Ritual: Ọlọ́pàá ká orí mẹ́wàá àti ìfun èèyàn mọ́ ọọ́físì Alfa, ọwọ́ tẹ èèyàn mẹ́wàá

"Àgbà Alfa ni ọkọ n‘Ibadan, kàyéfì ni bí wọn ṣe ká orí mẹ́wàá àti ìfun èèyàn mọ́ ọọ́físì rẹ̀"

Awọn ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, @policeNg

Ọwọ Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti tẹ afurasi mọkanla pẹlu ori gbigbẹ mẹsan, ori tuntun kan, ifun ati awọn ẹya ara eeyan mii niluu Ibadan.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo, Adewale Osifeso lo kede ọrọ naa nigba to n ba awọn akọrotin sọrọ ni olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo.

O ni ọwọ tẹ awọn afurasi naa nibi ti wọn sa pamọ ni agbegbe Orita Aperin.

Osifeso ni awọn afurasi naa lo n ṣe okoowo ori ati ẹya ara eeyan fun awọn ohun etutu.

Agbẹnusọ ọlọpaa fikun pe "Awọn eeyan mọkanla naa lo ti jẹwọ pe awọn kopa ninu okoowo naa nigbati a fi ọrọjumitoro ọrọ pẹlu wọn.

"Wọn jẹwọ pe awọn lọ maa n hu awọn ori gbigbẹ naa ni itẹ oku kaakiri.

"Bakan naa ni wọn jẹwọ pe ori tutu ati awọn ẹya ara eeyan ti a ka mọ wọn lọwọ lo jẹ ti ọkan lara wọn, to n jẹ Amuludun.

Awọn afurasi naa ni amuludun lo pa ẹni to ni ori naa, to si bẹ ori ọhun bo se pa ẹni naa tan, amọ ti afurasi naa ti salọ."

"Alfa ni mo mọ ọkọ mi si, o ya mi lẹnu pe wọn ri ori eeyan ninu ọọfisi rẹ̀"

Ọkan lara awọn afurasi ti ọwọ lo jẹ iyawo Alfa, ẹni to jẹ olori awọn ọdaran naa, ti oun naa ti salọ, ni oun ko mọ pe ọkọ oun ni ori eeyan ninu ọfisi rẹ nitori alfa musulumi ni oun mọ ọkọ si, to si jẹ ohun iyalẹnu.

O salaye pe oun lọ si ọfisi ọkọ oun lati gba ọwọ ounjẹ ni awọn ọlọpa wọle de lati wa tu ọfisi, ti wọm si ri ori eeyan.

Kí ló lé pa tọkọtaya lóru mọ́jú, ọkọ ń pọ ẹ̀jẹ̀ nímú, ìyàwó ń pọ ọṣẹ?

Ohun iyalẹnu lo jẹ fun awọn mọlẹbi, ara adugbo ati awọn ọrẹ, ọkunrin agbẹ kan, ẹni ọdun mẹtadinlogun, Kehinde Egbeyi ti wọn sawari oku rẹ pẹlu ti Iyawo rẹ, Bukola ninu yara wọn ni agbegbe Oke Erinja, ni opopona Ilaro si Owode nijọba ibilẹ guusu Yewa nipinlẹ Ogun.

Iwadi ileeṣẹ BBC fihan pe awọn tọkọtaya naa ni wọn gbe pọ pẹlu ọkan lara mọlẹbi wọn kan ti orukọ rẹ n jẹ Joel, ẹni ti wọn jọ wo tẹlifisan lasalẹ ki wọn to wọle sun.

Lowurọ arọ ọjọ keji ni Joel kesi Kehinde pe ko jade, ki wọn morile oko to jẹ isẹ ojo wọn ni sise, sugbọn Kehinde ko da lohun.

Joel pariwo orukọ Kehinde ati iyawo rẹ , Bukola lati jade kuro ninu yara wọn sugbọn ko si ẹni kankan laarin tọkọtaya to dahun si ipe naa.

Osojumikoro to ba ileeṣẹ iroyin abẹle sọrọ ni Joel ati awọn aradugbo ja ilẹkun yara Kehinde wọle, ti wọn si sawari oku rẹ ati Iyawo ninu yara.

O tẹsiwaju pe ko si ami pe tọkọtaya naa ni arẹ lara lọjọ Aje, ki wọn to lọ sun. Osojumikoro ni kete ni awọn ransẹ si ileeṣẹ ọlọpaa.

“Joel, Kehinde ati iyawo rẹ ati awọn aradugbo miiran ni wọn jọ joko wọ ere sinima ninu palọ wọn. Lẹyin ti wọn pari ni onikaluku ko sinu yara wọn ati Kehinde pẹlu iyawo rẹ.

“Sugbọn arọ, nigba ti awọn yooku dide lati lọ soko, wọn ri pe Kehinde ati iyawo rẹ ko jade ninu yara wọn,

“A ri ẹjẹ ni imu Kehinde, ti iyawo si pọ ọsẹ lẹnu”

Osojumikoro ni kete ti wọn ja ilẹkun wọle ni wọn ri oku tokotaya naa, ti ẹjẹ si wa ni imu Kehinde, Iyawo si n pọsẹ lẹnu.

O tẹsiwaju pe ko ṣeṣe ko jẹ pe efin ẹrọ amunawa lo ṣekupa tọkọtaya naa nitori ko si ohun to jọ bẹ ninu ile wọn tabi ita ile wọn.

Aburo Kehinde, Joel fidi isẹlẹ naa mulẹ, to si ni wọn sin tọkọtaya naa.

Joel ni awọn mọlẹbi ṣe akiyesi pe iku tọkataya naa ki n ṣe oju lasan sugbọn wọn ti fija fun Ọlọrun ja.

“Emi ni mo lọ sọdọ awọn ọlọpaa ni Owode to isẹlẹ naa to wọn leti lori iku ẹgbọn mi ati iyawo mi. Awọn ọlọpaa kan wa wo isẹlẹ naa fun arawọn

“Awa mọlẹbi ti gba lati fija fun Ọlọrun ja. Inu ironu ni Iya mi wa, ti ko si le sọrọ bayi”

Joel ni awọn mọlẹbi ọkọ ti sin Kehinde ti awọn ti Iyawo si ti wa gbe oku iyawo naa lati lọ sin.

Ki ni ileeṣẹ Ọlọpaa sọ?

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi fidi isẹlẹ naa mulẹ.

“Nkan to sẹlẹ nipe wọn ri oku tọkọtaya naa ninu yara wọn. Ibeji ni ọkọ, to n gbe pẹlu ikeji rẹ ninu ile kan na.

“Lẹyin tiisẹlẹ naa sẹlẹ, wọn fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti, ti a si wa lati wa gbe oku naa fun ayẹwo ati iwadi sugbọn awọn mọlẹbi ni awọn ko kẹfin kọlọfin kankan ati pe awọn ṣe ẹjọ.

“A sọ fun wọn pe ki wọn tọwọ bọwe lori ohun ti wọn duro le lori.”