'Torípé a wà lókè òkun, ẹ ní a ò lè dìbò, èyí kò dára rárá! Ohun táà fẹ́ rèé'
Gẹgẹ bi eto idibo ṣe n sunmọ lorilẹede Naijiria ti ipolongo ibo naa si n lọ lọtun losi, awọn ọmọ Naijiria to wa niluu gangan nikan lo n kopa.
Awọn ọmọ Naijiria to ti lọ soke okun fi erongba wọn han lori eyi lasiko ti wọn n ba BBC sọrọ.

Toripe awọn to n gbe ni orilẹede yii nikan naa lo lee lọ si ibudo idibo lati lọ tẹka, awọn to n gbe loke okun ni o yẹ ki aato wa fun awọn naa.
Ninu ifọrọwanilẹwo BBC yii pẹlu awọn ọmọ Naijiria to n gbe loke okun, wọn sọ ohun ti wọn ro gẹgẹ bi wọn yoo ṣe padanu anfani lati ko ipa to ṣe koko ninu awọn idibo to n bọ lọna.












