Nigeria Presidential elections 2023: Ṣé lóòtọ́ ní INEC mọ̀ọ́mọ̀ yọ àsíà labour Party kúrò lórí ìwé ìdìbò

Oríṣun àwòrán, Labour Party
Ọpọlọpọ iroyin lo ti jade lasiko idibo sipo aarẹ ati ti aṣojuṣofin lorilẹede Naijiria.
Awọn ẹgbẹ oṣelu mẹta lo n lenke ninu idibo naa, awọn ẹgbẹ oṣelu APC, PDP ati labour party.
Amọ lasiko to ku diẹ ki idibo naa bẹrẹ ni awọn aworan kan suyọ nibi ti asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party ko si lori iwe idibo awọn ile igbimọ aṣọfin, ti wọn si bẹrẹ si ni pin ka lori ẹrọ ayelujara.
Awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu naa fi ẹsun kan ajọ INEC pe wọn mọọmọ gbe igbesẹ naa lati dina awọn eniyan lati maṣe dibo
Kini ẹsun ti wọn fi kan INEC?
Ni oju opo ikansiraẹni Labour Party lori Twitter ni wọn ti kede pe asia ẹgbẹ wn ko ri lori awọn iwe idibo kan, ni ipinlẹ Eko ati ti awọn miran
Awọn ololufẹ wọn kaakiri orilẹede Naijiria fi fidio sita ati fọto sita to ṣafihan naa.
Bakan naa ni wọn fi ẹsun kan INEC pe wọn gbe igbesẹ naa lati ma ṣe jẹ ki awọn bori ni awọn agbegbe naa
Amọ iwe idibo naa ko gbe orukọ ẹgbẹ oṣelu naa jade ninu asia ti INEC gbe jade.
Njẹ ṣe lootọ ni orukọ ẹgbẹ oṣelu Labour party ko jade ni ninu iwe idibo?
Adari ẹka eto INEC, Zainab Aminu Abubakar sọ fun ileeṣẹ BBC pe loot ni ẹgbẹ oṣelu labour party ko han ni awọn iwe idibo kọọkan.
O ni eyi ko ṣẹyin bi ẹgbẹ oṣelu naa ko ṣe fi orukọ awọn oludije wọn ṣọwọ si INEC.
INEC ni o ku ọjọ diẹ ki idibo naa waye ni ẹgbẹ oṣelu naa gbe wọn lọ si ileẹjọ, bio tilẹ jẹpe wọn ko fi orukọ awọn oludije wọn ranṣẹ si wọ.
Amọ ẹgbẹ oṣelu Labour party ni ileẹjọ̀ giga ni Abuja ti kan an ni pa fun INEC lati fi orukọ awọn oludije sinu iwe idibo amọ INEC ko gbọ si wn lẹnu.
Kini idi ti INEC fi yọ orukọ ẹgbẹ oṣelu kuro ninu iwe idibo?
Ajọ eleto idibo INEC ni aṣẹ lati yọ orukọ ẹgbẹ oṣelu kuro nipo ti wọn ko ba ṣe idibo abẹle lati yan oludije.
INEC ni bi ẹgbẹ oṣelu kan tilẹ ṣe idibo abẹle lai pe oṣiṣẹ idibo INEC sibẹ wọn ko ni fi orukọ si inu iwe idibo.
Bakan naa ni wọn fikun un pe saaju ki idibo to sun mọ ni wọn ti ma n kede gbedeke fun ẹgbẹ oṣelu lati kede ẹni ti yoo dije du ipo ninu ẹgbẹ oṣelu naa.
Amọ ti ẹgbẹ naa ko ba fi orukọ wọn lede o ṣeeṣe ki wọn padanu lati ri orukọ wọn lori iwe idibo.
Iroyin ofege nipa INEC n tan kaakiri...
Orisirisi iroyin lo n tan kaakiri nipa pe ajọ eleto idibo INEC gbiyanju lati doju idibo naa palẹ.
Wọn si n fi ẹsun kan INEC pe wọn n lo ẹrọ BVAS lati fi dena awọn eniyan pe ki wọn ma dibo yan ẹni ti wọn fẹ.
Bakan naa ni wọn fi ẹsun kan INEC pe awọn eniyan n lo oju opo esi idibo INEC lati gbe esi idibo jade.
Amọ INEC ni awọn kan lo gbe ayederu oju opo INEC sita ti wọn si n fi iroyin ẹlẹjẹ sibẹ.












