Wo olùdíje ààrẹ tó wà lókè ténté nínú èsì ìbò ìpínlẹ̀ mẹ́rìnlà tí INEC kéde

Tinubu

Oríṣun àwòrán, AFP

Oludije ipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu lo ṣi n leke tente bayii ninu esi ibo ipinlẹ mẹrinla ti INEC ti kede.

Tinubu ti jawe olubori pẹlu ida 44% esi ibo ti wọn ṣi kede, nigba ti ẹni to n tẹle, Atiku Abubakar ni nnkan bii 33% ida ibo naa.

Ẹni to wa ni ipo kẹta ni Peter Obi, to ti ni nnkan bii ida 18% bayii lẹyin to la Bola Tinubu mọlẹ nipinlẹ Eko.

Lọjọ Aje, awọn aṣoju PDP ati Labour binu jade kuro ninu gbọgan ti INEC ti n kede esi ibo naa lẹyin ti wọn fẹsun magomago kan INEC ati APC.

APC ni ẹgbẹ oselu ti esi ibo ko ba tẹ lọrun lẹtọọ lati gba ile ẹjọ lọ

Ṣugbọn INEC ti sọ pe irọ lasan ni ẹsun ti awọn ẹgbẹ oṣulu mejeji fi kan oun.

Igba akọkọ ree ti INEC yoo lo BVAS lati fi esi ibo ranṣẹ.

Bo tilẹ jẹ pe PDP sọ pe esi ibo naa ni magomago ninu, ti LP si sọ pe awọn n fẹ ki wọn wọgile ibo naa fun atundi, INEC ti kede pe oun yoo tẹsiwaju lati maa kede esi ibo awọn ipinlẹ to ku.

Awọn to wa bojuto eto idibo naa lati Europe sọ pe INEC kuna lati ṣe imurasilẹ to tọ fun eto idibo ọhun, eyii to ṣe ipalara fun esi to n jade.

APC ti sọ pe ẹgbẹkẹgbẹ ti esi ibo naa ko ba tẹ lọrun lẹtọọ lati gba ile ẹjọ lọ,

Lati igba ti awọn Ologun ti gbe ijọba kalẹ lọdun 1999, ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP lo n leke tente eto oṣelu Naijiria ki Labour to de.

Ki ẹgbẹ oṣelu kankan to le jawe olubori ninu ibo Aarẹ ni Naijiria, oludije rẹ gbọdọ ni iye ibo to pọju ati ida 25% ibo ti wọn ba di ipinlẹ marundinlọgbọn ninu mẹrindinlogoji to wa ni Naijiria, to fi mọ ilu Abuja.

Bi bẹẹ kọ, atundi ibo yoo waye laarin ọjọ mọkanlelogun, amọ ko ṣẹlẹ ri ni Naijiria.

Rògbòdìyàn wáyé lórí bí Peter Obi ṣe na Tinubu mọ́lé ní Eko, Sọ́jà gba ìgboro láti pèsè àlááfíà

Awọn Sọja to wa ni igboro Eko

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ti fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni idarudapọ waye nipinlẹ naa ni kete ti ajọ INEC kede esi ibo aarẹ ti ẹgbẹ oselu kọọkan gba nipinlẹ Eko.

Gẹgẹ bi INEC ti kede rẹ, oludije fun ẹgbẹ oselu Labour Party, Peter Obi, lo lewaju ninu ibo aarẹ naa nipinlẹ Eko, tii se ipinlẹ oludije sipo aarẹ fẹgbẹ oselu APC, Bola Tinubu.

Ninu ibo aarẹ naa, Peter Obi ni ibo 582,454, Bola Tinubu ni ibo 572,606, ti Atiku Abubakar, tẹgbẹ oselu PDP si ni ibo 75,750, nigba ti Rabiu Kwankwaso tẹgbẹ oselu NNPP ni ibo 8442.

Ni kete ti esi ibo naa bọ sigboro, lawọn janduku kan ti ko fara mọ esi ibo naa, jade sita lati fi ẹhonu wọn han bi o tilẹ jẹ pe ajọ INEC ko ti kede ẹni to bori gbogbo esi ibo aarẹ naa jakejado Naijiria.

Awọn janduku ọhun lo ya lọ sawọn ọja kan nilu Eko, ti wọn si n dunkooko mọ awọn ontaja to wa nibẹ.

Sọja

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Tinubu, Sanwo-Olu bẹbẹ fun alaafia nigboro Eko

Lara awọn ọja ti wọn ti fi ẹhonu wọn han ni Oyingbo ati Balogun, ti wn si ko awọn oniruuru ohun ija oloro lọwọ lati da alaafia ilu ru.

Iwa idaluru naa lo mu ki Asiwaju Bola Tinubu ati gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu figbe bọnu fawọn eeyan ipinlẹ Eko lati gba alaafia laaye.

Ninu atẹjade ti ikọọkan wọn fisita lasiko ti rogbodiyan naa n lọ lọwọ, awọn mejeeji ni bi ẹgbẹ oselu se bori nipinlẹ Eko se afihan ilana eto isejọba to pegede.

Tinubu ni bi ẹgbẹ oselu Labour se bori nipinlẹ Eko ko to lati da wahala silẹ nitori isejba alagbada fun araalu kọkan ni anfaani lati dibo fun ẹni to ba wu lọkan.

Awọn ologun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileesẹ ologun bọ sigboro lati pana rogbodiyan

Wayi o, ileesẹ ologun ilẹ wa ti wa da awọn osisẹ rẹ saarin ilu lati dena wahala to le suyọ lawọn agbegbe kan nilu Eko.

Ohun gbogbo si ti pada bọ sipo bayii, ti alaafia si ti n jọba pada nipinlẹ Eko.