Aṣòfin tó borí ìbò dèrò ọgbà ẹ̀wọ̀n torí ẹ̀sùn ìpànìyàn lásìkò ìdìbò

Awọn osisẹ ọgba ẹwọn n gbe asofin Doguwa lọ si ahamọ

Ile ẹjọ ti fi asoju-sofin kan to n soju ẹkun idibo Doguwa ati Tudun Wada nipinlẹ Kano nile asofin apapọ ilẹ wa, Alhassan Ado Doguwa, si ahamọ ọgba ẹwọn.

Alhassan Ado Doguwa lo foju han nile ẹjọ lati wa sọ tẹnu rẹ lori ẹsun ti wọn fi kan pe o lọwọ ninu iku eeyan mẹta.

Lọjọru nileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Kano kede pe oun ti gbe asojusofin naa si ahamọ lori ẹsun pe o lọwọ ninu wahala to bẹ silẹ lasiko akojọpọ ibo to waye lọjọ Satide ni ẹkunidibo rẹ.

Fidio kan to ti gba ori ayelujara kan lo safihan ọpọ eeyan to fi ara gba ọgbẹ ọta ibọn lasiko akojọpọ ibo naa, ti eeyan mẹta si jade laye lara wọn.

Ọlọpaa fi tipa mu Doguwa ni papakọ ofurufu tori o kọ lati jẹ ipe wọn

Idi si ree ti Kọmisana ọlọpaa nipinlẹ Kano, Muhammad Yakubu se pasẹ fun ẹka ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lati tanna wadi isẹlẹ naa.

Saaju nileesẹ ọlọpaa ti fi atẹjade kan sita pe oun ti ransẹ pe asofin Doguwa saaju, ẹni ti wọn n naka si pe o lọwọ ninu iwa isekupani naa.

Wọn ni lati ọjọ Aje ni wọn ti fiwe ipe ransẹ si lati yọju sileesẹ ọlọpaa amọ to faake kọri lati tẹwọ gba iwe naa.

Idi si ree ti ileesẹ ọlọpaa se lọ fi tipa gbe wa si ahamọ wọn lati papakọ ofurufu Aminu Kano, to ti fẹ gbera lati rinrinajo, ti wọn si fi oju rẹ bale ẹjọ ni Ọjọru.

Asofin Alhassan Doguwa

Oríṣun àwòrán, INEC/TWITTER

Ọlọpaa n wa awọn afurasi yoku to ti salọ lori ẹsun ipaniyan naa

Ileesẹ ọlọpaa wa leri leka pe iwadii oun yoo muna doko lori isẹlẹ naa, ẹnikẹni ti aje iwa ibajẹ naa ba si si mọ lori ni yoo foju bale ẹjọ.

Bakan naa lo ni oun ti n finmu finlẹ nipa awọn afurasi yoku to lọwọ ninu iwa ika naa, paapaa awọn to ti sa kuro nipinlẹ naa.

Asofin Doguwa, to n soju ẹgbẹ oselu NNPP lo wọle ibo sile asoju asofin ninu ibo to waye lẹkun idibo rẹ lọjọ Satide to kọja.

Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Kano wa fọwọ gbaya fawọn araalu pe eto idibo to ku yoo lọ ni alaafia, ẹnikẹni to ba si fẹ da omi alaafia ilu ru, ni yoo fi imu ko ata ofin.

Baba at'ọmọ to n jale ko sọwọ ẹṣọ aabo l'Ogun

AWORAN

Oríṣun àwòrán, ABIMBOLA OYEYEMI

Ọwọ ẹṣọ alabo ipinlẹ Ogun ti a mọ si So-Safe Corps ti tẹ baba agbalagaba ẹni ọdun marundinlọgọrin kan, Abioro Weniwon, ati ọmọ rẹ, Zacchaeus Abioro toun jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn.

Gẹgẹ bi agbẹnusọ fun ileeṣẹ ẹṣọ aabo ọhun, Mọruf Yusuf ṣe ṣalaye fun BBC YORUBA laipẹ yii, o ni ọjọ Ẹti, Furaidee to kọja lọwọ awọn tẹ awọn mejeeji.

Yusuf sọ pe inu oko oloogbe kan, Alaaji Mọruf Kaka to wa niluu Ihunbọ, ijọba ibilẹ Ipokia l'awọn mejeeji ti jale wọn, ko to di pe ọwọ palaba wọn segi.

Nigba to n ka awọn ohun ti wọn ji sita, Yusuf ni iwe ile meji ọtọọtọ, ferese ile ati ohun elo mọto (C-Causion) kan.

Yusuf tun fi kun ọrọ rẹ pe awọn kan lo ta ileeṣẹ wọn lolobo, ko to di pe wọn bẹrẹ iṣẹ iwadii, to si ni ko pẹ rara ti ọwọ fi tẹ awọn mejeeji.

O l'awọn mejeeji jẹwọ pe lotitọ l'awọn jale ẹsun ti wọn fi kan wọn, ati pe awọn ti lu gbogbo ẹru ti wọn ji ko ni gbanjo fun ẹnikan ti wọn pe ni Bapa Madaki, ẹni ọdun mejilelọgbọn.

Nigba to n pari ọrọ rẹ, o sọ pe ọga awọn Sọji Ganzalo ti paṣẹ pe ki wọn lọ fa awọn mejeeji le awọn ọlọpaa ẹkun Idiroko lọwọ lati tẹsiwaju iwadii lori wọn.