Màá tako èsì ìbò tó kéde Tinubu bíi ààrẹ torí láti ayé ológun ni mo ti ń làkàkà láti di ààrẹ - Atiku

Oríṣun àwòrán, Atiku Abubakar
Oludije sipo aarẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar ti sọrọ fun igba akọkọ lẹyin ibo to waye pe o ku diẹ irinajo rẹ lati di aarẹ orilẹede Naijiria gba ẹmi.
Igbakeji aarẹ tẹlẹ sọ eleyi nigba to n sọrọ niluu Abuja lọjọ kẹta, oṣu kẹta ọdun 2023 pé erongba oun lati di mu iyapada ba orilẹede Naijria ti bẹrẹ lati aye ologun.
O ni o to aimoye ọdun toun ti wa lori pe oun fẹ di aarẹ orilẹede Naijiria.
"Pẹlu ibanujẹ ọkan ni mo fi n ba yin sọrọ loni, mo ti lo aimoye ọdun bayi lati fi ara mi jin si sinisn orilẹede Naijiria lati mu ayipada ba ijọba awarawa.
"Lati igba ologun ni mo ti bẹrẹ, irinajo to ku diẹ ko gba ẹmi mi ni ati ti ọmọkunrin mi, ti ọlọpaa mẹrin si padanu ẹmi wọn lasiko to duna lati dola ẹmi wa . Ori komiyọ lọjọ naa nitori ore ifẹ Ọlọrun ati aanu rẹ.
"Iyẹn nikan kọ, ọrọ aje mi fẹ danu kọlẹ. Ipinnu ati erongba mi lojẹ ki n parapọ pẹlu awọn eeyan jankankan miiran.
"Gẹgẹ bi olori lati ninu ẹgbẹ oṣelu SDP, pẹlu ẹmi ati alaga wa lọwọlọwọ bayi, a jagun ti a si bori eto idibo aarẹ lọdun 1993, eto idibo ti wọn sapejuwe gẹgẹ bi eyi to dara ju ninu itan orilẹede Naijiria , Ko si ayelujara nigba naa sugbọn ohun lo dara ju,"
Ètò ìdìbò 2023 kọ ní ìlérí tí ìjọba Buhari ṣé fún ọmọ Nàìjíríà - Atiku
Oludije ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar ti bu ẹnu atẹlu esi idibo aarẹ to waye lọsẹ to kọjọ, Ọjọ kẹdọgbọn, oṣu keji ọdun 2023.
O ni ibo to waye ja oun kunlẹ nitori ko ki n ṣe ohun to reti ati ko ki n ṣe bi eto idibo yẹ ko se waye niyẹn rara.
Oludije PDP na ika abuku si ajọ eleto lorilẹede Naijiria, INEC fun bi wọn se kuna lati tẹlẹ ilana ti wọn gbe kalẹ funm arawọn.
Atiku sapejuwe ibo ọdun 2023 gẹgẹ "Ibo to buru lati igba ti orilẹede Naijiria ti pada si ijọba awarawa".
Ipade pẹlu awọn akọroyin waye lẹyin ti ẹgbẹ oṣelu Labour Party naa kede pe awọn yoo morile ileẹjọ lati tako esi idibo ti ajọ INEC kede.
Atiku, ẹni to se ipo keji ninu eto idibo naa ni oun ti bẹrẹ ipade pẹlu awọn agbẹjọro rẹ lati mọ igbesẹ to yẹ lati gbe lori eto idibo to waye.
"Eto idibo ọdun 2023 fihan awọn eeyan pe a nilo atunse lori ọrọ oselu. INEC ja wa kulẹ gan.
Ohun iyalẹnu lo jẹ pe INEC suure kede esi ibo
Atiku ni ohun iyalẹnu lo jẹ fun ohun bi ajọ INEC ṣe sure lati kede esi ibo pẹlu bi ibo didi se ni ọpọlọpọ kudiẹkudiẹ.
"Lẹyin ọpọlọpọ imọran, mo ti pinnu lati tako ilana ati esi idibo ti ajọ INEC kede ."
Atiku wa fi ọrọ ransẹ si Aarẹ Buhari pe asiko si wa lati fi apẹẹrẹ rere silẹ .
"Ija yii ki n se nipa temi, nipa iwọ ati ọjọla awọn eeyan to n gbọ mi ni.
"Ati nipa ọjọla ijọba awarawa ati igbeaye to rọnu.
"Mo mọ bi isẹlẹ yii se ri lara awọn ọmọ Naijiria"
Iléẹjọ́ ní kí ẹ tí ṣé ìfẹ̀hónúhàn - Ààrẹ Buhari sí àwọn olùdíje yòókù

