Mo mọ̀ pé èmi ni mo ni gbogbo àwọn èèyàn Ogun, báa bá fẹ́ dìbò àmọ́ mi ò lè kó wọn silẹ̀ fún ẹnikẹ́ni - Sẹ́nétọ̀ Yayi

Àkọlé fídíò, Senator Yayi: Àwọn tó ń ní owó tí wọ́n ń gbà nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin ti pọ̀jù, irọ́ ńlá ló pọ̀

Saa meji ni Sẹnetọ Solomon Olalekan ti lo nile igbimọ aṣofin Naijiria nibi to ti ṣoju ẹkun Iwọ-Oorun ipinlẹ Eko.

Ni bayii, o n gbero lati ṣe saa kẹta nile aṣofin aṣofin bayii gẹgẹ bi aṣoju ẹkun Iwọ- Oorun nipinlẹ Ogun.

Bakan naa, o mẹnu ba aawọ to suyọ laarin rẹ, gomina ana nipinlẹ Ogun Ibikunle Amosun ati gomina to wa lori alefa lọwọlọwọ nipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun.

Sẹnetọ Yayi

Gẹgẹ bi ọpọlọpọ ṣe maa n pe e, Yayi ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba ṣalaye idi ati bo ṣe rii ṣe to re lati ipinlẹ Eko si Ogun to si tun fẹ jẹ Sẹnetọ.

Bakan naa, o sọ idi ti ipo Sẹnetọ Ogun West ṣe tọ sii ju gbogbo awọn to ku ti wọn jọ n du ipo naa to sijẹ pe inu oṣelu Ogun ni wọn bi awọn si.

Yayi tun fesi lori ọrọ ti awọn eeyan maa n sọ pe owo gọbọi gọbọi lawọn aṣofin n gba, o ni irọ gbaa ni.