Awọn eto ẹgbẹ kọọkan
All Progressives Congress
Awọn ohun to ṣe pataki
- Lari ṣe afikun bi Naijiria ṣe n fi ọja ranṣẹ silẹ okeere, ati adinku si bi bo ṣe n ko ọja wọle
- Ṣe adinku iye ọdọ ti ko riṣẹ pẹlu idaji laarin ọdun mẹrin
- Gbe igbesẹ lati ri daju pe ẹka eto idajọ ni ominira
Eto ọrọ aje
- Ṣe atilẹyin fun awọn ileeṣẹ nla-nla
- Ri daju pe ko si ọwọngogo mọ laarin ilu
- Ṣe afikun ipese epo rọbi pẹlu ida ogun
Eto igabnisiṣẹ
- Da iṣẹ ti iye rẹ to miliọnu kan silẹ ni ẹka imọ ICT laarin ọdun meji
- Fi adinku si airiṣẹṣe nipa ṣiṣe atilẹyin fun awọn banki lati maa ya awọn ọdọ olokowo kekek lowo
- Ṣe atilẹyin fun miliọnu meji oniṣowo lati kọ awọn ọdọ lori bi wọn ṣe maa da ileeṣẹ silẹ
Eto ilera
- Ṣe ifilọlẹ eto adojutofo eto ilera fun o kere tan ida ogojin awọn ọmọ Naijiria laarin ọdun meji pere
- Ṣe afikun ati idanilẹkọ fun awọn oṣiṣẹ eto ilera, paapaa awọn to wa ni ẹka eto ilera alabode
- Ṣe atilẹyin fun kikọ awọn ile iwosan alagbeka fun anfani araalu
- Ṣe atilẹyin fun ipese ipese oogun ati abẹrẹ ajẹsara labẹle
Eto abo
- Ṣe afikun owo oṣu awọn oṣiṣẹ eto abo ati ipese iranwọ fun awọn ọmọ ogun to ṣubu loju ija ati awọn to farapa
- Ṣe itgbesoke ohun ija, ohun elo ibaraẹnisọrọ ati ọkọ awọn awọn ọmọ ogun
- Ṣe igbanisisẹ ati idanilẹkọ awọn ọmọ ogun atawọn oṣiṣẹ eto abo
- Fi opin si ikọlu awọn agbebọn si dukia ijọba
Eto ẹkọ
- Ṣe atunṣe ẹka eto ẹkọ lati ile ẹkọ alakọbẹrẹ titi de ile ẹkọ giga
- Ṣe ifilọlẹ eto ẹyawo fun awọn akẹkọọ
- Gbe owo kalẹ fun eto ẹkọ lara eyii ti awọn akẹkọọ yoo ti maa ya
Iwa ajẹbanu
- Fi gbedeke si iye owo ti awọn adari atawọn oṣisẹ ijọba yoo maa na
- Fi adinku si iye owo ijọba to n ṣofo
- Ṣe iwuri fun awọn oṣiṣe to jafafa ki a si tu aṣiiri awọn ayederu oṣiṣẹ ijọba to n gba owo oṣu lai ṣiṣẹ
- Fi adinku si bi iṣẹ ijọba ṣe n falẹ
Labour Party
Awọn ohun to ṣe pataki
- Ṣe awọn ohun to ki ofin le fẹsẹ mulẹ, doju ija kọ iwa ajẹbanu ki a si ṣadinku iye owo ti ijọba n na
- Mu Naijiria kuro ni ipo orilẹ-ede to n ko ọja wọle nika si eyii to n ko ọjalọ silẹ okere fun tita
- Ran awọn araalu lọwọ lati ṣe aṣeyọri nipa ṣiṣe atilẹyin fun imọ sayẹnsi, imọ ẹrọ ati eto ẹkọ
Eto ọrọ aje
- Mu ayipada ba ọrọ ajẹ pẹlu atilẹyin fun eto ọgbin
- Din ọwọngogo ounjẹ atawọn nnkan mii ku, rii daju pe banki apapọ CBN ni ominira
- Fi adinku si igbẹkẹle ijọba lori epo rọbi nikan
- Yọ awọn ofin to mu ko ṣoro lati ko ẹru ato owo wọle lati ilẹ okeere
Eto igabnisiṣẹ
- Ṣi anfani silẹ awọn olowo kekeke lati ya owo lọna ati di airiṣẹ ṣe ku lawujọ
- Ṣe idagbasoke awọn araalu
- Mu irọrun ba karakata lọna ati le mu ki awọn ileesẹ ilẹ okere wa si Naijiria
- Ṣe awọn eto ti yoo mu ko rọrun fun awọn olokowo kekeke lati gberu si
Eto ilera
- Ṣe afikun owo oṣu ati igbeaye awọn oṣiṣẹ eto ilera
- Pese eto adojutofo eto ilera fun 133 miliọnu eeyan to kuṣẹ julọ ni Naijiria
- Pese idanilẹkọ to peye fun awọn oṣiṣẹ eto ilera ki wọn le jafafa si lẹnu iṣẹ wọn
- Fun araalu ni anfani si eto ilera pẹlu owo perete
Eto abo
- Fopin si ikọlu awọn abebọn
- Fọwọsowọpọ pẹlu awọn orilẹ-ede ayika fun abo awọn ẹnubode wa
- Ṣagbekalẹ ofin fun idasilẹ ọlọpaa agbegbe
- Gba ọpọ eeyan siṣẹ ologun, ọlọpaa atawọn iṣẹ eto abo mii, a oo si fun wọn ni idanilẹkọọ atawọn atilẹyi mii ti wọn bas n fẹ