Oríṣun àwòrán, Facebook.com/MuhammaduBuhari
Aarẹ Mohammadu Buhari ti rọ awọn oludije sipo aarẹ ti wọn fi di rẹmi tabi ti wọn ni esi idibo ko tẹ lọrun gba ileẹjọ lati lọ ṣe ifẹhonuhan.
Buhari ni o ṣe pataki ki awọn oludije ati awọn ololufẹ wọn yago fun iwọde ati ifẹhonuhan lori titi nitori o lodi sofin.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ Aarẹ, Garba Shehu fi ransẹ si awọn akọroyin ni Aarẹ ti rọ awọn oludije lati jade ti wọn ba ni ẹri to peye lati ti fi tako esi idibo ajọ INEC to kede oludije sipo aarẹ ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu gẹgẹ bi aarẹ tilu sẹsẹ dibo yan
“Mo mọ pe awọn oloṣelu ati awọn oludije sipo aarẹ le ma tẹwọ gba esi idibo ti ajọ INEC kede.
“Sugbọn ko si bi esi idibo naa ṣe fẹ nira lati tẹwọ gba, ko gbọdọ jẹ ohun ti yoo fa rogbodiyan lawujọ wa.
“Ẹ lọ si ileẹjọ ti ẹ ba kẹfin pe magomago wa ninu esi idibo ti ajọ INEC kede fun araalu.
Aarẹ ni ko ba si ẹri to tako esi ibo naa, o ti han gbangba pe awọn araalu lo yan ẹni to wu wọn lọkan lati di olori orilẹede Naijiria.
“Mo rọ awọn oludije ati awọn ololufẹ fi apẹẹrẹ alaafia lede fun awọn araalu nitori pe wọn fi ibo wọn sọrọ lori ẹni ti wọn fẹ gẹgẹ aarẹ.”
Ẹnì tó kàjú ipò Ààrẹ ló borí ìbò - Buhari

Oríṣun àwòrán, Aarẹ Mohammadu Buhari
Aarẹ Muhammadu Buhari ti ransẹ ikinni ku orire si aarẹ tuntun ti ilu sẹsẹ dibo lorilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu lẹyin to bori eto idibo aarẹ to waye lọjọ Satide.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ aarẹ, Garba Shehu buwọlu fun awọn akọroyin niluu Abuja, Aarẹ Buhari ni awọn eeyan orilẹede Naijiria lo dibo yan ẹni to kajuẹ gẹgẹ bi aarẹ ti yoo lewaju orilẹede Naijiria.
Buhari tẹsiwaju pe eto idibo fihan pe awọn araalu yan ẹni to wu wọn lọkan ni lai wo boya ẹẹya tabi oun miiran. Aarẹ ni iyatọ ti deba orilẹede Naijiria lẹyin ti oun Aarẹ ati Aarẹ tuntun padanu ipinlẹ rẹ sọwọ ẹgbẹ oṣelu miiran.
“Mo ti ṣetan lati sisẹ pọ pẹlu aarẹ tuntun ati lati bẹrẹ bi yoo ṣe gbe igbara silẹ fun ninu oṣu karun un.
“Eto idibo yii fihan pe ijọba awarawa fun awọn araalu ni anfani lati dibo yan ẹni to ba wu wọn gẹgẹ bi olori.
“Mo padanu ipinlẹ mi sọwọ ẹgbẹ oṣelu miiran, Aarẹ tuntun na ko jawe olubori nipinlẹ to wa.
‘N ko ni eto idibo ko ni kudiẹkudiẹ ninu’
Aarẹ tẹsiwaju pe oun ko ni eto idibo to waye lọjọ Satide ko ni kudiẹkudiẹ ninu rara nitori ẹrọ to n gbe esi ibo lọ sori ayelujara ko si sisẹ. Fun idi eyi, Aarẹ ni awọn aye kan wa ti ajo eleto idibo yoo ni lati sisẹ si lati tan imọlẹ si pe ko si magomago ninu eto idibo.
“Mo mọ pe awọn oloṣelu kan ati awọn oludije ko ni tẹwọgba esi idibo yii. Ohun to dara ni.
“Ti ẹnikẹni ba ni ẹri pe magomago wa ninu esi idibo ti ajọ INEC kede, ko jade wa sita.
“Ti ko ba si ẹsi, ki wọn gba pe ohun awọn araalu lo sọrọ sita.
“Mo mọ o le nira lati gba ijakunlẹ sugbọn wọn ni anfani lati lọ si ileẹjọ liasi jadijagan.”















