Ìdí tí mó ṣe fi ìlú òyìnbó sílẹ̀ wá dupò Aṣojú-ṣòfin fún Ogbomoso Sothwest rèé – Họ́nọ́rébù Onireti
"Lóòtọ́ mo lè gbé lókè òkún àmọ́ Nàìjíríà tí mo ti ní iléèṣẹ́, okóòwò, ó yẹ kí n lè ṣe aṣojú ilé aṣòfin ni Naijiria".
Eyi ni ọrọ oludije sipo aṣoju-ṣofin to fẹ ṣoju iha Guusu-Iwọ Oorun ilu Ogbomoso, Họnọrebu Olufemi Onireti to jẹ olugbe ilẹ Amẹrika amọ ọmọ bibi ilu Ogbomoso ni.
Iriri rẹ ati ohun ti ẹbi rẹ la kọja nipa aisi awọn nnkan amayedẹrun ni ilu rẹ lo ṣalaye pe o mu oun pada wa si Naijiria lati wa du ipo aṣoju-ṣofin ko ba le ṣe nnkan irọrun si ilu nipasẹ ipo naa.
"Lóòtọ́ mo lè gbé lókè òkún àmọ́ Nàìjíríà tí mo ti ní iléèṣẹ́, okóòwò, ó yẹ kí n lè ṣe aṣojú ilé aṣòfin".

'Mo mọ̀ pé ìyà omí ń jẹ́ wọ́n l’Ogbomoso, a ti ṣe iṣẹ́ púpọ́, ìdí tí mo si fi fẹ́ ṣojú nílé ìgbìmọ̀ aṣojú-ṣòfin rèé'

Họnọrebu Onireti ninu ifọrọwanilẹnuwo yii pẹlu BBC Yoruba jẹ ko di mimọ pe oun ni ileeṣẹ ni orilẹede Naijiria ti oun si n da okoowo tori naa, o yẹ ki oun naa le wa nnkan ṣe si ilu oun, eyi lo jẹ ki oun wa si Naijiria lati wa pe apoti oṣelu.
Pabanbari idi to sọ nipe, oun ni imọlara iya to jẹ awọn ara ilu Ogbomoso daadaa.
O mẹnu ba ipenija omi ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin ti mọlẹbi rẹ ṣi n tiraka to bẹẹ to jẹ pe wọn maa n da Garri sinu omi Kanga ki wọn to le rii mu.
"Mo súnmọ́ aráàlú, tí mo bá tún dé ipò Aṣójú-ṣòfin, máà tún súnmọ́ ìlú síi.
Taa ba nifẹ araalu lootọ, a o ni maa ko janduku kiri nilu."
Onireti gba awọn oloṣelu ẹgbẹrẹ nimọran lati dẹkun lilo janduku lati fi gba ipo.















