"Wọn ti gbé àwòrán èmi àti ẹbí mi sórí ayélujára, ẹ̀mí wa wà nínú ewu"

Alakoso to wa fun akojọpọ esi ibo aarẹ nipinlẹ Rivers, SCOPE, Ọjọgbọn Charles Teddy Adias ti dawọ ikede esi ibo aarẹ duro nipinlẹ naa.
Laarọ ọjọ Isẹgun ni Kọmisana ajọ INEC naa kede bẹẹ nibudo ti wọn ti n kede esi ibo nilu Portharcourt.
O ni oun gbe igbesẹ naa nitori bawọn eeyan kan se n dunkooko mọ ẹmi oun ati ti mọlẹbi oun.
O fikun pe ẹmi oun ko de lati tẹsiwaju nidi kikede esi ibo aarẹ to ku nipinlẹ Rivers.
"Se ni wọn n dunkooko mọ ẹmi mi ati tawọn ẹbi mi.
Lati igba ti eto idibo yii ti bẹrẹ ni wọn ti n halẹ pe ẹmi emi ati ẹbi mi wa ninu ewu ti mo ba tẹsiwaju lati kede esi ibo naa.
Wọn n fi ẹsun kan mi pe awọn eeyan kan lo gba me lati se eru ibo fun ẹgbẹ oselu kan."
Ọgbẹni Adias wa kede fun gbogbo ipejọpọ to wa nibudo idibo INEC naa pe oun ti so ikede eto idibo nipinlẹ naa rọ na titi di igba miran.
O ni oun ko ni pada kede esi ibo naa ayafi ti ajọ INEC ba seleri pe aabo to peye wa fun ẹmi oun ati ti mọlẹbi oun.
Lẹyin ikede Adias yii, lo dide kuro niwaju to joko si, to si rin jade kuro ninu gbọngan ikede ibo naa.
Isẹlẹ naa si lo soju Kọmisana fun ileesẹ ọlọpaa nipìnlẹ Rivers.
Saaju ni Alakoso to wa fun akojọpọ esi ibo aarẹ nipinlẹ Rivers, ti kede esi ibo aarẹ ni ijọba ibilẹ mọkanlelogun ninu ijọba ibilẹ mẹtalelogun to wa nipinlẹ Rivers.
Nibayii, ijọba ibilẹ meji pere lo ku ki Adias kede, amọ to faake kọri lati se bẹẹ nitori ẹsun iudunkooko mọni to ni awọn igun kan n se si oun ati mọlẹbi oun.
“Gbogbo fọto mi ati ti ẹbi mi ni wọn ti pin sori ayelujara”
Adias wa fikun pe ẹmi oun ko de rara ti oun ba tẹsiwaju lati kede esi ibo naa nitori gbogbo aworan oun ati ti ẹbi oun ni wọn ti pin kaakiri awọn oju opo ayelujara.
Bakan naa lo fiku pe ọpọlpọ ipe ni oun n gba lojumọ pẹlu oniruuru atẹjisẹ, eyi ti wọn fi n dunkooko mọ oun ati ẹbi oun.
O ni se ni wọn n gbe awọn atẹjisẹ naa sawọn oju opo ayelujara lati kede ewu to wa fun awọn, ti oun ba fi tẹsiwaju lati kede awọn esi ibo aarẹ naa.
Adias ni ojuse oun lasan ni lati tẹwọgba awọn esi ibo to n wa lati ibudo ti wọn ti n ko awọn esi ibo jọ lawọn ijọba ibilẹ.
O fikun pe oun ko ni anfaani sawọn esi ibo yii tabi mọ bi wọn se se eto idibo naa, to si n ya oun lẹnu lori idi ti wọn se n dunkooko mọ oun ati ẹbi oun.
A pese aabo to peye fun alakoso esi ibo ni Rivers, a si wadi awọn to wa nidi iwa idunkooko mọ ẹmi rẹ - Kọmisana ọlọpaa
Wayi o, Kọmsana ọlọpaa nipinlẹ Rivers, Aderemi Adeoye ti bu ẹnu atẹ lu iwa idunkooko mọ ni naa.
Adeoye ni gbogbo awọn eeyan ti ọwọ awọn agbofinro ba ba pe wọn wa nidi iwa idunkooko mọ ni yii ni wọn yoo foju wọn ba ile ẹjọ.
O wa rọ Alakoso to wa fun akojọpọ esi ibo aarẹ nipinlẹ Rivers, lati kọwe ẹhonu nipa idunkooko mọni si ẹmi rẹ naa.
O fikun pe ileesẹ ọlpaa yoo bẹrẹ akanse iwadii loju ọgan si iwa idunkoooko mọni naa.
Kọmisana fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Rivers wa fi ọwọ idaniloju sọya pe oun yoo pese eto aabo to peye fun alakoso naa atawọn ẹbi rẹ.
Bakan naa lo tun rọ Alakoso to wa fun akojọpọ esi ibo aarẹ nipinlẹ Rivers, lati pari ikede esi ibo aarẹ to n se nitori eyi le ni ipa nla lori akojọpọ esi ibo lapapọ ilẹ wa.
Amọ Alakoso to wa fun akojọpọ esi ibo aarẹ nipinlẹ Rivers kọ lati tẹti si ẹbẹ Kọmisana ọlọpaa naa.















