Bola Tinubu tó di ààrẹ, PDP àbí APC ni yóò gbè fún nínú ìbò gómìnà l‘Oyo?

Esi ibo aarẹ to kọja, nibi ti ẹgbẹ oselu APC ti bori nipinlẹ Oyo ti n fa awuyewuye bayii.
Idi ni pe awọn eeyan kan n sọ kiri pe adehun kan wa laarin aarẹ tuntun, Bola Tinubu ati gomina Seyi Makinde, to jọ mọ adehun bu fun mi, ki n bu fun ọ.
Amọ bi ẹgbẹ oselu APC se n sẹ pe ko si adehun kankan, ni PDP n yinmu si wọn.
"Sátidé ni ẹ́ mọ̀ bóyá Makinde ló jẹ́ kí Tinubu wọlé l‘Oyo àbí bẹ́ẹ̀kọ́"
Nibayii ti Bola Tinubu ti di aayo iyawo, ti ẹgbẹ oselu PDP ati APC nipinlẹ Oyo n du mọ ara wọn lọwọ lo mu ki BBC Yoruba tọ awọn agbẹnusọ fun ẹgbẹ oselu mejeeji nipinlẹ Oyo lọ, lati tanna wadi idi ti ariwo fi pọ lori ajọsepọ Makinde ati Tinubu pẹlu Folarin.
A si fẹ mọ idi ti wọn fi lero pe bi asiwaju Bola Tinubu se wọle ipo aarẹ yoo ni ipa lori abajade esi ibo gomina to n bọ nipinlẹ Oyo.
"Tinubu kò sé àdéhùn àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Makinde, ìfẹ́ Asiwaju ni ará Oyo fi dìpò ààrẹ fún APC "
Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ipinlẹ Ọyọ ti ṣelaye wipe abewo ti Aarẹ tuntun ti ilu dibo yan, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ṣe si ọfisi Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ọnimọẹrọ Ṣeyi Makinde saaju eto idbo aarẹ ko ni ohunkohun ṣe pẹlu bi ẹgbẹ oṣelu APC ṣe wọle n'ipinlẹ Ọyọ.
Ninu ọrọ ti alukoro fun ẹgbẹ oṣelu naa, Ọlawale Ṣadare ba BBC Yoruaba sọ, o ni ifẹ ti awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ ni si Tinubu ati ẹgbẹ oṣelu to ti jade lo mu ki wọn dibo fun un.
Lodi si iroyin to n lọ kaakiri wipe adehun to wa laarin Tinubu ati Makinde lo mu ki ẹgbẹ oṣelu APC wọle ni ipinlẹ Ọyọ, bẹrẹ lati 'Unit 001, Ward 11' nibi ti Ṣeyi Makinde ti dibo aarẹ, Ṣadare ni,
"Ẹnikẹni ti o ba ni fọnran ibi ti Makinde ati Tinubu ti jọ ṣe adehun ko mu fọran naa jade.
Ṣe lori BBC Yoruba ni, tabi BCOS?
"Ko si ibi ti Makinde ti sọ fun ẹnikẹni pe ki wọn dibo fun Tinubu, ohun to wu aralu lo ṣe."
Ṣadare ni awọn oludibo ipinlẹ Ọyọ kii darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu alatako.
O ni ilepa wọn ni bi ẹgbẹ to wọle idibo Aarẹ loke yoo ṣe wọle ibo Gomina n'ipinlẹ naa.
O fikun ọrọ rẹ pe ninu eto si ipo Gomina ti yoo waye lọjọ kọkanla oṣu kẹta ọdun yii, ni awọn eeyan yoo ti mọ boya Makinde lo jẹ ki Tinubu wọle n'ipinlẹ Ọyọ, tabi bẹẹ kọ.
Saaju ni igbimọ ipolongo ibo fun oludije ipo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC fi ọrọ lede wi pe ko si adehun kankan laarin ẹgbẹ naa ati Makinde gẹgẹ bi iroyin ṣe n gbee kaakiri.
Ọkan lara awọn aṣoju igbimọ naa, Arabinrin Nike Ajagbe lo fi idi ọrọ yii mulẹ nibi ipade awọn oniroyin kan to waye l'Ọjọru, nilu Ibadan.
Ajagbe ni abẹwo ti igbimọ ipolongo ibo ṣe si ọfisi Makinde pẹlu Tinubu saaju eto idibo ko tumọ si pe wọn fi ọwọ si igbiyanju rẹ lati ṣe Gomina lẹẹkeji.
O ni Aarẹ tuntun ti ara ilu ṣẹṣẹ dibo yan jẹ ẹnikan ti kii fi ẹgbẹ oṣelu rẹ ṣere, ti o si tumọ si wi pe gbogbo ipa ni yoo sa ti ẹgbẹ APC yoo fi wọle ni Iwọ-oorun Gusu ti o jẹ ibudo agbara rẹ.
Tinubu to wọle n'ipinlẹ Ọyọ kii ṣe iṣẹ ọwọ APC bikoṣe aṣa wi pe 'Yoruba lo kan - PDP Oyo
BBC Yoruba wa kan si alukoro ẹgbẹ oṣelu PDP n'ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Akeem Ọlatunji lati fesi si gbogbo ọrọ to wa nilẹ yii.
Alaye ti o ṣe ni pe awọn ko mọ ohun to ṣokunfa ariwo ti ẹgbẹ oṣelu APC n pa.
O ni Tinubu to wọle n'ipinlẹ Ọyọ kii ṣe iṣẹ ọwọ APC bikoṣe aṣa wi pe 'Yoruba lo kan' ati wi pe gbogbo awọn Gomina orilẹede Naijiria ṣe ipada kan ni bii ọdun kan sẹyin n'ipinlẹ Delta, nibi ti wọn ti fi ohun ṣọkan wi pe ki ipo aarẹ yi wa si ẹkun Guusu.
