si n gbe lẹyin ẹgbẹ oṣelu to wa ni jọba
Ajọ eleto idibo INEC tọrọ aforiji fun awọn aiṣedeede kọkan to waye wọn ṣeleri lati fi oju sunukun wo awọn abajade esi idibo,ajọ na ni awọn ibudo idibo miran ko si bi awọn oṣiṣẹ rẹ yo ṣe lo intanẹẹti lati fi awọn abajade esi idibo ransẹ.
O ni awọn oṣiṣẹ ajọ idibo INEC ṣẹṣẹ lo si ile iṣe INEC lati fi awọn abajade na sori ẹrọ imọ IREV.
Ọpọlọpọ lo ni abajade esi idibo sipo aarẹ ko tete lọ lori ẹrọ BVAS bi awọn abajade esi idibo sipo ile igbimọ aṣofin agba ati aṣoju sofin ti awọn eeyan di lọjọ kanna.
Agbenusọ ẹgbẹ oṣelu PDP Dino Melaye ni awọn oludibo ipinlẹ Ekiti pọ ju awọn to forukọ silẹ lati dibo lọ,alaga ajọ INEC Mahmood Yakubu tako ọrọ naa pẹlu aridaju ẹri.
Awọn kan lori ẹrọ ayelujara sọ wi pe abajade ibo ipinlẹ Ekiti ni wọn ti tẹ jade ọjọ marun ṣaaju ki ẹtọ idibo to waye ti Mahmood Yakubu ni iroyin ofege ni.
Awọn aworan kan wà lori ẹrọ ayelujara bi awọn kan n ṣe n dayaja awọn oludibo ti awọn kan si fi tipatipa da ibo ru pẹlu awọn iwa jagidijagan nipinlẹ Eko ti Peter Obi bori.
Awọn akọroyin ile iṣẹ BBC ri bíi awọn kan ti da awọn esi idibo ru ni awọn agbegbe kan ni Eko.
- Ìkéde Tinubu bíi ààrẹ, dàbí ẹni pé ọfọ wọ̀lú ni - Bode George
- Ẹnì tó kàjú ipò Ààrẹ ló borí ìbò - Buhari
- -Wọn ti gbé àwòrán èmi àti ẹbí mi sórí ayélujára, ẹ̀mí wa wà nínú ewu-
- Ọ̀rọ̀ àlùfàǹsá ni Obasanjo sọ, ó fẹ́ dojú ìjọba alágbádá bolẹ̀ ni - Tinubu
- Ìjọba Seyi Makinde tí sú aráàlú ní wọn fí tó sẹ́yìn ẹgbẹ́ òṣèlú APC - Yunus Akintunde
Ile iṣe BBC ṣe abẹwo ṣoju ọpọ ayelujara INEC lati wo awọn esi idibo ti wọn gbe sibe ṣugbọn ari aiṣedeede ninu awọn abajade esi idibo kokan,awọn ibomiiran to yẹ kí abajade esi idibo jade aworan awọn oṣiṣẹ INEC lọ wa nibẹ
Awọn iwadii ile iṣe BBC fihan pe awọn esi ibudo ibudo idibo kan ni Ado Ekiti fi aworan ẹnikan han dipo aworan esi idibo ti wọn fọwọsi.
Awọn aiṣedeede yii le jẹ nitori awọn ajọ INEC ko ṣe idanilẹkọọ to peye fun awọn oṣiṣẹ rẹ tabi kọ jẹ wi pe wọn momo fẹ ru ebi lu ajọ INEC.
Ile iṣe BBC ri awọn aiṣedeede miran papajulọ ibiti wọn ti fi abajade esi ibo ipinlẹ Sokoto si ti Ipinle Rivers, nibiti Atiku Abubakar ti bori ni Sokoto, ti Bola Tinubu si bori ni Rivers nibiti Peter Obi ti fẹ rí ibo pupọ.
Ọpọlọpọ awọn ololufẹ ẹgbẹ oṣelu APC lo ni eto Idibo ọdun yii kẹsẹ jari nitori ẹgbẹ oṣelu to n se ijọba lọwọ ko bori ni ipinlẹ Eko ati Abuja, nigba ti awọn ololufẹ ẹgbẹ oṣelu LP ni magomago wa ninu esi idibo ọhun.
Ẹniti o bori eto idibo na ni awọn aiṣedeede kọkan wa ṣugbọn awọn ko ni yoo sọ ibiti eto idibo naa yoo dari si.
Esi idibo ọdun yii fihan pe o wa lara awọn eto idibo ti o gbona julọ lati igbati ijọba awarawa kẹrin ti bẹrẹ ni ọdun 1999, ti esi idibo naa si fihan pe o kọju si ibikan.













