Màá fẹ̀yìntì nínú òṣèlú lẹ́yìn ìbò gómìnà láti gbé níbi tó wù mí, bóyá Ghana, Togo àbí Nàíjíríà - Bode George

Bode George ati Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Collage

Agba oselu kan nipinlẹ Eko, to tun jẹ eekan oloselu ninu ẹgbẹ oselu PDP, Oloye Olabode George ti kede pe oun yoo fi adagba eto oselu rọ, ni kete ti ibo gomina ba pari.

Bode George sisọ loju ọrọ naa lasiko to n kopa lori eto ori mohunmaworan kan tileesẹ Arise gbe jade.

George, ẹni to n fapa janu lori esi ibo aarẹ to gbe Bola Tinubu wọle wa naka abuku si alaga ajọ INEC, Yakubu Mahmood lori bi ko se mu ileri to se fọmọ Naijiria sẹ.

"Ko ba a jẹ Ghana, Togo tabi Naijiria, mo le lọ gbe nibikibi"

O wa rọ INEC lati jẹ ki ifẹ araalu sẹ lasiko idibo gomina ti yoo waye lọsẹ to n bọ.

“Mo ti pinnu pe lẹyin eto idibo gomina ni maa fẹyin ti ninu oselu sise, maa si ni ominira lati maa gbe nibi kibi to ba wu mi.

Ko baa jẹ orilẹede Ghana ni, tabi Togo tabi ni orilẹede Naijiria, mo le lọ gbe nibikibi.

Mo n fẹ igbe aye ifọkanbalẹ fun ara mi, mo si mọ ọkunrin ti wọn n pe ni Tinubu yii daadaa.

Eeyan ko le gba inu okunkun lati ri imọlẹ, n ko ba si ki ku oriire to ba jẹ pe ọna to tọ lo gba dori aleefa.”

Ìkéde Tinubu bíi ààrẹ, dàbí ẹni pé ọfọ wọ̀lú ni - Bode George

Àfi èmi, èmi ló kàn, Ìwọ ló kàn ní gbogbo ìgbà, lórí irọ́ - Bode George

Aworan Bode George ati Bola Tinubu

Agba ọjẹ ninu fẹgbẹ oṣelu PDP, Oloye Bode George ti bu ẹnu atẹ lu esi ibo to kede Bola Tinubu, gẹgẹ bii aarẹ tuntun fun orilẹede Naijiria.

Oloye Bode George ni ikede ofege, ti ko ni itẹwọgba rara ni esi ibo naa.

Bode George, nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori esi ibo aarẹ ti INEC kede rẹ ni ọna eru ni Bola Tinubu, fi wọle sipo aarẹ.

Agba oselu naa ni eyi ri bẹẹ nitori bi ajọ INEC ṣe kuna lati kedi esi idibo lati ori ẹrọ BVAS.

O ni igba idẹra jina si orilẹede Naijiria pẹlu igbesẹ naa.

"Ki lo jẹ igba idẹra, Ọlọrun ma ma jẹ ka rin nigba ti esu n rin, ile ti eeyan ba fi itọ kọ, iri ni n wo.

"Kọle sori apata, wuruwuru ni wọn ṣe.

Ọgbẹni Prof Yakubu, olori INEC yẹn lo sọ fun wa pe ẹrọ BVAS ni a ma fi dibo, o wa di ijọ ibo, wọn wa ni ẹrọ BVAS ko sisẹ mọ, ka ma binu."

"O yẹ INEC pa idibo ti di igba mii ni, ibo ti ko si ẹrọ BVAS nibẹ, odo ni, ofo ni"

Oloye George tẹsiwaju pe Olori ajọ INEC, Mahmod Yakubu ko fi iwa ọmọluabi ṣe eto idibo.

O ni o si han gbangba pe wọn lẹdi papọ mọ awọn ẹgbẹ oṣelu kan lati ṣe mọdarun eto idibo aarẹ to waye lọjọ Satide ni.

