Ohun tí ọlọ́pàá ń ṣe fún adigunjalè ló lè ṣè fún olùwọ́de tó bá kọlu banki- iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, BBC/Nigeria police
Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti sọ pe adigunjale ni ẹnikẹni to ba kọlu ile ifowopamọ si, ẹrọ apọwo ATM, ọna ti agbofinro ba si fi n koju awọn adigunjale ni wọn yoo fi koju ẹnikẹni to ba fi iwọde boju lati kọlu banki tabi ẹrọ ATM.
Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Ọmọọba Olumuyiwa Adejọbi lo sọ eyi ninu atẹjade kan to fi si oju opo Twitter rẹ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa naa ṣe alaye yii lori iroyin bi awọn oluwọde ṣe n kọlu banki ati ẹrọ apọwo ATM lawọn agbegbe kan lorilẹede Naijiria.
“O yẹ ka ran awọn eeyan leti pe ẹnikẹni to ba kọlu banki, ẹrọ apọwo ATM, adigunjale ni, bi wọn si ṣe n koju adigunjale ni wọn yoo ṣe doju kọ wọn.”
O ni awada nla ati iwa aimọkan n ṣe ọpọ ọmọ orilẹede yii lori gbedeke ibi ti awọn oluwọde loore ọfẹ lati de.
Adigunjalè làwọn olùwọ́de tó ń kọlu báńkì, ATM, ohun tí òfin ní kí ọlọ́pàá ṣe fún wọn nìyí
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ni iyalẹnu lo jẹ pe awọn eeyan kan, eyi ti ko yọ awọn to kawe pẹlu silẹ, n bu ẹnu atẹ lu ileeṣẹ ọlọpaa lori bi awọn ọlọpaa ṣe yinbọn tu awọn oluwọde to lọ kọlu ẹka banki apapọ Naijiria CBN to wa nilu Benin.
“Bi ọwọ ofin ba tẹ ọ tabi bi wọn ba kẹfin rẹ ni sakani banki apapọ CBN pẹlu erongba ati kọlu u, ọlọpaa laṣẹ ati agbara lati kọlu ẹni bẹẹ pẹlu gbogbo ọna to ba wo pe o yẹ, paapaajulọ bi wọn ba ri pe ẹni bẹẹ ni nnkan ija lọwọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
O wa rọ gbogbo awọn to n ṣe iwọde lati rii pe wọn n ṣe ohun gbogbo ti wọn n ṣe bi o ti tọ ati bi o ṣe yẹ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Ọmọọba Muyiwa Adejọbi ni iwoye awọn agbofinro fihan pe ọpọ awọn to n ṣe iwọde lawọn ilu kaakiri nipa inira ọwọngogo owo naira yii ni o n ṣe bẹẹ nitori ati le ji nnkan tabi hu iwa ipa lati ṣe afọwọra ohun ti kii ṣe tiwọn.
O ni awọn wọnyii lo si n ta ẹrẹ ba awọn to n ṣe iwọde naa nitootọ.












