Peter Obi gan ní ẹjọ́ láti jẹ́, á jọ pàdé nílé ẹjọ́ - APC

Aworan Peter Obi ati Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Facebook/Peter Obi/Bola Tinubu

Igbimọ to n risi ipolongo fun Aarẹ tuntun ti wọn sẹsẹ dibo yan ninu ẹgbẹ oṣelu APC ti fesi pada fun oludije ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi, pe awọn ti ṣetan lati pade rẹ ni ileẹjọ lori ipe to tako esi idibo aarẹ ti ajọ INEC kede.

APC ni o dawọn loju pe Bola Tinubu lo bori eto idibo naa ati pe Peter Obi naa ni ẹjọ lati rọ ni ileẹjọ.

Peter Obi, nigba to n bawọn akọroyin sọrọ niluu Abuja salaye pe o daoun loju pe oun bori eto idibo, to oun si setan lati fihan gbogbo ọmọ Naijiria bẹ.

Ti a ko ba gbagbe, bi ọjọ meji sẹyin ni ajọ INEC kede Bola Tinubu ti ẹgbẹ oṣelu APC gẹgẹ bi ẹni to jaweolubori ninu eto idibo aarẹ to waye lọsẹ to kọja.

"A ni ẹri lọwọ bi awọn janduku se kọlu awọn to fẹ dibo fun ẹgbẹ oṣelu wa"

Bayo Onanuga, alaga igbimọ to n risi ipolongo ibo fun Tinubu, ninu atẹjade to fi ransẹ si awọn akọroyin ni awọn tẹwọ gba igbesẹ Peter Obi lati lọ si ileẹjọ.

"To ba ni ẹjọ lati ṣe, o gbọdọ wa pẹlu ẹri pe magomago wa ninu eto idibo naaa

"Obi gbọdọ sọ bi ẹgbẹ oṣelu rẹ se ko gbogbo ibo ni awọn ipinlẹ kan"

Onanuga ni o ṣe koko fun Obi lati wa salaye bi ẹgbẹ se ko ida adọrun ninu gbogbo ibo to wa lati apa guusu oorun ti awọn ẹgbẹ oṣelu yoo ko ri nnkan .

"A ni ẹri lọwọ bi awọn janduku se kọlu awọn to fẹ dibo fun ẹgbẹ oṣelu wa.

"Ti Obi ba de ileẹjọ, o gbọdọ sọfun wa bi o ṣe mọ pe magomago wa nibi eto idibo, paapa ni apa ariwa nibi ẹgbẹ oṣelu rẹ ko ti aṣoju, tabi tọwọ bọwe lẹyin idibo.

"A jẹ ẹgbẹ oṣelu Labour Party ati PDP ni otitọ ọrọ. Wọn padanu ibo ko si nnkan ti iroyin ofege fẹ da fun wọn.

"Tinubu ti setan lati bẹrẹ isẹ lati sin awọn ọmọ orilẹede Naijiria pẹlu otitọ ọkan."

Mo borí ìdìbò Ààrẹ 2023, máa dẹ fí hàn ọmọ Nàìjíríà - Peter Obi

Aworan Peter Obi

Oríṣun àwòrán, Facebook.com/PeterObiGregory

Oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party fun ibo aarẹ ọdun 2023, Peter Obi ti sọrọ lori esi ibo ti ajọ INEC kede laipẹ yii.

Nilu Abuja ni Obi ti ṣe ipade pọ pẹlu akọroyin lẹyin ọjọ kẹfa ti idibo ti waye, to si o da oun loju pe oun bori eto idibo to waye lọsẹ to kọja.

Obi ni oun setan lati tan imọlẹ si gbogbo ohun to so kunkun ni ọna ofin lati fi han gbogbo aye pe oun ni oun bori eto idibo to kọja.

Alaga ajọ INEC ti kede Bola Tinubu ti ẹgbẹ oṣelu APC gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori eto idibo naa pẹlu apapọ ibo to ju milọnu mẹjọ lọ.

Obi ni eto idibo to waye jina si otọọ, to si jẹ pe irọ ni wọn gbe jade.

"Eto idibo yoo wa ninu itan Naijiria pe ohun lo ku diẹ tako ju".

Lati igba ti ajọ INEC ti kede oludije sipo aarẹ ẹgbẹ oṣelu APC gẹgẹ bi aarẹ ti ilu sẹsẹ dibo yan ni ọpọlọpọ eeyan ti bẹrẹ lati ma fi apa janu lori esi ibo naa.

Ẹgbẹ oṣelu Labour bori ipinlẹ mejila sugbọn apapọ ibo gbe wọn si ipo kẹta ninu irinajo lati di aarẹ orilẹede Naijiria.

Lati bori ipo aarẹ orilẹede Naijira, oludije gbọdọ ni ida mẹdọgbọn ibo lati gbogbo ipinlẹ lorilẹede Naijiria .

"N ko ti jawọ lori ọrọ Naijiria"

Oludije Labour Party ni oun si ni igbagbọ ninu orilẹede Naijiria tuntun, to si rọ awọn ọmọ Naijiria lati kopa ninu eto idibo gomina to n bọ lọna.

Obi ni oun ko lẹdi pupọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu kankan sugbọn oun lẹdi apupọ pẹlu gbogbo ọmọ orilẹede Naijiria to n binu lroi esi ibo ti INEC kede.

Bakan na ni Obi rawọ ẹbẹ si awọn ọmọ Naijiria pe ki wọn ma kuro lorilẹede Naijiria nitori oun wa pẹlu wọn lati mu ayipada de ba Naijiria.

Obi bẹrẹ ipade rẹ pẹlu awọn akọroyin pẹlu idakẹ jẹjẹ iṣeju kan fun awọn eeyan to padanu ẹmi wọn ati awọn to farapa lasiko ibo to waye lọjọ kẹdọgbọn, oṣu keji.