Àwọn ọmọ Nàìjíríà yarí, wo bí wọ́n ṣe ń bọ́ gidi fún ìjọba torí àṣẹ "má ná owó náírà àtijọ́"

Àkọlé fídíò, New naira note: Hàà New noòtì ni o! Ẹni tí kò bá ti ní new note kó padà sílé o!

"Ìyàwó ilé ń “suffer” o, Dẹ́rẹ́bà Danfo gan ò gbádùn o, ile epo o gba owo, a o r'owo na o!"

Awọn ọmọ Naijria n rawọ ẹbẹ si ijọba apapọ lati ṣaanu awọn mẹkunu tori pe iya ti pọ nitori latari ipenija aisi owo naira ti wọn le na.

Ikọ iroyin BBC Yoruba bọ sigboro lawọn ilu kọọkan nilẹ Yoruba lati gbọ latẹnu awọn eeyan iru ohun ti wọn fara gba latari ko si owo yii.

Awọn ọmọ Naijiria

Lara awọn taa ba sọrọ to jẹ olukọni nipa ọkọ wiwa, Festus Akinola ni "owo ti wọn ni awọn maa ko kuro nilẹ ti wọn parọ yii, ohun ni gbogbo eniyan ṣi n na, a dẹ ti pinu pe laarin ara wa, aa maa gba a lọ, a ko ni ko o lọ sile ifowopamọ".

Awọn ọmọ́

Bakan naa Ararin Adijatu Kehinde ni ọja ko lọ dede mọ, awọn o ta lati aarọ ati pe ko tilẹ si owo lati tọju awọn ọmọ.

Gbogbo wọn ṣaa n pariwo pe ko si Banki to n gba owo naira atijọ lọwọ awọn.

Koda awọn awakọ gaan yari pe ẹni ti ko ba ti ni owo naira tuntun lọwọ ko pada sile.