Wo Kókó mẹ́fà tó wà nínú idajọ ti Supreme Court gbe kalẹ̀ lórí àtúnse Naira

Naira atijọ ati tuntun

Oríṣun àwòrán, CBN

Iroyin to n tẹ wa lọwọ lati ile ẹjọ to giga julọ nilẹ wa ti kede pe wọn ti gbe idajọ kalẹ lori awuyewuye to n waye nipa atunse Naira ilẹ wa.

Ninu idajọ ti igbimọ onidajọ ẹlẹni meje naa, ti adajọ Emmanuel Agim ko sodi gbe kalẹ, wọn kede pe ki awọn ọmọ Naijiria maa na Naira atijọ ati tuntun lọ.

Amọ wọn fi gbedeke le pe, nina Naira atijọ naa yoo dopin ni ọjọ Kọ́kanlelọgbọn osu Kejila ọdun yii, eyiun ọjọ to kẹyin ọdun yii.

Idajọ naa si lo n lodi si asẹ ijọba apapọ pe Naira tuntun nikan ni ka maa na nilẹ yii.

Kókó ìdájọ́ mẹ́fa tí ile ẹjọ to ga julọ gbe kalẹ̀ lọ́jọ́ Ẹtì

Bẹẹ ba gbagbe, ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria lo ti kọkọ pasẹ pe ka maa na owo Naira atijọ lọ papọ mọ tuntun titi ti oun yoo fi gbe idajọ oun kalẹ lori ẹjọ ti El-Rufai at awọn gomina APC mii pe tako atunse Naira tuntun.

Koko keji ni pe ilana lilo oju opo itakun agbaye lati maa san owo ko muna doko to, to si n se segesege pẹlu ofin banki apapọ ilẹ wa.

Koko kẹta to wa ninu idajọ naa ni pe aarẹ il wa nikan ko le da se ipinnu lori atunse Naira lai jẹ kawọn igun olupẹjọ mọ nipa rẹ, eyiun awọn gomina ipinlẹ kọọkan.

Koko kẹrin ni pe lasiko to n gbe ilana atunse Naira tuntun yii kalẹ, ofin ilẹ wa pọn ni dandan pe ki aarẹ bun awn igbimọ majẹobajẹ lorilẹede yii gbọ nipa igbesẹ naa.

Koko idajọ kẹrin ni pe ilana atunse Naira tuntun naa se idiwọ nla fun isọwọ sisẹ awọn ijọba ipinlẹ yika orilẹede yii.

Koko idajọ karun ni pe igbesẹ ijọba apapọ naa lodi sofin ilẹ wa.

Koko idajọ kẹfa ni pe kawọn ọmọ Naijiria maa na owo Naira atijọ lọ pẹlu tuntun, to si gbọdọ jẹ itẹwọgba.

Koko idajọ keje ni pe igbesẹ nina owo beba Naira atijọ yoo wa sopin ni ọjọ to pari ọdun 2023, eyiun ọjọ kọkanlelọgbọn osu Kejila ọdun 2023.

Owo tuntun

Oríṣun àwòrán, CBN

Awọn gomina mẹwaa lorilẹede Naijiria lo pe ijọba apapọ lẹjọ lati tako ilana siṣe eto pasipaarọ owo naira tuntun.

Ọsẹ to kọja ni ileẹjọ sun ẹjọ si ọjọ kẹta oṣu kẹta ọdun 2023.

Ọjọ kọkanlelọ̀ọgbọn oṣu kini ọdun 2023 ni banki apapọ CBN kọkọ fi ṣe gbedeke paṣipaarọ owo beba olodindi igba naira (N200), ẹẹdẹgbẹta naira (N500) ati ẹgbẹrun kan naira (N1000) ki wọn to sun un siwaju si ọjọ kẹwaa oṣu keji ọdun 2023 lẹyin ti ọpọ ọmọ Naijiria bẹrẹ si ni ke irora lori ilana eto naa.