Ìbò ààrẹ́ dá ìjà rọ̀fọ̀rọ́fọ̀ sílẹ̀ lágbo tíátà Yorùbá

Iyabo Ojo, Dayo Amusa, Adunni Ade, Basira Badia, Lege àti Aminatu papapa kọjú ìjà síra wọn

Akisanya, Ojo, Lege ati Amusa

Oríṣun àwòrán, Collage

Idibo aarẹ to waye lọjọ Satide ti n fa ijangbọn nla laarin awọn osere tiata lorilẹede Naijira, paapaa ni ẹka ti ede Yoruba.

Ohun to si fa aawọ naa ni bawọn osere tiata kan to n se atilẹyin fun ẹgbẹ oselu Labour Party ati oludije rẹ, Peter Obi, se n tabuku awọn akẹẹgbẹ wọn to n ti Bola Tinubu ati ẹgbẹ oselu APC lẹyin.

Lara awọn osere tiata to wa lẹyin Peter Obi ni Iyabo Ojo ati Adunni Ade, ti wọn n fọnrere pe oludije ẹgbẹ oselu Labour naa lo kaato lati dari orilẹede Naijiria.

Bakan naa, Dayo Amusa, Aminatu Papapa ati Badira Badia wa lẹyin Tinubu, ti wọn si n lọ ba se ipolongo ibo, eyi ti ko dun mọ awọn akẹẹgbẹ wọn to n se ti peter Obi ninu.

Ki lo fa idi ija to waye?

Ohun to fa ija naa ni bi wọn se ni Iyabo Ojo se gbe awọn esi idibo aarẹ kan sita lẹyin eto idibo aarẹ eyi to n safihan pe ẹgbẹ oselu Labour lo n moke, paapaa lawọn agọ idibo to ti dibo ati ni ayiika rẹ.

Iyabo Ojo, ẹni to kede pe bi oun se n ti ẹgbẹ oselu Labour lẹyin ko ni ohunkohun se pẹlu ẹya tabi ẹsin amọ oun n fẹ ki Naijiria gba afẹfẹ ọtun sara ni.

O ni oun gbagbọ ninu ọgbọn akoso ati afojusun Peter Obi, to si see se fun orilẹede Naijiria lati ni ibẹrẹ ọtun, ki iran to n bọ maa ba koju isoro ti iran yii n la kọja lọwọ lọwọ.

O wa n gbadura pe ki Peter Obi bori ibo aarẹ naa, ko si mase ja awọn ọmọ Naijiria kulẹ.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 1

Esi ti Lege fọ ree:

Ikede Iyabo Ojo yii lo bi osere tiata lọkunrin, Lege ninu, to si se fidio kan sita lati ke sawọn araalu pe ki wọn mase gba awọn esi ibo ti Iyabo Ojo gbe sita gbọ.

Bakan naa lo n kede pe o ya oun ara lo n ta Iyabo Ojo nitori pe APC ko gbe ni ati pe kikida ibi ti oludije to n se atilẹyin fun nikan lo n gbe sita.

Lege wa rọ Iyabo Ojo lati gbe awọn esi ibo jade nibi ti oludije ti oun n satilẹyin fun ti n bori pẹlu.

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 2

Awọn akẹẹgbẹ mi n gba epe sori ara wọn tori owo tasọrẹ - Adunni Ade

Aduuni Ade n tiẹ lo n salaye awọn isoro to koju lasiko to lọ dibo, o ni ara opun ko ya, ti oun si n lo oogun lọwọ.

Amọ ifẹ ti oun ni fun ilẹ Naijiria lo mu ki oun pinnu lati lọ dibo, ti oun si de si agọ idibo oun to wa ni Osapa London ni aago mẹfa aarọ, ti oun si kuro nibẹ ni aago mẹrin irọlẹ, ki oun to pada lọ dibo lalẹ.

O wa n fesi si iroyin kan to ni ajọ INEC sọ pe ko si ibo kankan to waye ni agọ idibo oun, ti awọn isoro to la kọja lati dibo si n ka lara.

Idi si ree to se n foju laifi wo awọn osere tiata kan ti wọn n ba ẹgbẹ oselu kan seto ipolongo ibo, to si ni sebi owo perete, ti ko ju ẹgbẹrun lọna aadọrun naira ni wọn fun wọn lori gbogbo wahala wọn fun odidi osu meji.

Aduuni Ade ni wọn o yẹ ki oju ti wọn nitori awọn n sepe le wọn lori, oorun si pa wọn, eyi ti ko yẹ ko ri bẹẹ fun wọn.

Skip Instagram post, 3
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 3

Ko tọ siẹ lẹnu, alaimoore ni ẹ - Dayo Amusa

Bakan naa ni Dayo Amusa sọrọ lori isẹlẹ naa amọ lowe lowe lo gbe ọrọ tiẹ sita loju opo Instagram rẹ

Sugbọn awọn ọmọran kan lori ayelujara ni ara awọn osere tiata lobinrin kan lo n fi awọn ọrọ to gbe sita naa ba wi.

Ọrọ to gbe sita naa tun ni osere binrin miran, Bimbo Akisanya gbe soju opo Instagram tiẹ naa.

Amọ awọn osere tiata mejeeji naa lo ti pa ikede naa rẹ lawọn oju opo \Instagram wọn bi o tilẹ jẹ pe ọrọ yii ti tẹ wa lọwọ saaju ki wọn to rẹ.

Lara ohun ti Dayo Amusa sọ ni pe “Ko tọ si ẹ lẹnu, se bi ẹni to n pe ni tọọgi abi janduku yii lo sanwo ile ẹkọ awọn ọmọ rẹ.

O tun se ọjọ ibi fun ọmọ rẹ, o sanwo ile to haya, o sanwo ọkọ ofurufu rẹ l silẹ okeere, to si tun ba ọ san owoya to gba lori ile rẹ tuntun.

Ẹni to n se iru eyi kii se tọọgi lasiko to n se awọn nnkan wọnyi, alaimoore ni ẹ, awọn ọrọ yii ko si tọ si ẹ lẹnu.

Ọrọ ti Dayo Amusa kọ, eyi ti Bimbo Akinsanya gbe sita

Oríṣun àwòrán, the_bimboakisanya/Instagram

Tinubu ti se awọn osere loore pupọ, a ko le gbagbe rẹ - Aminatu Papapa ati Badira Badia

Ọrọ ti Aduuni sọ yii lo bi Aminatu Papapa ati Badira Badia ninu tawọn naa fi se fidio soju opo Instagram ikọọkan wọn.

Ọrọ ti awọn mejeeji sọ ko fi bẹẹ yatọ sira wọn, ti wọn si n sọ fawọn akẹẹgbẹ wọn to lodi si ẹgbẹ oselu APC pe olukaluku lo ni ominita lati se atilẹyin fun ẹgbẹ oselu to ba wu.

Awọn mejeeji si lo tun n pa lowe lowe pe ọkan lara akẹẹgbẹ wọn lobinrin to n ta ko awọn yii lo ti jẹ ọrẹbinrin ri fun oloselu tabi ẹni ti wọn n pe ni tọọgi yii.

Wọn wa kadi ọrọ wọn nilẹ pe Asiwaju Bola Tinubu tawọn n tẹle yii lo ti se ọpọ oore fun awọn akẹẹgbẹ awọn ri lasiko isoro awọn ko si le gbagbe rẹ laelae, oore si ni oore n wọ le.

Skip Instagram post, 4
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 4

Skip Instagram post, 5
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 5