Èsì ìbò dá ìjà sílẹ̀, èèyàn mẹ́rin kú, wọ́n gún 42 ní ọ̀bẹ

Ibi ti wọn dana sun

Oríṣun àwòrán, Ibrahim Adams/Facebook

Ẹgbẹ oṣelu NNPP ni ipinlẹ Kano ti fẹsun iṣekupani kan awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Kano.

Agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu naa, Sanusi Bature Danwaki Tofa ni ọmọ ẹgbẹ oun mẹta ni wọn ti ba iṣẹlẹ naa lọ, ti wọn si fina si ile ẹgbẹ to wa ni Tadun Wada ni irọlẹ ọjọ Aiku.

Tofa ni ọmọ ẹgbẹ NNPP mejilelogoji ni wọn gùn ni ọbẹ, ti wọn si yinbọn mọ awọn miran.

Ẹni ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ sọ fun akọroyin BBC pe ọkan lara awọn to n dije ninu ẹgbẹ oṣelu APC lo dari awọn janduku naa wa lati ṣe iṣẹ ibi naa nigba ti wọn ka awọn abajade esi idibo.

O tẹsiwaju wí pe awọn oṣiṣẹ alabo gbiyanju lati da iṣẹlẹ naa duro nigbati wọn yinbọn, ṣugbọn ọwọ wọn ko ká awọn to wa ṣiṣẹ ibi naa.

Irọ ni NNPP n pa - APC

Alaga ẹgbẹ oṣelu APC ni Kano, Abdullahi Abbas, ni irọ ni ẹgbẹ oṣelu NNPP pa mọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC.

O ni awọn ọmọ ẹgbẹ oun kọ lo wa nidi iṣẹlẹ naa, ti o si na ìka aleebu si ẹgbẹ oṣelu NNPP.

Ile iṣe ọlọpaa ipinlẹ Kano ni awọn ṣiṣẹ lori iṣẹlẹ iṣekupani naa, ti awọn yoo sì fi imu ẹni ti o jẹbi fọn fere.

Wayi o, wọn ti sin awọn eeyan to fori sọta isẹlẹ naa.