Ẹ̀yin ará Eko, ẹ gba àlááfíà laaye, mìmì kan kò le mìwá – Asiwaju Ahmed Tinubu

Oríṣun àwòrán, Others
Oludije sipo aarẹ ni ẹgbẹ oṣelu APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ti kesi awọn ara ipinlẹ Eko lati gba alaafia laaye.
Tinubu sọ eyi ninu atẹjade to fi lede nipa iroyin rogbodiyan to bẹ silẹ ni awọn agbegbe kan nipinlẹ Eko nitori esi idibo sipo aarẹ ni Naijiria.
Lẹyin ti wọn ni awọn onijagidijagan kan ṣe ikọlu si awọn eniyan to wa lati ẹya igbo amọ ti wọn n gbe nipinlẹ Eko.
O ni ki awọn ara ilu gba esi idibo aarẹ ti INEC kede nibi oludije sipo aarẹ ni ẹgbẹ oselu Labour party, Peter Obi ti bori nipinlẹ Eko gẹgẹ bi ifẹ awọn eniyan.
Tinubu ni ohun to mu ki ijọba tiwantiwa wuyi ni pe awọn eniyan ni ẹtọ lati dibo fun ẹni to ba wu wọn.
Bakan naa ni oludije sipo aarẹ naa ni gẹgẹ bi ẹni to fẹran ijọba tiwantiwa, ohun gbọdọ gba esi idibo naa ni alaafia.
Tinubu to jẹ gomina nipinlẹ Eko ri wa bu ẹnu atẹ lu awọn to n fa wahala ni Eko, to si ni ki wọn tẹ ọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ.
Nitori pe ẹgbẹ oselu wa kuna perete ni idibo to waye nipinlẹ Eko naa ko ni ki awọn eniyan maa da wahala silẹ.’’
Gẹgẹ bi ẹni to nifẹ ijọba tiwantiwa, agba wi pe eniyan le gberi soke ni agbegbe kan, ko si padanu ni agbegbe miran.
Nitori naa a gbọdọ gba alaafia laye nipinlẹ Eko ki eto idibo naa le lọ ni irọwọrọsẹ.
Dino Melaye fi ẹ̀họ́nú hàn lórí èsì ìdìbò tí INEC ń kà ní Abuja

Ṣẹnetọ to n ṣoju ẹgbẹ oṣelu PDP nibi ti wọn ti n ka esi idibo ni ilu Abuja ti kesi Ajọ INEC lati gba ọna to tọ lati kede esi idibo naa.
Dino Melaye lo fi aidunnu rẹ han lasiko ti wọn n ka esi idibo aarẹ ni ilu Abuja.
Dino ni ohun ti awọn fẹ ni ki INEC fi esi idibo si oju ẹrọ wọn lori ẹrọ ayelujara.
‘’Gẹgẹ bi atunṣẹ ti ajọ INEC ṣẹ ninu iwe ofin ti ọdun 2022, INEC ṣeleri fun awọn ọmọ Naijiria pe wọn yoo ri esi idibo ni ẹrọ ayelujara INEC to yẹ ki esi idibo wa.’’
‘’Ohun to yẹ ko waye ni ki wọn fi esi naa si ori ẹrọ ayelujara ki a le gbagbọ pe ko si magomago ninu esi idibo naa.’’
Bakan naa ni awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu ADP ati PRP ṣe agbatẹru ohun ti Dino Melaye sọ.
Amọ alaga ajọ INEC, Mahmood Yakubu ninu idahun rẹ ni pe awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu ti yẹ ki wọn sọrọ nipa fifi esi idibo si ori ẹrọ ayelujara wọn.
‘’Esi idibo gba ọna mẹrin kọja ko to de Abuja nibi ti a ti n ka esi idibo naa lakotan.’’
Gbogbo kudiẹ-kudiẹ ti ẹ ba ṣakiyesi ninu esi idibo naa yẹ ki ẹ ti bere nipa rẹ ni esi idibo ti wọn ka ni agọ idibo, to si lọ si wọọdu lati ibẹ.’’’
‘’Lẹyin naa lo lọ si ijọba ibilẹ, ki wọn to gbe esi idibo naa sita ni ipinlẹ.’’
Bakan naa ni Mahmood kesi Dino Melaye lati maṣe dabaru kika esi idibo naa ru
Akala, Adeyemi, Akinremi jawe olúborí sílé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin ní ìpínlẹ̀ Oyo

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK
Wọn ti kede Olamijuwonlo Akala gẹgẹ bi ẹni ti o bori ibo sile igbimọ aṣojuṣofin apapọ tẹkun idibo Ogbomoso.
Ọmọ gomina tẹlẹ ri ni ipinlẹ Oyo naa, dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC sile igbimọ aṣojuṣofin lati lọ ṣoju ẹkun idibo Gusuu Ogbomoso/Ariwa Ogbomoso ati ijọba ibilẹ Oriire.
Olamijuwonlo Akala ẹni to ti jẹ alaga tẹlẹ ri nijọba ibilẹ guusu Ogbomoso nigba kan ri dije pẹlu oludije ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) Olufemi Onireti.

