Ayo Adebanjo tutọ́ sókè-fojú gbàá lórí èsì ìbò ààrẹ

Aworan Bola Tinubu ati Ayo Adebanjo

Ọkan lara awọn agbaagba ninu ẹgbẹ Afenifere, Alagba Ayo Adebanjo, ti ni ikini fun igba ranpẹ ni bawọn eeyan kan se n ki Aarẹ tuntun ti ilu sẹsẹ dibo yan, Bola Tinubu.

Adebanjo ni o han gbangba pe ọna ẹburu ni wọn fi da eto idibo aarẹ to waye lọjọ Satide ru.

Adebanjo, nigba to n ba ileeṣẹ BBC Yoruba sọrọ, wa sapejuwe ijawe olubori Tinubu gẹgẹ bi ohun ti ko seese rara, ti ko si le fi ẹsẹ mulẹ.

O ni gbogbo awujọ agbaye lo lodi si esi idibo to gbe Tinubi wọle gẹgẹ bi aarẹ, to si tun han gbangba si awọn ọmọ orilẹede Naijiria pe magomago wa ninu esi idibo ti INEC kede.

"Ko le sise, ko si ibo rara, wọn gba ọna ẹburu lori ibo yẹn"

Adebanjo ni "Ko le sise, ko si ibo rara, wọn gba ọna ẹburu lori ibo yẹn ni.

"Awọn wo lo n ki Tinubu ku orire, iyẹn ko ki n ṣe ibo rara, ibo to gbe Tinubu wọle ko ni itẹwọgba, ko si ni sisẹ.

"O han si gbogbo wa pe ko ni itẹwọgba rara, awọn ajọ onwoye ibo lagbaye ni esi idibo yẹn ni mago mago ninu,

Awọn onwoye ibo labẹle naa sọ ti wọn pe wọn ṣe magomago ni.

"Esi ibo ti wọn ko ba lo ẹrọ BVAS fun ko ni itẹwọgba"

Alagba Ayo Adebanjo tẹsiwaju pe "ohun iyalẹnu lo jẹ fun ẹgbẹ oṣelu Labour Party ati awọn ẹgbẹ oṣelu yooku pe ajọ eleto idibo ko lo ẹrọ BVAS fun idibo, bi wọn ṣe ṣe ileri fun wa saaju ibo.

"Wọn kede pe a o fi ẹrọ BVAS dibo, o wa di asiko yii, wọn wa pati, iyẹn ko ni itẹwọgba rara.

"Ko si ọrọ nibẹ rara, eto idibo ko tii waye rara. Kii ṣe ẹgbẹ oṣelu Labour nikan lo fi ẹdun ọkan wọn han sita, gbogbo wa ni.

"Obansajo ni wọn gbọdọ tun eto idibo ṣe, Abdulsalam naa ni ki wọn lọ tun ṣe, gbogbo awọn ẹgbẹ oṣelu alatako ni awọn naa darapọ mọ wọn.

Idi ni pe esi ibo ti wọn kede ko papọ mọ nkan to wa lori ẹrọ BVAS rara.

"Awọn ẹgbẹ oṣelu yii fẹ dana sun orilẹede Naijria ni, igba diẹ loku.

Aarẹ Buhari wa ni oun ki 'Baby Boy' ku orire."

Àbò, ọrọ̀ ajé àti ïgbáyégbádùn ọ̀dọ̀ gbọdọ̀ gbé pẹ́ẹ́lí nínú ìjọba Tinubu - Afenifere

Pa Reuben Fasọranti gbe ọwọ le Tinubu lori fun adura

Ẹgbẹ Afẹnifẹre ti ki aarẹ ti ilu ṣẹṣẹ dibo yan, Bọla Ahmed Tinubu ku oriire bo se jawe olubori ninu ibo aarẹ to kọja.

Bakan naa ni wọn rọ ọ pe ko mu ọrọ abo, ọrọ aje ati mimu ọrọ ẹlẹyamẹya kuro pẹlu ipese isẹ ati igbayegbadun awọn ọdọ lọkunkundun ninu iṣejọba rẹ.

Ẹgbẹ Afẹnifẹre labẹ idari Alagba Reuben Faṣọranti lo sọ eyi lati tọka si pe Sẹneto Tinubu lo kun oju iwọn ju lati koju iṣẹ ati ipenija to wa nilẹ fun orilẹede Naijiria ati awọn eeyan rẹ bayii.

Akọwe agba fun ẹgbẹ Afẹnifẹre nigbakan ri, Oloye Sẹhinde Arogbọfa sọ ninu ifọrọwọrọ pẹlu BBC News Yoruba pe igbagbọ ẹgbẹ naa ni pe Tinubu yoo ṣisẹ ju awọn yoku lọ.

Tinubu, fa awọn agbaagba Yoruba to sisẹ tako ọ mọra - Afenifere

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Arogba ni “Lori ọrọ abo, ọrọ aje ati mimu ọrọ ẹlẹyamẹya kuro, ọpọlọpọ awọn ọdọ ti ko ri iṣẹ, yoo le pese iṣẹ fún wọn.

Bakan naa, Tinubu yoo si le ṣe itọju awọn ọdọ yii gẹgẹ bi o ṣe ṣe nigba to jẹ gomina ipinlẹ Eko”

Oloye Arogbọfa ṣalaye pe igbagbọ oun ni pe Tinubu gẹgẹ bi aarẹ yoo le fi ọwọ fa gbogbo awọn to ṣiṣẹ tako o mọra.