O ni eyii ni ọpọlọpọ awọn eeyan to wa ni ipinlẹ Ọyọ ti gbe si ọkan, ti o si mu ki o nira lati kan an nipa fun awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP pe ki wọn dibo fun oludije fun ipo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu naa.
O ni Tinubu to wọle ko tumọ si wi pe ara ilu ipinlẹ Ọyọ n fẹ ẹgbẹ oṣelu APC.
Ọlatunji ni ọgọrọ awọn eeyan to dibo fun Tinubu lo mu ki pupọ ninu awọn to n dije du ipo ile igbimọ aṣofin ninu ẹgbẹ oṣelu PDP padanu ibo wọn, gẹgẹ bi o ṣe waye lasiko ti ọgọrọ awọn eeyan dibo fun Mohammadu Buhari lọdun 2019.
O ni bi Tinubu ṣe wọle loke ko le ṣe idiwọ fun Makinde lati ma wọle ẹlẹẹkeji nitori iru ẹ ti ṣẹlẹ ri lọdun 2011, ti awọn eeyan ilu ipinlẹ Ọyọ dibo fun ẹgbẹ PDP ninu ibi aarẹ ṣugbọn ti wọn tẹ ika wọn fun ẹgbẹ oṣelu ACN ninu eto idibo fun ipo Gomina.
Ìjọba Seyi Makinde tí sú aráàlú ní wọn fí tó sẹ́yìn ẹgbẹ́ òṣèlú APC - Yunus Akintunde

Sẹnetọ ti won ṣẹṣẹ dibo yan nipinlẹ Oyo, Yunus Akintunde ti sọrọ lori bo se jawe olubori ninu eto idibo sipo Sẹnetọ fun aarin gbungbun ipinlẹ Oyo.
Akintunde ni eyi ko sẹyin bi awọn oludibo nipinlẹ Oyo ṣe kọ ẹyin si isejọba Gomina Seyi Makinde ati ẹgbẹ oselu PDP.
Akintunde, ninu ifọrọwerọ pẹlu akọroyin BBC Yoruba lẹyin ti wọn kede rẹ gẹgẹ bi Sẹnetọ ti wọn dibo yan, salaye pe abajade esi idibo fihan pe awọn eeyan ipinlẹ Oyo fẹran ẹgbẹ oṣelu APC.
O wa fi ọwọ gbaya pe lakọ ni ẹgbẹ oselu naa wa saaju eto idibo gomina to n bọ.
Ti a ko ba gbagbe, pupọ awọn to padanu ibo abẹle ninu ẹgbẹ naa lo lọ si ẹgbẹ oṣelu Accord ati awọn ẹgbẹ oṣelu miiran.
Sugbọn esi ibo ọsẹ to kọja ti fihan pe ọpọlọpọ wọn ni ko si ami pe ẹgbẹ naa rẹyin ninu abajade esi idibo yii.
Akintunde ni yoo nira diẹ fun oludije PDP ati Gomina ipinlẹ Oyo lati fi ẹgbẹkẹgbẹ pẹlu ẹgbẹ oṣelu APC.
‘Ko si adehun kankan laarin ẹgbẹ oṣelu PDP ati APC pe wọn yoo sisẹ fun aseyọri Tinubu’
Akintunde salaye lori boya Gomina ipinlẹ Oyo Seyi Makinde ba ẹgbẹ APC sisẹ pọ, eyi to jẹ kí wọn le jawe olubori ninu eto idibo.
“Ko si adehun tàbí ọrọ ajọsọ kankan laarin ẹgbẹ APC ati Seyi Makinde.
”APC n bọ lati mu idẹrun de fun awọn eeyan ipinlẹ Oyo.”
‘Lẹyin owo oṣu sisan, Makinde ko ni aṣeyori nipinlẹ Oyo’
Akintunde salaye pe lẹyin sisan owo oṣu awọn osisẹ ti Makinde mu ni ọkunkundun, pupọ awọn ohun titura lo n jẹ awọn araalu niya
“Iṣejọba Gomina Seyi Makinde ti su ọpọlọpọ nitori wi pe Makinde kò ṣe ijọba ipinlẹ daradara,
“Yatọ si owo oṣu ti Makinde n san dede gbogbo awọn ẹka ijọba to ṣeku ni wọn pariwo.”
“Eto abo to ti mẹhẹ ni ka wi ni ,tabi awọn kudie kudie ti ijọba Seyi Makinde n ṣe
“Ona kan ti awọn ara ipinlẹ Oyo le fi sọrọ ni bi wọn ti diboyan gbogbo aṣoju ẹgbẹ oṣelu APC gẹgẹbi Gomina ati Sẹnẹtọ.
Akintunde rọ awọn ọmọ ipinlẹ Oyo lati diboyan aṣoju ẹgbẹ APC gẹgẹ bi Gomina ipinlẹ Oyo.
O ní botilẹ jẹ wi pe ọpọlọpọ rogbodiyan lọ bẹ silẹ ṣaaju eto idibo ninu eyi ti owongogo epo bẹntiro aisi owo naira tuntun waye,O ni gbogbo iṣẹlẹ ko fi oun rara nitori ife Ọlọrun lọ ṣe.
Akintunde ṣeleri lati jẹ aṣoju daradara fun gbogbo awọn ara ijọba ibilẹ mọkanla ti o jẹ Sẹnetọ wọn.
O ni laarin ọdun kan ti oun ba bẹrẹ isẹ gẹgẹ bi Sẹnetọ idagba soke yo yaa.
















