Ìdìbò tó ń bọ̀ yìí, Ọrọ̀ ta ló tọ́, ta ni Ifa mú ni, Asiwaju Tinubu sì ni Ọlọ́run rán! – Oba Elegushi

Àkọlé fídíò, Oba Elegushi: Ẹni tí Ọlọ́run bá mú láti jẹ Ọba, gbogbo yín gbúdọ̀ gbárùkù tìí ni bí bẹ́ẹ̀

Ọba Ademola Elegushi ninu ifọrọwanilẹnuwo yii ṣe afiwe ọrọ to n sọ pẹlu bi o ṣe wa ninu aṣa Yoruba to jẹ wipe lati kekere ni wọn a ti maa tọka si ọmọ kan pe “Ọba lọla ni ọmọ yii o”. O ni atigba naa si ni wọn a ti maa tọju ti wọn a maa kọ ọmọ naa fun ipo Ọba.

“Ọlọrun ko ni sọkalẹ, eeyan kan naa lo maa ran, Asiwaju l’Ọlọrun ran, Ọlọrun dẹ ran an sibi ti Ifa naa sọ.

Elegushi ni oun ti ba Asiwaju ṣiṣẹ daadaa ni ipo iṣejọba to ti wa sẹyin gẹgẹ bii oluranlọwọ pataki fun Bola Tinubu to si ni oun ti kọ ọgbọn ati oye lara Asiwaju gẹgẹ bi ọmọluabi ti wọn biire.

“Ọgbọn ati oye ti mo kọ lọdọ Asiwaju lati le maa ba awọn eeyan ṣe lo ran mi lọwọ nigba ti mo de ori alefa”.

Ọba Elegushi

O ni ninu idile oye, ọmọ Ọba pọ amọ “t’Ọlọrun ba ti mu eeyan kan ninu ẹbi, gbogbo yin maa gbaruku ti i ni, ẹni ti ko ba dẹ gbaruku ti i, nnkan to ba ri a fi ori ara rẹ gbe e.”

Torinaa, Elegushi fọwọ sọya pe o da oun loju pe gbogbo iṣoro to n koju Naijiria yii yoo to wa sopin bi wọn ba yan adari ti yoo mu orilẹede lọ ibi giga ninu idibo ọjọ Kẹẹdọgbọn Oṣu Keji.

Ki lo ṣẹlẹ si ibaṣepọ laarin Ọba Ouwo ati Ọba Elegushi ti wọn o rin papọ mọ́?

Ọba Elegushi, Tinubu ati Oluwo

Ọba Elegushi ṣalaye pe oun ko ba ẹnikẹni ja rara. Ọpọlọpọ eeyan lo mọ Elegushi ati Oluwo papọ nibayii, o jọ pe nnkan ko fi bẹẹ danmọran mọ laarin wọn.

“Teeyan ba fi eeyan si aye rẹ ko tumọ si pe o ba eeyan ja. Onikaluku gbọdọ̀ mọ iwọn ara rẹ.

A o mọ iwọn ara wa tẹlẹ ni ṣugbọn nisisiyi, onikaluku ti mọ iwọn ara rẹ, onikaluku joko si aye ẹ, iyẹ kii ṣe ija”.

Ọba Elegushi