O ni paapaa julọ awọn agbaagba ilẹ Yoruba ti wọn tako idije rẹ.

O ni nitoripe iwa ọlaju tete de ilẹ Yoruba ju ọpọlọpọ ẹya miran lorilẹede Naijiria lọ, lo mu ki oniruru eeyan maa dide lati fi iha ti wọn ba kọ si ohunkohun han.

Adari Afẹnifẹre, Oloye Adebanjọ wa lara awọn to lewaju ipolongo ibo fun oludije fun ẹgbẹ oselu Labour, Peter Obi eleyi to pin ẹgbẹ baa si meji lẹyin ti Oloye Faṣọranti sọ pe Tinubu ni ẹgbẹ Afẹnifẹre n ba lọ

Oloye Arogbọfa nigba to n sọrọ lori eyi ni kii ṣe tuntun, aye Awolowo gan lo ti kọkọ bẹrẹ ati pe gbogbo wọn ọkan naa ṣi ni gbogbo wọn, awọn agbaagba naa yoi si tun pada joko sọrọ fun ilọsiwaju ilẹ Yoruba

Kò si ohun tó ń jẹ́ “ electronic transmission” nínú ìwé òfin ìdìbò Nàìjíríà - Ahmad Lawan

Aarẹ ile asofin agba ni Naijiria, Sẹnetọ Ahmad Lawan

Oríṣun àwòrán, other

Aarẹ ile aṣofin agba orilẹede Naijiria, Sẹnetọ Ahmad Lawan ti sọ pe ko si ohunkohun to jọ fifi esi ibo ranṣẹ nipa imọ ẹrọ ayelujara ninu iwe ofin eto idibo Naijiria tọdun 2022.

Sẹnetọ Ahmad Lawan sọ eyi di mimọ nigba ti aṣoju ẹkun idibo Kwara Central, Ibrahim Oloriẹgbẹ gbe ọrọ ka iwaju ile lori awuyewuye to n waye lori eto idibo sipo aarẹ to waye lọjọ karundinlọgbọ osu keji.

O ni ohun to wa ninu ofin ti wọn fọwọsi ni fifi ẹrọ idibo BVAS ya fọto uwe esi idibo ki wọn si fi ranṣẹ si agbada ayelujara server ti ajọ naa gbe kalẹ fun idibo yii.

Bi o tilẹ jẹ pe ọna ati pẹtu si awuyewuye naa ki kaluku si tẹle ilana ofin ati alaafia lo ṣokunfa ijiroro naa, ṣugbọn ọpọ ariyanjiyan lo da silẹ laarin awon aṣofin ẹgbẹ oṣelu APC ati awọn aṣofin ẹgbẹ alatako gbogbo ni ile asofin agba naa.

Bi awọn aṣofin agba lẹgbẹ oṣelu APC ṣe to si ẹyin ijiroro naa lawọn ti ẹgbẹ alatako n faake kọri.

Aworan apanilerin cartoon Bola Tinubu

Aarẹ ile aṣofin agba sọ pe: ‘Ninu ofin idibo ti a buwọlu ko si ohun to n jẹ fifi ẹrọ ayelujara fi ibo ranṣẹ,ohun to wa nibẹ nififi awọn iwe to rọ mọ esi ibo ranṣẹ ti awọn aṣoju ẹgbẹ gbogbo yoo si ni ẹda iwe wọnyi lọwọ

‘INEC yoo wa ya iwe esi ibo yii lati fi ranṣẹ. A rọ ajọ INEC lati tẹle ofin yii at’awọn ofin miran lori ilana rẹ.”

Amoṣa o ni kii ṣe ojuṣe awon aṣofin lati maa tu ofin, ojuse ile ẹjọ ni.

Sẹnetọ Oloriẹgbẹ ni o yẹ ki ile asofin naa ke sawọn adari ẹgbẹ oṣelu, awọn oloselu ati gbogbo ọmọ Naijiria lati sinmẹdọ ki wọn si jẹ ki ajọ INEC yanju ojuṣe rẹ lori ibo naa gẹgẹ bi ofin idibo ṣe la a kalẹ.

Aworan nipa iye ibo ti ọkọkan awọn oludije gb

Amọsa awọn asofin ẹgbẹ oṣelu PDP bii Sẹnetọ Betty Apiafi lati Rivers, Emmanuel Oker-Jev lati Benue, Adamu Bulkachuwa lati Bauchi pẹlu Biodun Olujimi lati Ekiti tako ijiroro naa.

Awọn aṣofin ẹgbẹ alatako baa rọ ile naa lati maṣe da si ohun to n ṣẹlẹ ni ibudo akojọpọ ibo ki o ma baa tun ta epo si ina awuyewuye to n jo lọwọ lori rẹ.

Amoṣa awọn asofin ẹgbẹ oṣelu APC bii Sẹnetọ Sani Musa lati Niger sọ pe ayẹwo orukọ nikan ni ẹrọ idibo BVAS wa fun labẹ ofin idibo atipe kii ṣe eto idibo lori ẹrọ igbalode ni Naijiria n lo ti wọn yoo fi maa reti ki awọn ẹrọ naa maa ko aworan beba esi idibo ti wọn ya ranṣẹ si ajo INEC ni yajoyajo bi eto idibo ṣe n lọ.

Kò si ohun tó ń jẹ́ “ electronic transmission” nínú ìwé òfin ìdìbò Nàìjíríà -Ahmad Lawan, ààrẹ ilè aṣòfin àgbà