Nigeria election 2023: Wo àlàkalẹ̀ àwọn ìpèníjà tí Ààrẹ tó bá borí ní Nàìjíríà yóò dojú kọ

Awọn oludije ipo Aarẹ NAijira
Ila

Idibo apapọ Naijiria fun ọdun 2023 ku iwọnba ọjọ perete.

Gbogbo ipenija to nkoju orilẹede Naijiria lọwọ ati ṣaaju akoko yii tubọ mu ki pataki idibo naa ati abajade rẹ o ṣe pataki fun ọpọ ọmọ Naijiria atawọn onwoye lagbaye.

Gẹgẹ bi Naijiria ṣe jẹ orilẹede to ni ọrọ aje to pọ ju ati iye eniyan to pọju nilẹ Afirika - pẹlu eniyan miliọnu igba-o-le-mẹrinla eeyan, ohun to ba ṣẹlẹ ni Naijria ni ipa to pọ jantirẹrẹ.

Awọn oludibo ti wa ṣetan lati yan aarẹ tuntun lẹyin ọdun mẹjọ labẹ iṣejọba Muhammadu Buhari amọṣa o, ẹnikẹni to ba jawe olubori yoo foju wina awọn ipenija to le gidi.

Ninu aworan atọka yii ni diẹwa lara gbogbo nnkan to wa lọkan awọn to fẹ dibo.

Ọwọngogo ounjẹ
Ila

Ọwọngogo Ounjẹ

Ni ọdun to kọja bii ti awọn mii lagbaye, awọn ọmọ Naijiria ti fori ko ọwọngogo owo ounjẹ eyi ti bẹrẹ latari ipa ti ogun Ukraine da silẹ.

Ṣugbọn ṣaaju akoko yii naa ni owo ounjẹ ti n lọ soke tẹlẹ eyi to jẹ latari titi ti wọn ti awọn ẹnu ibode Naijiria ki wọn ma baa ri ọja ilẹ okere ko wọle ati ọwọngogo pasiparọ owo ilẹ okere naa.

Ounje

Oríṣun àwòrán, @Others

Àkọlé àwòrán, Ounje : Iresi

Bi a ba wo gbogbo ẹ pọ, ọwọngogo ni ọdun 2022 duro si ipo to kere diẹ ju ida mọkandinlogun to si jẹ eyi lo ga ju ri laarin ogun ọdun.

Garri to jẹ ounjẹ to kariile kari oko ti wọn n ṣe latara ẹgẹ wa lara ounjẹ ti ọwọngogo yii fọwọ kan diẹ amọ eyi to gọbọi ju ni bi owo awọn nnkan elo bii tomato ati ororo ṣe dede fo soke gija to si n pa awọn idile lara gidi gan.

Gbese Naijiria

Epo Rọbi

Bi aarẹ tuntun to ba jawe olubori ba fẹ ṣeranwọ fun awọn eeyan lori iye owo awọn nnkan to ṣe koko, wọn yoo koju iṣoro eyi to jẹ wipe ijọba ti n bábá n na owo bayii ju ohun ti wọn pa wọ́le lọ.

Iye Epo Robi ti Naijiria pese

Owo nla ni wọn n na sori pipese owo iranwọ epo bẹntiro bẹẹ si ni orilẹede Naijiria yii t'Eleduwa fun ni ẹbun pipese epo ko tii raye lo anfani ọwọngogo epo naa tori wọn ko ni ileeṣẹ to fọ epo wọn si ni lati maa pada gbe epo wọn wọ̀ orilẹede lati ibi ti wọn ti ba wọn fọ ọ.

Eyi ti n kọ awọn onimọ lominu nipa bi wọn ṣe lee ri gbese ilu ka kuro nilẹ tan pẹlu iye owo ele to n gori rẹ.

Ila

Gẹgẹ bi ọkan lara awọn orilẹede ilẹ Afirika to n pese epo rọbi ju, Naijiria ti dara le goolu ju fun ipawo wọle ijọba to fi mọ ọna ati ni owo ilẹ okere.

Amọṣa, orilẹde olowo epo rọbi yii ko tii ṣamulo anfani awọn owo ti wọn ri pa, ọpọ lara rẹ lo si ti di jiji tabi eyi ti wọn lo ni ilokulo.

Nibayii, ipese epo rọbi ti n fori la ilẹ lati bii ọdun mẹwaa sẹyin. Lọdun 2022, o ja walẹ si ipo to kere julọ laarin ọgbọn ọdun.

Jiji epo rọbi ati biba ọpa epo jẹ ni wọn da ẹbi adanu yii le lori. Bi a ba wa fi eleyi kun iye dun ti ko fi bẹẹ si idokoowo to fi mọ ọjọori awọn ibudo ipọnpo yii gan, o tumọ si wipe Naijiria ti n fa sẹyin awọn orilẹeede Afirika mii to n pese epo rọbi.

