2023 Elections: Àwọn nǹkan tí o gbọ́dọ̀ mọ̀ kí o tó lọ sí ibùdó ìdìbò nìyí
Gẹ́gẹ́ bí alakale àjò tó ń rí sí eto idibo ni Naijiria, ìyẹn INEC, lọ́la òde yìí gan ni a ó máa yàn ẹni tí yóò máa gba ipò lọ́wọ́ Ààrẹ Muhammadu Buhari fun saa ọdún mẹ́rin mìíràn àti asoju sì ilé igbimo asofin àpapọ̀ èyí tó wà ní ìlú Abuja.
Báwo ni a ṣe ń dibo gan àti pé àwọn igbese wo ni ènìyàn ni lati tẹ̀lé?
Láàárín Aago mẹ́jọ àárọ̀ sí aago méjì ọsan ni INEC fi lédè pé eto ìdibo fi maa wáyé ní gbogbo ibùdó idibo tó wà ní Nàìjíríà pátápátá.
Ohun tí èyí túmọ̀ sí ní pe ni kété ni eto idibo máa kase nílẹ́, tí ẹnikẹ́ni bá wá sí ibùdó idibo ni aago méjì kọjá iseju kan péré kò lè rí ibo di àmọ́ ó gbogbo àwọn tó bá wà lórí ìlà kí aago méjì tó lu ni wọn ní anfani láti dibo kódà kò jẹ wí pé aago mejo ni gbogbo wọn tó dibo tán.
Kí ẹnikẹ́ni tó lè kopa láti dibo ni Naijiria, ó gbọ́dọ̀ jẹ ọmọ orílẹ̀ èdè yìí, tí pé ọdún méjìdínlógún, ní káàdì idibo alalopẹ àti pé orúkọ rẹ gbọ́dọ̀ wá ní àkọsílẹ̀ ìwé ibùdó idibo tí onítọ̀hún yóò ti dibo.
Tí asiko idibo bá ti tó, abala méjì ni eto naa pin sì, àkọ́kọ́ ni ṣíṣe àyẹ̀wò káàdì idibo èyí tí wọ́n ń pè ní Accreditation tí abala kejì sì jẹ didibo gangan.
- Àwọn ọ̀nà láti fi dá ìròyìn òfégè mọ̀ lásìkò ìbò 2023
- https://www.bbc.com/yoruba/articles/c0w2727ze65o
- Ẹnikẹ́ni tí ọwọ́ bá tẹ̀ tó ń pín ẹ̀bùn tàbí tó ń gba ẹ̀bùn owó fi ra ìbò yóò ṣẹ̀wọ̀n-EFCC
- Ìwádìí BBC tú àṣírí àwọn ojú òpó kàn tó n pín ayédèrú ìròyìn kà nípa ìdìbò Nàìjíríà
- Torí N200,000 ni mo ṣe lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ ajínigbé láti jí bàbá mi gbé - Afurasí
Ní kété tí aago mẹ́jọ bá ti lu ni òṣìṣẹ́ INEC yóò tó àwọn oludibo sórí ìlà gẹ́gẹ́ bí wọn ba ṣe de sibi ibùdó idibo lati ṣe ayẹwo kaadi idibo yin pẹlu imọ ẹrọ BVAS lati fidi rẹ mulẹ pe ibudo idibo to tọ gan-an ni ẹ wa ati pe kaadi idibo yin jẹ ojulowo.
Wọn maa ni ki fi ika yin sibi ẹrọ naa lati ṣayẹwo ọwọ yin. Bakan naa ni wọn yoo wo inu iwe ti akọsilẹ orukọ wa lati mọ boya orukọ yin wa lara awọn to le dibo ni ibudo idibo naa.
Ti wọn ba ti ri orukọ yin ninu iwe naa ni wọn maa ṣe ami si ọwọ yin oe ẹ ti dibo ti wọn yoo si fun-un ni iwe idibo gan-an nibi ti orukọ awọn ẹgbẹ to n dije kọọkan wa, eyi ti wọn buwọlu lẹyin ti wọn si jan lontẹ, lati lọ dibo fun ẹni to wu yin ninu akoto kekere ti wọn ti gbe kalẹ.
Kika ni iwe naa maa wa ti wọn fi ma gbe leeyin lọ́wọ́, bí wọ́n dẹ ṣe ka fun-un yin naa ni ẹyin naa maa ka lati ju u sinu awọn apoti ibo eyi ti wọn gbe kalẹ lati ju u si.
Ofin Naijiria ko fi aye gba ẹnikẹni lati ṣe afihan ẹgbẹ to ba dibo fun léyin to dibo tan o
Ibo didi ti pari niyẹn ti ẹ ba ti ṣe gbogbo eyi tan, nnkan to ku fun-un yin ni lati maa lọ si ile yin tabi ki ẹ jokoo wọọrọwọ lai fa wahala lati ri bi eto idibo naa ṣe ma pari ati bi wọn ṣe maa ka lati kede ẹgbẹ to ba gbegba oroke ni ibudo idibo tẹ ti dibo.
Ẹ o le ṣe ipolongo bi o ti wu ko mọ fun ẹnikẹni tabi maa sọ akọmọna ẹgbẹ oṣelu kankan ni ibudo idibo.
Ko si aye fun awọn nnkan ija oloro tabi awọn nnkan to le da inu fo aya fu silẹ nibudo idibo
Lilo asia ẹgbẹ oṣelu kankan jẹ titẹ ofin idibo loju mọlẹ
Bakan naa ni ko si aye fun jija awọn ohun elo idibo gba lọwọ awọn oṣiṣẹ INEC.
Ọ̀rọ̀ mi ko ni ju bayii lọ na, ipade di ibudo idibo.

