2023 Nigeria Election: Àbọ̀ ìwádìí BBC rèé nípa ìròyìn tó ní INEC ń lo ojú òpó ayélujára rẹ̀ láti yí èsì ìdìbò

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu alatako ti fi ẹsun kan ajọ eleto idibo loju ẹrọ ayelujara pe oju opo ajọ naa ni wọn n lo lati fi ṣe ayederu esi idibo.

Oju opo INEC naa ni wọn pese pe ki awọn oṣiṣẹ wọn maa fi esi idibo ẹka idibo sibẹ, ti awọn eniyan yoo si maa ri bi esi idibo naa ṣe n wọle.

Ẹsun ti wọn fi kan INEC ni pe awọn eniyan kan ti n lo oju opo naa lati fi esi idibo ayederu sibẹ.

Amin iyasọtọ kan
Amin iyasọtọ kan

Amọ iwadii fihan pe kii se oju opo idibo INEC ni ayederu esi idibo naa wa.

Amọ awọn ọbayejẹ ni wọn ṣe ẹda oju opo naa, ti wọn si n fi ayederu iroyin sibẹ lati gbe ọkan awọn eniyan soke lori esi idibo naa.

Bakan naa ni oju opo ayederu naa ki n ṣe nkankan naa pẹlu ti INEC, ti ami oju opo si yatọ si ti INEC.

Iroyin ayederu miran to tun jade ni lilo ẹrọ BVAS lati ṣwe ayederu esi idibo paapaa lori ẹrọ ayelujara.

Awọn ti wọn fi ẹsun yii kan INEC tun ni awọn yoo bẹrẹ ifẹhọnuhan ti ẹni ti wọn fẹ ko ba wọle.

Eyi ko ṣẹyin bi awọn ẹrọ BVAS naa ṣe kọ lati ṣiṣẹ ni awọn ẹkun kọọkan ni Naijiria nitori aisi ẹrọ ayelujara to ja geere tabi ẹrọ naa.

Ọpọlọpọ igba ni wọn ti fi ẹsun kan ajọ INEC pe wọn n ṣiṣẹ papọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu APC lati doju ibo ru ni Naijiria amọ ko si aridaju nipa ẹsun naa.

Awọn oludibo

Wo ìpínlẹ̀ márùn-ún tí ìbò ti ń tẹ̀síwájú lọ́jọ́ Àìkú

Nibayii ti ajọ INEC ti n se akojọpọ esi ibo aarẹ ati tawọn asofin apapọ to waye lọjọ Satide, o dabi ẹni pe eto idibo naa ko tii pari patapata.

Idi ni pe ajọ eleto idibo nilẹ wa, INEC ti kede pe etyo idibo naa si n tẹsiwaju lawọn ẹkun idibo kọọkan lawọn ipinlẹ kan nilẹ Naijiria.

Ohun to sokunfa igbesẹ yii ni pe awọn eelo idibo pẹ ko to de sawọn agbegbe idibo kan, nigba ti ẹrọ BVAS ko sisẹ lawọn agọ idibo miran bo se yẹ.

Eyi si wa lara ohun to mu ki eto idibo ma lee waye tabi ko ma tete pari lawọn irufẹ agọ idibo bẹẹ.

Amọ ni awọn agbegbe miran, jagidi jagan waye, bawọn janduku kan se n kọlu awọn osisẹ ajọ INEC atawọn oludibo lawọn agọ idibo kan.

Isẹlẹ naa ni ko jẹ ki eto idibo tete pari nibẹ tabi ko ma tiẹ waye rara, eyi si lo mu ki ajọ INEC kede pe idibo yoo maa waye ni irufẹ awọn agbegbe yii lonii ọjọ Aiku.

BBC Yoruba wa se akojọpọ awọn ipinlẹ ti eto idibo ti n tẹsiwaju lonii.

Àkọlé fídíò, 2023 Nigeria Election: Ìgbàgbọ́ wa ní pé Nàìjíríà ṣì máa dùn lẹ́yìn ìdìbò ọ̀la yìí

Wo awọn ipinlẹ ti eto idibo ti n tẹsiwaju lọjọ Aiku:

Balyesa:

Agọ idibo mọkanlelogoje, 141, ni ajọ INEC sun eto idibo wọn siwaju lọjọ Satide si Sọnde nipinlẹ Bayelsa.