Iye ọdọ Naijiria
1px transparent line

Iye Ọdọ

Pẹlu bo ṣe jẹ pe nnkan bii idaji awọn to wa lorilẹede Naijira ni ọjọ ori wọn koi tii to mejidinlogun, awọn adari orilẹede n koju ipenija lori ọna lati ṣe amulo aduru iye awọn ọdọ yii.

Wọn ni lati ran idagbasoke ọrọ aje lọwọ lati lee ṣamojuto ohun ti gbogbo awọn ọdọ yii nilo ti wọn si ni lero lati di.

Bo tilẹ jẹ pe ọpọlọpọ wọn ṣi kere lati lọ dibo, ida ogoji iye oludibo ni ọjọ ori wọn ko to marunlelogoji eyi to mu ki wọn jẹ igun ti o pọ ju.

Bi wọn ba ri wọn ba sọrọ taara, o ṣeeṣe ko ni ipa lori eto idibo naa.

Awọn ọmọ NAijiria ti ko niṣẹ
1px transparent line

Airiṣẹ

Ohun akọkọ ti ọpọ ọdọ Naijiria n fẹ ni iṣẹ

Lọwọlọwọ, ida mẹta awọn eeyan Naijria to fẹ ṣiṣẹ ni ko ri iṣẹ. To ba jẹ ti awọn ọdọ, o ju idaji awọn to wa laarin ọmọ ọdun mẹẹdogun si mẹrinlelogun lọ to n wa iṣẹ.

Bo tilẹ jẹ pe itujade arun Coronavirus naa da kun ipenija yii amọ iṣoro ainiṣẹ ti wa nilẹ ṣaaju Coronavirus.

Ọrọ aje Naijiria ti dagba lati ọdun 2015, ṣugbn ko kan ṣaa yara to ni lati pese anfani fun awọn mii to n wa iṣẹ.

Lafikun, iṣoro abo wa lara nnkan ti wọn ti woye gẹgẹ bi idi fun aisi idagbasoke, ṣugbọn awọn onimọ nipa ọrọ aje naa tun da ẹbi rẹ ru aiko owo naira jade to ti wn si n ti awọn ibode lati bu ẹnu atẹ lu idokoowo.

Ori ayelujara
Ila

Ohun Amayedẹrun

Iye ohun amayedẹrun to yẹ ko mu imugbooro ba ọna ati ṣe owo ati igbe aye ojoojumọ ti walẹ gidi gan.

Ipo akurẹtẹ ti ipese ina wa ti pẹ gan ti ko niye ọdun eleyi to ti di ọrọ yẹyẹ bẹẹ si ni ida marunlelaadọta iye eeyan Naijiria lo n jẹ anfani ina, gẹgẹ bi Banki agbaye ṣe kọ ọ silẹ.

Ina mọnamọna

Bo ba si wa di ti ka lo itakun ayelujara, ida mẹrindinlogoji nikan lo n wa lori ayelujara eyi to fi Naijria si ọwọ aarin awọn orilẹede to wa ni iha Iwọ Oorun Afirika.

1px transparent line

Abo

Bi a ba boju wo bi iwa ipa ṣe n peleke sii ni Naijiria, yoo jẹ ohun to ṣe koko fun aarẹ to ba jẹ lati koju.

Nigba ti wọn kọkọ dibo yan aarẹ Buhari lọdun 2015, idunkokomọni latọdọ ikọ ẹlẹsin Islam, Boko Haram di wahala to tobi nilu. Nisinsiyi ti wọn ko tilẹ wa dari awọn agbegbe pupọ mọ, iwa ijinigbe, ikọlu to lọw oṣelu ninu, ikọlu laarin awn agbẹ ati daran-daran, iwa ipa ati idigunjale to fi m iwa aburu latọwọ awọn ọlọpaa ti da idamu sọkan awọn eeyan nitori ọr abo.

eyi kii sii ṣe ipenija to doju kọ iha Ila Oorun Ariwa nikan mọ, o ti wa tan kaakiri gbogbo ilu orilẹede naa.

1px transparent line

Eto Ẹkọ

Ọkan ninu ọmọ marun lagbaye ni ko si nile ẹkọ gẹgẹ bi ajọ isọkan agbaye, according to the UN's children's fund, Unicef. ṣe sọ ọ.

Nigbati eyi jẹ alabajọpin ninu iye eeyan to wa lorilẹede Naijiria, koko ni pe ida ogoji ninu awn ti ọjọ ori wn wa laarin ọdun marun si mọkanla ni orilẹede naa ni ko si nile ẹkọ to si n k ni lominu.

Eyi jẹ ipenija to kariile kari oko lorilẹede Naijiria koda, lilọ ile ẹkọ tilẹ dikun jọjọ ni iha Ariwa. Lara okunfa eyi ni iṣoro abo, amọ ọrọ ẹda akọ tabi abo to fi mọ iṣẹ́ naa jẹ okunfa gboogi.

Ila
Nigeria election graphic