Àkàndá ẹ̀dá ni Tinubu, àmì Ọlọ́run wà lára rẹ̀ ló ṣe jáwé olúborí ìbò Ààrẹ – Ooni

Oríṣun àwòrán, Facebook
Ooni Ile-Ife, Kabiyesi Enitan Ogunwusi Ojaja Kejì ti kan sáárá sí ìjáwé olúborí Bola Ahmed Tinubu gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Nàìjíríà.
Ooni Ogunwusi nígbà tó ń kópa lórí ètò ilé iṣẹ́ amóhùnmáwòrán TVC ṣo pe àkàndá ẹ̀dá ni Tinubu nítorí náà ló ṣe jáwé olúborí.
Ó ní àwọn àmì Ọlọ́run kan wà lára Tinubu tí wọ́n ṣiṣẹ́ fún-ún láti ri pé ó gbégba orókè níbi ìdìbò náà.
"Gbogbo àwọn tí kò dìbò fún Tinubu lápapọ̀ ju iye ìbò tó gbé Tinubu wọlé lọ."
"Èyí fi hàn pé àkàndá ẹ̀dá ni Tinubu, tó ní àwọn ẹ̀mí mímọ́ kan tó ń ṣiṣẹ́ ire fun láti dé ipò náà."
"Ọlọ́run dá Tinubu lárà ọ̀tọ̀ ni tó jẹ́ wí pé ó ní iṣẹ́ pàtàkì tí Ọlọ́run fẹ́ fi jẹ́ fún àwùjọ ni. "
Ooni ni òun ní ìgbàgbọ́ pé àwọn ìránṣé Ọlọ́run kan ń bá Tinubu gbé ló fi jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò tó jẹ́ wí pé àwọn tí kò fẹ pọ̀ ju àwọn tó fẹ nípò lọ.
Ṣáájú ni Ooni ti ránṣẹ́ ìkíni kú oríire sí Tinubu tó sì rọ àwọn olùdíje yòókù tó fìdí rẹmi láti gba kádàrá, kí wọ́n ṣe àrídájú rẹ̀ pé àláfíà jọba ní Nàìjíríà.
Kọmíṣánà ọlọ́páà Eko ṣèpàdé pẹ̀lú Falz, Macaroni

Oríṣun àwòrán, Others
Kọmiṣọnna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Idowu Owohunwa ti ṣepade pẹlu awọn alẹnulọrọ nipinlẹ Eko.
Lara awọn to ba ṣepade ni gbajugbaja olorin Folarin Falana ti ọpọ eniyan mọ si Falz ati adẹrinpoṣonu, Debo Adebayo ti ọpọ eniyan mọ si Mr Macaroni.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin ni ipade naa waye ni olu ileeṣẹ wọn nipinlẹ Eko.
Lara ohun ti wọn jiroro le lori ni ọrọ eto aabo to dẹnukọlẹ, paapaa ni asiko eto idibo to n lọ lọwọ ni Naijiria.
Awokọṣe ni ẹ jẹ, ẹ gba alaafia laaye – Kọmiṣọnna ọlọpaa sọ fun Falz, Macaroni
Owohunwa kesi awọn alẹnulọrọ naa lati gba alaafia laaye nipinlẹ Eko, ki wọn si fi jagidijagan silẹ.
Bakan naa ni wọn kesi wọn lati ba awọn ọmọlẹyin wọn sọrọ ati awọn ololufẹ wọn, ki wọn gba alaafia laaye fun igbayegbadun gbogbo eniyan ni ipinlẹ Eko.
‘’ A pe ipade naa lati ba awọn alẹnulọrọ sọrọ lati gba alaafia laaye nitori eto idibo to n lọ lọwọ ati idibo sipo aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ pari.’’
‘’A ba awọn eniyan sọrọ ṣaaju idibo sipo gomina ti yoo waye ni Ọjọ Kọkanla, Oṣu Kẹta, ọdun 2023’’
‘’A fẹ ki wọn jẹ awokọṣe nipa sisọ ọrọ alaafia, ki wọn si ma mu ipinlẹ tabi orilẹede Naijiria gbona jainjain.’’
Bakan naa ni kọmiṣọnna ọlọpaa fi ye wọn pe awokọṣe ni wọn jẹ ni awujọ nitori awọn eniyan n wa ẹni ti yoo fi ọna han wọn.
Ileeṣẹ ọlọpaa wa fi ye awọn eniyan pe awọn yoo da aabo bo awọn ara ilu ti awọn yoo si fi ẹnikẹni to ba da omi alaafia ipinlẹ naa ru jofin.















