Ẹ̀ lọ sùn lálẹ́ òní, ó di ọ̀sán ọ̀la ká tó bẹ̀rẹ̀ ìkéde èsì ìdìbò - INEC

Oríṣun àwòrán, Others
Alaga ajọ INEC ni Naijiria, Mahmood Yakubu ti kede pe o di ọsan ọjọ isinmi, Ọjọ Kẹrindinlọgbọn, Oṣu keji, ọdun 2023, ki ajọ naa to bẹrẹ si ni kede esi idibo sipo aarẹ ati tawọn asofin apapọ to waye loni.
Yakubu lo kede bẹẹ lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ lori ibi ti ọrọ de duro ninu idibo to n lọ lọwọ naa.
O ni igbagbọ awọn nipe ki o to di ọsan ọla, gbogbo esi yoo ti maa wọle si ibudo ikede esi idibo ni Abuja.
Alaga ajọ INEC ni asiko naa ni awọn yoo bẹrẹ si ni kede esi idibo bo se waye nipinlẹ kọọkan.
‘’Idibo yoo waye laarọ ọla ni awọn agbegbe ti wọn ko tii dibo’’
Mahmood Yakubu fikun un pe gbogbo agbegbe ti idibo ko ti tete waye lọjọ Abamẹta, ni awọn eniyan yoo ti pada dibo.
O ni awọn agbegbe bi Kebbi ti idibo ko i tii waye, ni idibo naa yoo ti waye.
Bakan naa lo ni awọn agbegbe ti rogbodiyan ti bẹ silẹ lasiko idibo ni agbegbe Ikate, Mafoluku, Oshodi ati Surulere ni ipinlẹ Eko ni idibo ti bẹrẹ pada.
‘’A ti da awọn idibo duro ni awọn agbegbe kan ni Esan, ti idibo yoo si waye ni ọṣẹ meji si isinyii, ki gbogbo awọn ọmọ Naijiria le dibo bi wọn ṣe fẹ.’’
‘’Gbogbo awọn ẹṣọ eleto aabo, awọn oniroyin to fi mọ awọn onwoye idibo lo wa ni sẹpẹ lati mọ bi idibo naa ṣe n lọ.’’
‘’A ri pe BVAS ni awọn eniyan n ṣe ikọlu si amọ ati gbaradi fun eyi ti a si ti pese ohun elo miran fun awọn eniyan lati lo.’’
Ọwọ́ wa tẹ obìnrin tó ní káàdì ìdìbò 17 lọ́wọ́ – EFCC

Oríṣun àwòrán, EFCC
Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lorilẹede Naijiria, EFCC ti kede pe ọwọ awọn ti tẹ obinrin kan ni ilu Kaduna to ni kaadi idibo mejidinlogun lọwọ.
Ajọ EFCC lo fi lede loju opo ikansiraẹni wọn lori Twitter.
Ninu akọjade wọn naa ni wọn ti salaye pe agbegbe Badarwa ni ilu Kaduna, ni ipinlẹ Kaduna ni wọn ti ri obinrin naa he.
Arabinrin naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Maryam Mamman Alhaji lo jẹ ọkan lara igbimọ aladuroti ẹgbẹ oṣelu kan ni Naijiria.
‘’POS ni a fẹ fi san owo fun awọn ti wọn fẹ ta ibo wọn’’
‘’Lọwọ rẹ lati ri kaadi ibibo mẹtadinlogun to jẹ ti awọn oludibo pẹlu akọsilẹ nipa aapo isuna wọn ni banki.’’
‘’Bakan naa ni obinrin ọhun ni nọmba awọn eniyan lọwọ ti wọn wa ni wọọdu Badarwa/Malali ward 01 ati 08’’
EFCC ni awọn ri obinrin naa mu nigba ti awọn oṣiṣẹ wọn dibọn bi ẹni pe awọn ni kaadi idibo ti wọn fẹ ta, to si ko si wọn lọwọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Nibayii, Ajọ EFCC ni obinrin naa wa ni panpẹ wọn ni ẹka ileeṣẹ wọn nipinlẹ Kaduna.
Ajọ naa ni awọn n tọpinpin obinrin naa lọwọ lati mọ awọn to n ba ṣiṣẹ ni awọn ojukọ idibo.
EFCC fikun un pe obinrin naa jẹwọ pe awọn n gba kaadi idibo, ti awọn yoo si fi owo ranṣẹ si apo aṣunwọn wọn ni banki.
O ni ọna ti awọn fẹ gba lati pin owo fun awọn eniyan ni lati lo POS lati pin owo naa fun wọn












