Nigeria Election 2023: Àwọn géńdé tó fi aṣọ bojú ń jú ìgò àti àdá kiri, wọn gba fóònù àwọn òṣìṣẹ́ INEC

Se ni ohun gbogbo tun pakasọ ni agọ idibo kọkanla, 011, ni agbegbe Igbokusu, Nicon town, lagbegbe Lekki nilu Eko lasiko ti eto idibo aarẹ n lọ lọwọ.
Gẹgẹ bi awọn eeyan to wa ni agọ idibo naa ti salaye fun akọroyin BBC, se ni awọn gende agbebọn kan de si agọ idibo naa, ti wọn si ni kawọn eeyan mase dibo mọ.
Ọgbẹni Sunny Njoku, lasiko to n ba BBC sọrọ ni se lawọn gende agbebọn naa wa pẹlu afọku igo lọwọ wọn ati ada, ti wọn si n le awọn eeayn kuro lagọ idibo naa.

Koda, o ni awọn janduku naa tun le awọn osisẹ eleto idibo kuro lagọ idibo naa, ti wọn si gba foonu to wa lọwọ wọn pẹlu.
Bakan naa, Njoku ni se lawọn gende agbebọn ọhun tun gbe apoti idibo mẹta lọ eyi ti ibo tawọn eeyan di kun inu rẹ bamu bamu.
"Ni bayii, a ko le tẹsiwaju mọ pẹlu ibo didi ni agọ idibo yii nitori wọn ti gbe apoti idibo lọ, tawọn osisẹ ajọ INEC si ti sa lọ." Njoku salaye
"Mo subu, mo fi ẹsẹ rọ, ọkọ mi naa subu, o fi apa sese nigba ti agbebọn ya bo agọ idibo wa"

Tunwẹ, awọn eeyan kan fara pa lasiko ti awọn agbebọn naa ya bo agọ idibo kọkanla ni Igbokusu naa, ti ọwọ ọkunrin kan bo, ti ẹsẹ obinrin kan si rọ pẹlu.
Nigba to n ba BBC sọrọ, Dokita Okolie Ikem salaye pe awọn ti pari gbogbo igbesẹ to yẹ lati dibo, kawọn janduku to de si agọ idibo naa.
Ikem ni " A ti yẹ orukọ wa wo, ti ẹrọ BVAs naa si ti gba itẹka wa, koda, wọn ti kan ọda si wa lori ika, eyi to se afihan pe a se ayẹwo, ka kan dibo lo ku.
Sadede la ti ti igo n fo kiri loju ofurufu, tawn ọkunrin kan to fi asọ boju si mu ada lọwọ, eyi to n kọ yanranyanran.
Idi ree ti gbogbo eeyan se n sa kaakiri, mo subu, mo fi ẹsẹ rọ, ti ọkọ mi naa si subu, to si fi ọwọ sese.
A ko le dibo mọ, wọn ti ji foonu awọn osisẹ INEC lọ, ti idarudapọ si ti wa nibi."


Ìró ìbọn da àgọ́ ìdìbò rú, ọ̀pọ̀ ìwè ìdìbò fọ́n ká inú gọ́tà
Se ni ọrọ di ẹni ti ori yọ, o dile nigba ti awn agbebọn kan ya bo awọn agọ idibo to wa ladugbo Surulere nipinlẹ Eko.
Ni ikorita Shaki Crescent ati opopona Akinyele to wa ni agbegbe Aguda ni Surulere, iwe idibo fọnb kalẹ kaakiri, tawọn miran si bọ soju omi.
Ṣe ni awọn oludibo n sa asala fun ẹmi wọn nigba ti wọn gbọ iro ibọn naa, ti jinnijinni ibọn si da bo ọpọ wọn.
Koda, se ni awọn osisẹ ajọ eleto idibo mu ẹrọ BVA salọ kuro lawọn agbegbe idibo naa, kawọn agbebọn naa maa baa ba jẹ.

Akọroyin BBC to wa ni agbegbe naa jabọ pe se ni awọn agbebọn naa da awọn ibo ti wọn nu sinu apoti ibo nu.
Se lawọn iwe idibo naa si fọn kaakiri ilẹ, koda, ọpọ awọn iwe idibo naa lo ti yi mọ ẹrọfọ, ti wọn si wa ninu gọta.
Ọpọ awọn apoti idibo naa ni wọn fọ mọlẹ, ti ike naa si fọn kaakiri, nigba ti ideri awọn apoti idibo naa fọn kaakiri.

Bakan naa la ri awọn iwe idanimọ awọn osisẹ eleto idibo nilẹ, ti wọn ju kaakiri pẹlu awọn iwe atọna fawọn oludibo.
Ileesẹ eleto idibo tabi ọlọpaa ko tii sọrọ nipa isẹlẹ naa.
Amọ ọga agba funa ajọ INEC, Mamood Yakubu ti ni ohun yoo bawọn ọmọ orilẹede Naijiria sọrọ ni aago mẹrin abọ lati jabọ nipa bi eto idibo naa se lọ.

