"O yẹ ki Olori INEC wuwa ọmọluabi ni, o si yẹ ko pa eto idibo ti pe awọn yoo tun ṣe nijọ miiran.

"Ibo ti a ba ma di, ti ko si ẹrọ BVAS nibẹ, odo ni, ofo ni,

"Wọn fẹ ba ilu yii jẹ, wọn ni awọn fi ọwọ ka ibo. asise ti a ṣe ni aye atijọ niyẹn ti a gbe awọn ti ko yẹ ko de bẹ wọlẹ.

"Tinubu kii n ṣe ọta mi sugbọn irọ ti pọju"

Nigba to salaye nipa ajọṣepo rẹ pẹlu Aarẹ tuntun, George o ni oun kii ṣe ọta Tinubu rara sugbọn irọ lo pọju ninu gbogbo ohun ti wọn gbe jade fun awọn araalu.

"Emi Bode George, n ko gba rara. Ẹ lọ wadi ẹni ti a gbe ipo fun.

"Ki n se atilẹyin fun ta ni, Tinubu ko ki n ṣe ọta mi, ẹ ma ri bẹẹ, ko gba iyawo mi.

Bẹẹ ni ko pa mi lọmọ, ani irọ ti pọju, onirọ lẹ gbe jade, ẹ tun wa fi irọ ṣe eto idibo.

"Ofin Naijiria ni ẹrọ BVAS ni ki wọn fi gbe esi ibo jade, ofege ni gbogbo eto idibo naa, ka sọ otitọ ọrọ tori ọjọ ọla,

" Ikede Tinubu bi ẹni pe ọfọ wọlu ni"

"Jijo iya ka wo o, ni wọn jo kiri"

Bode George wa sapejuwe ọrọ Aarẹ Muhammadu Buhari, to ni awọn araalu ilu lo fi ibo yan olori tuntun, gẹgẹ ọrọ ti ko bojumu rara.

O ni ọna ẹburu ni wọn gba kede ẹni to jawe olubori eto idibo naa.

" Abosi ni gbogbo ohun ti wọn ṣe pata. awọn ogbotangiri to wa lati ilẹ okere ti wọn ri a bi ṣe ṣe, ṣe bi wọn ṣe n ṣe ni ilu wọn niyẹn?

"Ibo ti wọn fi ọwọ ka yẹn, ki wọn ko lọ si abule wọn ni. Emi ko gba o.

"Ti a ko ba le sọ ootọ ọrọ, ẹmi lo kan, iwọ lo kan, afi emi emi, ẹ dẹ yiwe, o ṣe jẹ pe oru ni wọn kede ibo,

"Ki lo de ti a ko ṣe e loju mọmọ, ijo wo ni wọn n jo kiri."

"Tinubu o wọle, wọn yii iwe ni"

Bode George ni o da oun loju pe Tinubu kọ le wọle gẹgẹ bi aarẹ, ti ko ba ṣe pe wọn yii iwe esi idibo aarẹ to waye lọjọ Satide.

"So le wọle ni, wọn yiwe ni, ko le wọle ti ko ba ṣe pe wọn yi iwe.

"Tulasi ni wọn fi kede rẹ pe awọn eeyan dibo fun.

"Bi ẹni pe wọn gbe sẹyin rẹ ni, nnkan to wu wọn ni wọn ṣe, ko si ba oju mu.

"Ki gbe aye ṣe rere ni o".

N jẹ Oloye Bode George yoo ko kuro ni Naijiria gẹgẹ bii o ṣe sọ saaju?

BBC Yoruba tẹsiwaju pẹlu ifọrọwerọ rẹ pẹlu Baba Bode George, ta si bi i nipa ileri kan to se lasiko kan pe oun yoo kuro ni orilẹede Naijiria bi Bola Tinubu ba di Aarẹ.

Bode George ko fesi lori ọrọ sugbọn o ni awọn alabosi kan lo gbe iroyin naa jade.

"Awọn ọmọ alabosi kan, Tinubu ko kii ṣe ọta mi, a jọ wa lati ile kan naa ni."