Alaga ajọ INEC nilẹ wa, Mamood akubu lo kede bẹẹ ninu ọrọ to bawọn akọroyin sọ lẹyin ti eto idibo pari lọjọ Satide.

Yakubu ni idarudapọ to waye lawọn agọ idibo naa lo sokunfa isunsiwaju eto idibo nibẹ di ọjọ Aiku oni.

Cross Rivers:

Ni ipinlẹ Rivers, ajọ INEC kede pe eto idibo si n tẹsiwaju lonii ọjọ Aiku nipinlẹ Cross Rivers nitori bi wọn ko se lee pari ibo didi lawọn agbegbe kan nipinlẹ naa.

Atẹjade kan ti agbẹnusọ ajọ naa, Anthonia Nwobi fisita ni eto idibo naa yoo tẹsiwaju loni ọjọ Aiku lawọn agọ idibo to wa ni ijọba ibilẹ Bakassi.

Awọn oludibo

Taraba:

Bakan naa ni idibo n tẹsiwaju lonii nipinlẹ Taraba gẹgẹ bi ajọ INEC ti kede rẹ.

Ajọ INEC fidi rẹ mulẹ fun BBC pe ipinlẹ Taraba wa lara awọn ti eto idibo ko ti pari lọjọ Satide.

Eyi ko si sẹyin bi awọn ohun elo idibo se pẹ ko to de sawọn agọ idibo kọọkan ati bi intanẹti se se idiwọ fun ẹrọ BVAS lati sisẹ nibẹ.

Bakan naa ni iroyin kan ni wọn tun ji awọn osisẹ ajọ eleto idibo mẹta gbe lọ nijọba ibilẹ onga ni Taraba.

Awọn osisẹ ajọ INEC ti ko fẹ ka darukọ rẹ lo fidi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC.

Amọ osisẹ alarina fun ileesẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Taraba, Usman Abdullahi ni awọn ti n se iwadii si isẹlẹ naa lati mọ bo se waye.

Edo:

Alaga ajọ INEC, Mamood INEC, Mamood Yakubu ti kede pe eto idibo miran yoo waye lawọn agọ idibo kan nipinlẹ Edo.

Idi ni pe ko si ami idamọ ẹgbẹ oselu kan ninu iwe idibo lawọn ẹkun idibo meji nipinlẹ naa.

Mamood Yakubu wa pasẹ pe ki wọn sun idibo siwaju titi di ọjọ Kọkanla osu kẹta ọdun 2023 ti wọn yoo di ibo gomina ati tawọn asofin ipinlẹ.

Alaga INEC ni oun pasẹ bẹẹ nitori ofin fun ẹnikọọkan laaye lati dibo, gbogbo ọna si ni ajọ naa yoo gba lati ri daju pe ofin naa fẹsẹ mulẹ.

O wa kede pe loni ni wọn yoo kede esi ibo aarẹ yika Naijiria.

Kogi:

Ajọ eleto idibo ti wọgile awọn eto idibo to waye lawọn agọ idibo kan nijọba ibilẹ Ila Oorun Kogi.

Idi ni pe idarudapọ waye lawn agọ idibo naa nigba ti awn janduku da eto idibo ru lawọn agbegbe kan.

Koda, agọ idibo meji ni INEC ni wọn ti da ibo ru ni agbegbe Nyigba ati ni agọ idibo marun ni Omala nipinlẹ Kogi.

Ajọ eleto idibo ni se lawọn janduku naa n yinbọn si afẹfẹlati le awọn oludibo kuro lawwọn agọ idibo naa.

O ni eyi lodi si ofin, to si jẹ ki awọn wọgile eto idibo to waye lawọn agbegbe naa.

INEC ko wa sọ boya eto idibo naa yoo maa tẹsiwaju lonii.

Igbesẹ idarudapọ to waye lagọ idibo naa si lo bi ọpọ oludibo ninu nitori bi idaduro se ba idibo naa.

