Wo àwòrán mánigbàgbe ìdìbò ààrẹ àti tàwọn aṣòfin àpapọ̀

Àwòrán àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ lásìkò ìbò ààrẹ 2023
Bàbá ẹni ọdún mẹ́tàléláàdọ́rùn-ún ní ìlú Anambra inú òun dùn láti tún kópa nínú ètò ìdìbò
Àkọlé àwòrán, Bàbá ẹni ọdún mẹ́tàléláàdọ́rùn-ún ní ìlú Anambra inú òun dùn láti tún kópa nínú ètò ìdìbò
Àwọn ènìyàn tó ń ta àkàrà lásìkò ti ètò ìdìbò ń lọ lọ́wọ́
Àkọlé àwòrán, Àwọn ènìyàn tó ń ta àkàrà lásìkò ti ètò ìdìbò ń lọ lọ́wọ́
Àwọn bàbá arúgbó yìí kọ̀ láti jókòó ní ilé wọn ní ìpínlẹ̀ Ondo, wọ́n ní ojúṣe àwọn ni láti kópa nínú yíyan adadí tuntun fún Nàìjíríà.
Àkọlé àwòrán, Àwọn bàbá arúgbó yìí kọ̀ láti jókòó ní ilé wọn ní ìpínlẹ̀ Ondo, wọ́n ní ojúṣe àwọn ni láti kópa nínú yíyan adadí tuntun fún Nàìjíríà.
Àwọn ọ̀rẹ́ kòrí kòsùn tí wọ́n jọ kó ara wọn lọ sí ibùdó ìdìbò láti lọ dìbò fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ìgbé ayé wọn
Àkọlé àwòrán, Àwọn ọ̀rẹ́ kòrí kòsùn tí wọ́n jọ kó ara wọn lọ sí ibùdó ìdìbò láti lọ dìbò fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ìgbé ayé wọn.
Edith
Àkọlé àwòrán, Edith kọ̀ láti padà sílé lẹ́yìn tó ti jókòó fún wàkátì méjì tí àwọn òṣìṣẹ́ INEC kò tètè dé ibùdó ìdìbò rẹ̀ ní agbègbè Ogbà ní ìpínlẹ̀ Eko. Ó ní ìgbà àkọ́kọ́ tí òun ń dìbò rèé àti pé yóò dúró títí àwọn òṣìṣẹ́ INEC máa fi dé kódà kó jẹ́ alẹ́.
Àwọn bàbá arúgbó yìí ń bèèrè fún àtúnṣe sí ìlànà tí à ń gbà dìbò ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà kó le mú ìrọ̀rùn bá àwọn ènìyàn pàápàá àwọn arúgbó.
Àkọlé àwòrán, Àwọn bàbá arúgbó yìí ní ìpínlẹ̀ Ogun ń bèèrè fún àtúnṣe sí ìlànà tí à ń gbà dìbò ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà kó le mú ìrọ̀rùn bá àwọn ènìyàn pàápàá àwọn arúgbó.
Àwọn tó jẹ́ àkàndá ènìyàn kò jẹ́ kí ìpèníjà ara wọn dá wọn dúró láti ṣe ojúṣe wọn
Àkọlé àwòrán, Àwọn tó jẹ́ àkàndá ènìyàn kò jẹ́ kí ìpèníjà ara wọn dá wọn dúró láti ṣe ojúṣe wọn.
Ẹni to ní ìpèníjà ojú ní Ogbomoso, ìpínlẹ̀ Oyo
Àkọlé àwòrán, Ọkan l'ara awọn to ni ipenija oju n lo braille lati tọka si ojú ẹgbẹ oṣelu to fẹ dibo fun ni wardu 9 Osupa, Ogbomoso
Awọn ọdọ kan sọ oju popo di papa isere bọọlu lagbegbe Osodi nilu Eko lasiko idibo apapọ to n lọ lọwọ.
Àkọlé àwòrán, Awọn ọdọ kan sọ oju popo di papa isere bọọlu lagbegbe Osodi nilu Eko lasiko idibo apapọ to n lọ lọwọ.
Àwọn aláboyún náà kò gbẹ́yìn láti ṣe ojúṣe wọn
Àkọlé àwòrán, Àwọn aláboyún náà kò gbẹ́yìn láti ṣe ojúṣe wọn, wọ́n ní ọjọ́ ọ̀la àwọn ọmọ àwọn ni àwọn ń jà fún.
Àwọn olóúnjẹ yìí lo àkókò ìbò yìí láti pawó sápò.
Àkọlé àwòrán, Àwọn olóúnjẹ yìí lo àkókò ìbò yìí láti pawó sápò.
Àwọn ènìyàn kọ̀ láti lọ sílé àyàfi tí àwọn bá dìbò tán ní alẹ́, iná orí fóònù wọn ni wọ́n fi arí ètò ìdìbò náà.
Àkọlé àwòrán, Àwọn ènìyàn kọ̀ láti lọ sílé àyàfi tí àwọn bá dìbò tán ní alẹ́, iná orí fóònù wọn ni wọ́n fi arí ètò ìdìbò náà.
Ìyá ọmọ ìkókó yìí gbé ọmọ rẹ̀ wá sí ibùdó ìdìbò láti wá dìbò yan ẹni tí wọ́n tó fẹ́ láti tukọ̀ Nàìjíríà fún ọdún mẹ́rin mìíràn.
Àkọlé àwòrán, Ìyá ọmọ ìkókó yìí gbé ọmọ rẹ̀ wá sí ibùdó ìdìbò láti wá dìbò yan ẹni tí wọ́n tó fẹ́ láti tukọ̀ Nàìjíríà fún ọdún mẹ́rin mìíràn.
Àwọn jàǹdùkú da ibùdó ìdìbò rú ní Eko
Àkọlé àwòrán, Àwọn jàǹdùkú da ibùdó ìdìbò rú ní Eko
Onírèké ń bá títà ìrèké rẹ̀ lọ ní ibùdó ìdìbò
Àkọlé àwòrán, Onírèké ń bá títà ìrèké rẹ̀ lọ ní ibùdó ìdìbò.
Awọn agunbanirọ to sisẹ fun ajọ INEC
Àwọn àgùnbánirọ̀ sùn sílẹ̀ lẹ́yìn tí wan parí iṣẹ́ tán lálẹ́
Àkọlé àwòrán, Àwọn àgùnbánirọ̀ sùn sílẹ̀ lẹ́yìn tí wan parí iṣẹ́ tán lálẹ́.