Eto ẹkọ
- Gbe owo tabua kalẹ fun ẹkọ iṣẹ ọwọ, ere idaraya atawọn eto ẹkọ mii to rọ mọ imọ ẹrọ
- Ya ọpọ owo sọtọ funeto ilera, eto ẹkọ ati ile gbigbe
- Faye gba awọn ileeṣẹ aladabi lati maa dari awọn ile ẹkọ, ki ijọba si maa bojuto awọn ohun ti wọn n kọ nibẹ
- Na ida 14% owo ijọba si eto ẹkọ
Iwa ajẹbanu
- Ṣiṣẹ ni ilana to ba ofin iṣẹ ijọba mu
- Maa ṣe ayẹwo bi gbogbo ẹka ṣe n na owo loorekoore
- Fopin si afikun iranwo owo epo
- Ṣe gbogbo iṣẹ ijọba ni gbangba loju gbogbo araalu
New Nigeria Peoples Party
Awọn ohun to ṣe pataki
- Pese iṣẹ nipa eto ọgbin
- Yanju iṣoro eto abo
- Bọwọ fun ofin, a o si ṣe ohun gbogbo lọna to ba ofin mu
Eto ọrọ aje
- Gbogun ti iwa ajẹbanu ni gbogbo ẹka ijọba lọna ati pa owo wọle fun ijọba
- Ṣe igbelarugẹ eto ọrọ aje
- Ṣe atunṣe si ipaarọ owo ilẹ okere
Eto igabnisiṣẹ
- Mu adinku ba ainiṣelọwọ ọpọ araalu
- Ṣe iwuri fun awọn ọdọ lati kopa ninu eto ọgbin
- Ṣe iwuri fun awọn ileeṣẹ aladani lati da awọn ileeṣẹ to n pese ounjẹ silẹ ki awọn ọdọ le riṣẹ ṣe
Eto ilera
- Ṣe atunṣe si eto adojutofo eto ilera ijọba apapọ
- Mu adinku ba bi awọn araalu ṣe n lọ si oke okun fun itọju nipa ṣiṣe atunṣe si awọn ile iwosan wa ati fifun awọn oṣiṣẹ eto ilera wa ni ẹkọ to peye pẹlu ipese awọn irinṣe igbalode
- Ṣe afikun eto iṣuna ẹka eto ilera
Eto abo
- Gbogun ti iwa igbesumọmi
- Ṣe atilẹyin fun iṣọkan awọn ọmọ Naijiria
- A ko ni fi ohunkohun pamọ fun araalu
Eto ẹkọ
- Pese owo gọbọi fun ẹka eto ẹkọ
- A o ṣe igbeleke awọn ile ẹkọ giga wa ki a to maa da awọn miran silẹ
- A o gbiyanju lati kọ ile gbigbe fun 20 miliọnu awọn ọmọ ti ko si nile ẹkọ to wa laarin igboro wa
Iwa ajẹbanu
- A oo ṣe atilẹyin fun awọn ajọ ijọba to gbogun ti iwa ajẹbanu
- A ko ni fi ohunkohun pamọ fun araalu
- A oo lo imọ ẹrọ lati gbogun ti iwa ajẹbanu
Peoples Democratic Party
Awọn ohun to ṣe pataki
- Fun ẹka aladani laaye lati ṣiṣẹ daadaa
- Ṣe atilẹyin fun iṣọkan Naijiria nipa yiyan awọn lati gbogbo Naiojiria sipo ijọba
- Ṣe atunto eto ijọba Naijiria
Eto ọrọ aje
- A o ri daju pe GDP yoo ti gberasọ si ilọpo meji iyẹ $5,000 (£4,200) titi ọdun 2030
- Ṣe agbekalẹ awọn amayedẹrun faraalu
- A oo ṣe afikun bi a ṣe n wa epo rọbi si miliọnu meji 'barrels' lọjọ kan ṣoṣo titi ọdun 2027
Eto igabnisiṣẹ
- A oo da milọnu mẹta tuntun silẹ, a o si mu miliọnu mẹwaa eeyan kuro ninu iṣẹ
- A o ṣe agbekalẹ eto igbanisiṣẹ fun awọn araalu
- Idasilẹ awọn ileeṣẹ ti yoo ran awọn olokowo kekeke lọwọ
Eto ilera
- A o ṣagbekalẹ eto ilera ti owo rẹ ko dani lagara fun awọn araalu ko to di ọdun 2030
- A o ṣe iwuri fun awọn dọkita to wa nilẹ okere lati pada wale
- Atilẹyin fun awọn ileeṣẹ apoogun lati maa po oogun labẹle
Eto abo
- A o ṣeto iforukọsilẹ awọn ọmọ tuntun lati mọ iye araalu ati lati gbogun ti iwa ọdaran
- A o gba nnkan bii miliọnu kan eeyan siṣẹ ọlọpaa gẹgẹ bii alakalẹ UN
- Ṣe atunṣe si ibaṣepọ awọn ọmọ ogun atawọn araalu
- Ṣe atunto ẹka eto abo
Eto ẹkọ
- Ṣe igbelarugẹ ẹkọ imọ syẹnsi ati iṣẹ ọwọ
- Ṣe agbẹkalẹ ileeṣẹ ti yoo maa bojuto awọn ile ẹkọ giga
- Na obitibiti owo si ọna oju popo, oju irin, ina mọnamọna ati ile gbigbe
Iwa ajẹbanu
- Ṣe eto iwuri fun awọn oṣiṣẹ ijọba
- Lo imọ ẹrọ lati gbogun ti iwa ajẹbanu
- A o ri daju pe awọn idajọ ile ẹjọ lori iwa jẹgudujẹra mulẹ