Nipinlẹ Eko bakan naa, awọn agọ idibo kan ni ohun elo idibo pẹ ko to de ibẹ, eyi to bi ọpọ oludibo ninu.

Amin iyasọtọ kan

Wo bí èsì ìbò ṣe lọ ní àgọ́ ìdìbò àwọn olùdíje ààrẹ kọ̀ọ̀kan

Tinubu, Atiku, Obi ati Kwankwaso

Oríṣun àwòrán, Facebook

Láti ìgbà tí ìṣèjọba àwaarawa ti bẹ̀rẹ̀ padà láti ọdún 2019, ẹgbẹ́ òṣèlú méjì ló sábà máa ń léwájú nínú ìdìbò ìyẹn ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti PDP.

Àmọ́ nínú ìdìbò ọdún yìí, ìpèníjà mìíràn tún ti wáyé nítorí ẹgbẹ́ òṣèlú mìíràn tún ti dìde ìyẹn Labour Party tí Peter Obi ń díje lábẹ́ rẹ̀.

Ìbò kíkà ti bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀pọ̀ àwọn ibùdó ìdìbò èyí tí wọn yóò ṣe àkójọ gbogbo rẹ̀ tó bá yá láti fi ránṣẹ́ sí ìlú Abuja ní oríkò àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò láti kéde ẹgbẹ́ tó bá gbégbá orókè.

Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni ìrètí wà pé INEC yóò fi orúkọ ẹgbẹ́ tó mókè nínú ìbò náà jáde.

Bí àwọn olùdíje sípò ààrẹ ṣe gbégbá orókè ní ibùdó ìdìbò wọn nìyí.

Àwọn olùdíje sípò ààrẹ

Bola Tinubu mókè ní ibùdó ìdìbò rẹ̀ l'Ekoo

Bola Tinubu àti ìyàwó rẹ̀, Remi Tinubu lásìkò tó ń dìbò

Olùdíje sípò ààrẹ Nàìjíríà lẹ́gbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, Bola Tinubu gbégbá orókè ní ibùdó ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Eko.

Tinubu rí ìbò 33 nígbà tí Peter Obi tó súnmọ ní ìbò 8.

Atiku Abubakar tẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP rí ìbò ẹyọ̀kan.

Ènìyàn 43 ló dìbò ní ibùdó ìdìbò Tinubu nínú àwọn 324 tó forúkọ sílẹ̀ láti dìbò.

Bí èsì ìdìbò náà ṣe lọ nìyí:

  • APC - 33
  • LP - 8
  • PDP - 1
  • YPP - 1

Atiku Abubakar gbégbá orókè ní ibùdó ìdìbò rẹ̀

Atiku Abubakar lásìkò tó ń dìbò

Oríṣun àwòrán, ATIKU ABUBAKAR

Olùdíje sípò ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP, Atiku Abubakar gbégbá orókè ní ibùdó ìdìbò tó ti dìbò ní ìlú Yola tó jẹ́ ìlú abínibí rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Adamawa.

Èsì ìdìbò ibùdó ìdìbò yúníìtì kejìlá ní Ajiya Gwadabawa ní Yola, PDP rí ìbò 282, tí ẹgbẹ́ òṣèlú APC sì ní ìbò 57.

Ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party rí ìbò mẹ́fà tí NNPP sì ní ìbò ẹyọ̀kan.

  • PDP - 282
  • APC - 57
  • LP - 6
  • Alliance Party - 2
  • NNPP - 1
  • Boot Party - 1

Peter Obi náà gbégbé orókè ní ìpínlẹ̀ Anambra

Peter Obi àti ìyàwó rẹ̀ lásìkò tí wọ́n ń dìbò pẹ̀lú àwòrán èsì ìbò rẹ̀

Peter Obi tó díje lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party náà mókè ní ibùdó ìdìbò rẹ̀ tó ti dìbò ní ìpínlẹ̀ Anambra.

Ní ibùdó ìdìbò yúníìtì 19 ní Agulu, ìjọba ìbílẹ̀ Anambra ni Peter Obi ti dìbò.

Àbájáde èsì ìdìbò náà nìyí:

  • APC - 0
  • APGA - 3
  • LP - 236
  • New Nigeria Peoples Party - 2
  • PDP - 0