"Mo gbọ́ ìró ìbọn ní àgọ́ ìdìbò, mo sì ri tí ẹ̀jẹ̀ ń dà lójú mi"
Jennifer Efidi, ẹni tó fara pa lásìkò tó fẹ̀ bò ṣàlàyé bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé fún BBC

“Nígbà tí mo dé ibùdó ìdìbò mi, mo ri pé èrò pọ̀ púpọ̀, mo sì tò sórí ìlà lẹ́yìn tí mo ṣe àyẹ̀wò orúkọ mi láti mọ̀ bóyá mo lẹ̀tọ̀ọ́ láti dìbò níbẹ̀. Lẹ́yìn tí mo rí orúkọ mi ni mo lọ jókòó láti dúró de ìgbà tó ma kàn mí láti dìbò. Ìgbà náà ni mo dédé gbúròó ìbọn.”
Nǹkan tí mo arábìnrin Bina Jennifer Efidi sọ nìyí nígbà tó ń sọ ìrírí rẹ̀ lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ si nígbà tó lọ dìbò ààrẹ àti sílé ìgbìmọ̀ aṣòfin.
Ńṣe ni àwòrán Bina Jennifer Efidi pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ní gbogbo ara, tí ojú rẹ̀ sì wú gba orí ayélujára ní òpin ọ̀sẹ̀ lásìkò tó lọ ń dìbò ní ìpínlẹ̀ Eko tí àwọn ènìyàn sì ń kan sáárá si.
Ìròyìn tó gbalẹ̀ ni pé Edifi padà lọ sí ibùdó rẹ̀ láti lọ dìbò lẹ́yìn tó gba ìtọ́jú tán lẹ́yìn tí àwọn kan ṣe ìkọlù si.
Nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ yìí, Edifi ṣàlàyé bí gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé fún BBC, tó sì tún ṣàlàyé ìdí tó fi padà lọ dìbò.
"Mo ṣàdédé gbọ́ ìró ìbọn"
Edifi ṣàlàyé pé òun kò lérò wí pé nǹkan tó ṣẹlẹ̀ náà le ṣẹlẹ̀ sí òun nítorí ibùdó ìdìbò òun kò jìnà sí ilé rárá àti pé wọn kìí fa wàhálà ní ibùdó látẹ̀yìnwá.
“Nígbà tí mo dé ibùdó ìdìbò mi, mo ri pé èrò pọ̀ púpọ̀, mo sì tò sórí ìlà lẹ́yìn tí mo ṣe àyẹ̀wò orúkọ mi láti mọ̀ bóyá mo lẹ̀tọ̀ọ́ láti dìbò níbẹ̀.”
“Kò pẹ́ púpọ̀ ni àwọn àwọn ọmọ ìta kan ya dé sí ibi tí a tò sí láti dìbò, wọ́n wá sí ẹgbẹ́ ibi tí mo jókòó sí.”
“Kò jú bíi ìṣẹ́jú ọgbọ̀n lọ lẹ́yìn náà ni mo kàn dédé ri pé nǹkan bàmí níbi ojú bí ẹni wí pé ẹnìkan ju nǹkan bàmí lójú.”
“Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ náà ni mo gbọ́ ìró ìbọn, ó dàbí ẹní pé wọ́n yin ìbọn fún mi, àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí ní sá àsálà fún ẹ̀mí wọn, mo kàn di ojú mi mú, tí mo sì ń pàrìwò fún ìrànlọ́wọ́ ṣùgbọ́n kò sí ẹnikẹ́ni tó ṣetán láti rànmí lọ́wọ́.”
Ó ní òun sáré wọ inú ilé kan níbi tí obìnrin kan tó jẹ́ ará àdúgbò òun kan tí ẹni náà sì fi aṣọ gba ẹ̀jẹ̀ tó ń dà lójú òun.
“À ń pè fún ìrànlọ́wa àmọ́ kò sí ẹnikẹ́ni tó dá wa lóhùn, gbogbo wọn kàn ń ti ilẹ̀kùn mọ́ra.”
Efidi ní nítorí ẹ̀jẹ̀ púpọ̀ tí òun ti pàdánù, ọkọ̀ òun gbé òun lọ sí ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú.”
Ó ní ọ̀nà mẹ́rin ni wọ́n ti rán àwọn ibi tí òun ó ya lójú òun, tí òun sì gba abẹ́rẹ́ àti oògùn.
"Ìdí tí mo fi padà lọ dìbò"

"Kò sí ẹ̀ṣọ́ ààbò kankan ní ibùdó ìbò tí mo wà"
“Mo mọ̀ wí pé ìbò mi máa mú àyípadà wá ló jẹ́ kí n padà lọ láti lọ dìbò.”
Efidi ní ìdí tí òun fi padà lọ sí ibùdó ìdìbò lẹ́yìn tí òun kúrò ní ilé ìwòsàn nìyí pẹ̀lú ọgbẹ́ lójú.
Ó ní nígbà tí òun padà sílé òun ri wí pé àwọn ènìyàn tún ti ń dìbò lọ tí òun gbogbo ti padà bọ̀ sípò ni òun ṣe pinnu láti tún lọ dìbò.
Ó fi kun pé ó ya òun lẹ́nu pé kò sí ẹ̀ṣọ́ ààbò kankan ní ibùdó ìbò àwọn léyìí tó fún àwọn ọmọ gànfé láàyè láti wá ṣe ìkọlù sí àwọn.
“Wọ́n ju àpótí ìbò nù, tó bá jẹ́ wí pé àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò wà nílẹ̀ ni, bóyá èyí kò bá má ṣẹlẹ̀.”
Ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé kò sí ẹni tó le dá ẹnikẹ́ni tó bá ti ni ìpinnu láti ṣe nǹkan dúró.