Oríṣun àwòrán, Facebook
Ọjọgbọn Hakem Olarenwaju kede pe o bori pẹlu ibo ẹgbẹrun mẹtalelọgbọn ti Olufemi Onireti ti ẹgbẹ oṣelu PDP ni ibo ẹẹdẹgbẹẹrinla le diẹ
Ọjọgbọn Salami, lasiko to n kede Olamojuwonlo Akala gẹgẹ bi ẹni to bori ibo naa ni gbọngan ilu Ogbomoso, o ni “Mo kede Olamojuwonlo Akala gẹgẹ bi olubori ninu eto idibo Gusuu/AriwaOgbomoso ati ijoba ibilẹ Orire pẹlu ibo ẹgbẹrun mẹtalelọgbọn ti Olufemi Onireti ti ẹgbẹ oṣelu PDP ni ibo ẹẹdẹgbẹẹrinla le diẹ.
Olamiju Akala lẹyin ikede jẹjẹẹ pe oun ko ni ja awọn to dibo yan oun kulẹ ninu ojuṣe oun.
Ọmọ Aláàfin, Akeem Adeniyi Adeyemi wọlé fún ìgbà kẹta.

Oríṣun àwòrán, Akeem Adeniyi Adeyemi/Facebook
Akeem Adeniyi Adeyemi, ọkan lara awọn ọmọ Alaafin Ọba Lamidi Adeyemi ti ilu Oyo to gbesẹ laipẹ jawe olubori ni ijọba ibilẹ Atiba, Afijio, ila oorun ati iwọ oorun Oyo.
Adeyemi to n ṣoju ẹkun idibo naa lọwọlọwọ ni ile igbimọ aṣojuṣofin labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC ni o tun ri iyansipo pada labẹ ẹgbẹ kan naa.
Igba ẹkẹta niyi ti Akeem Adeyemi yoo wọle gẹgẹ bi aṣoju ni ilu Oyo.
Abajade esi ibo rẹ ni wọn kede ni gbọngan ikojọpọ fun ẹkun idibo ijọba apapọ to wa ni agbegbe ọfiisi ajọ eleto idibo ti orilẹede (INEC) ni ijọba ibilẹ Ọyọ East ni agbegbe Akunlemu niluu Ọyọ.
Lapapọ, Adeyemi ni ibo to le ni ẹgbẹrun mẹrinlelọgbọn (34,822 ) lati bori gbogbo awọn oludije miiran ti wọn jọ kopa ninu eto idibo naa.
Awọn oludije miiran ti wọn jọ dupo ni Mudashiru Kamil Akinlabi ti ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) ti oun ni ibo to le ni ẹgbẹrun kan lelọgbọn (31,671) ti Oyedemi Oyeleru ti Accord gba ibo to le ni ẹgbẹrun mẹtala lapapọ (13,544).
Ni Ibadan, Akinremi borí

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK
Ọmọọba Musliudeen Olaide Akinremi ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, lo jawe olubori nibi abajade idibo fun ẹkun ijọba apapọ ti Gusuu Ibadan fun igba keji.
Wọọdu mejila ni eto idibo naa ti waye ni ọjọ Satide.
Nigba to n kede abajade esi idibo ni bi aago mẹfa irọlẹ ni ọjọ Aiku, Dokita Adeleke Ayodeji Adewole sọ pe Akinremi gba apapọ ibo ẹgbẹrun mọkanlelogun le diẹ (21,135) lapapọ lati bori ti awọn to n ba dije.
Lanre Sarumi ti PDP ri ibo ẹgbẹrun mẹrindinlogun le ọgọta (16,060) nigba ti oludije ẹgbẹ Accord, Umar Faruk Arisekola-Alao ri apapọ ibo ẹgbẹrun mẹjọ le diẹ (8,108).
Ẹgbẹ oṣelu PDP rọwọ mu ni Oke Ogun

Oríṣun àwòrán, Facebook
Oludije ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party, PDP, fun agbegbe Iseyin/Itesiwaju/Iwajowa/Kajola Najeemdeen Oyeshina Oyedeji ni wọn kede gẹgẹ bi olubori ninu eto idibo agbegbe naa.
Oyedeji ni apapọ ibo to le ni ẹgbẹrun lọna ọgbọn (30,372) nigba ti oludije ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Soliu Abu Gbadamosi ni apapọ ibo to le ni ẹgbẹrun lọna mejidinlọgbọn (28,821.)
Oludije Accord Party, Samson Ogunbode ni ibo ẹgbẹrun mẹtadinlogun le die (17,532, ).
Ọjọgbọn Adeolu Adeleke aṣoju ajọ INEC kede Najeemdeen Oyeshina gẹgẹ bi ẹni ti o bori.












