Ó dùn mí pé ń kò le dìbò, ẹ̀rọ BVAS kò rí ojú àti ìka mi - Osoba

Gomina tẹlẹri nipinlẹ Ogun, Oloye Oluṣẹgun Ọṣoba ti n ge ika jẹ, to si n kọminu lori bi ko ṣe ri anfani lati dibo aarẹ ati tawọn asofin apapọ.
Idi ni pe ẹrọ BVAS kọ lati fun laaye lati dibo pẹlu bi ko se da ika rẹ mọ.
Gẹgẹ bi akọroyin BBC Yoruba to wa ni agọ idibo se wi, Ọṣoba lo de ibudo idibo rẹ to wa ni wọọdu kẹrinla, yuniiti karundinlogun, Ọmọlolu Housing, Ibara GRA, ni nnkan bi aagọ mọkanla lati dibo, to si to sori ila.
Bi eto naa ṣe kan Ọṣọba lati ṣe ayẹwo, ni ẹrọ BVAS kọ lati sawari orukọ gomina tẹlẹ naa.
Fun bi iṣẹju mẹwaa si ni wọn fi ṣe ayẹwo naa, ṣugbọn pabo lọ jasi.
Pẹlu ẹdun ọkan ni baba naa fi kuro ni ibudo idibo naa, ti ko jinna si ile rẹ.
Ohun to si ṣẹlẹ yii lo ya pupọ awọn oludibo to wa nibẹ lẹnu wi pe ayẹwo BVAS naa ko gba gomina tẹlẹri laaye lati dibo.
Lẹyin wakati mẹta, iyẹn ni deedee aago kan kọja iṣẹju meji ni Oloye Ṣẹgun Ọṣọba tun pada si ibudo idibo rẹ lati dibo, to si tun jẹ bakan naa.
Wọn ni gbogbo igbesẹ ti awọn oṣiṣẹ INEC gbe lati le jẹ ki ẹrọ BVAS naa gba Ọṣọba lo ja si pabo.

Ìbanujẹ ló jẹ́ fún mí pé ń kò dìbò – Osoba
Ninu ọrọ rẹ, Ọṣọba sọ pe “Mi o le dibo mi, ẹrọ BVAS naa tun kuna lati jẹ ki n dibo.
“Mo ti wa nibi lẹẹmeji ọtọọtọ lati dibo, ṣugbọn BVAS naa ko ri oju ati ọwọ mi.
Ti mo ba gbiyanju lati dibo lai jẹ pe BVAS yii ṣiṣẹ fun mi, o le jẹ ki wọn wọgile eto idibo to waye nibi.
Kaadi ti mo lo lakoko idibo ọdun 2019 naa ni mo tun mu wa sibi lati fi dibo, ibi ti mo ti n dibo naa ree.
Mi o dibo nitori pe mi o fẹ ki wọn wọgile ọgọrun ibo nitori ibo ẹyọ kan ṣoṣo ti emi di.
Ohun to ṣẹlẹ yii ba mi lọkan jẹ gidigidi, ṣugbọn mo ti gba kadara mi.
Iru eyi ko le ṣe ko ma ṣẹlẹ. Sibẹ o tun jẹ iwuri fun mi pe awọn eeyan jade lọpọ yanturu lati dibo.
Mo ri awọn agbaagba ti wọn jade lati dibo, o si fi mi lọkan balẹ wi pe APC maa bori.”












