Ẹ wo bí àwọn mọ́lẹ̀bi Adeniran ṣe di ẹnu ìbodè Iléẹ̀kọ́ Chrisland

Àwọn aláṣẹ Chrisland School tún ṣí apákan ilé ẹ̀kọ́ wọn, wọ́n ní ẹ̀ka girama nìkan nìjọba tì pa

Ileẹkọ Chrisland Shool Ọpẹbi nilu Eko ko tẹle aṣẹ ipinlẹ Eko pe ko wa ni titipa fun igba diẹ na titi ti wọn yoo fi pari iwadi lori iku akẹkọkọ ile ẹkọ girama rẹ kan to jade laye lasiko eto idije ere idaraya onilejile inter house sport to waye l’Ọjọbọ to kọja ni papa iṣire Agege stadium.
Ijọba ipinlẹ Eko pa aṣẹ pe ki ile ẹkọ naa wa ni titipa ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ eto ẹkọ tijọba ipinlẹ Eko fi sita lọjọ Aiku pe ki ileewe naa wa ni titipa.
Amọṣa nigba ti ikọ BBC News Yoruba de ile ẹkọ naa lowurọ ọjọ Aje, ẹka girama ile ẹkọ naa nikan ni wọn gbe ti pa ti iṣẹ ẹkọ si n lọ ni ẹka alakọbẹrẹ ni ile ẹkọ naa.
Bi o tilẹ jẹ wi pe ile ẹkọ “Chrisland Schools” Ọpẹbi ni ijọba ipinlẹ Eko paṣẹ pe ki wọn ti pa lai mẹnuba girama tabi alakọbẹrẹ, awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa n sọ pe ẹka ti ile ẹkọ girama nikan ni aṣẹ ijọba ipinlẹ Eko kan, ko kan ẹka ti alakọbẹrẹ.
Ikọ BBC News Yoruba tun fi idi rẹ mulẹ pe awọn oṣiṣẹ ile ẹkọ girama naa wa ninu ile ẹkọ naa ti wọn n ba iṣẹ lọ, awọn akẹkọọ nikan ni ko wọle.
Igbesẹ yii ti n fa oruyeye ati gbodonroṣọ latọdọ awọn mọlẹbi Whitney Adeniran, akẹkọọ to di oloogbe naa pẹlu bi wọn ṣe n kọminu pe iwa ainitara ọmọ ni awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa hu ti ko si bojumu.
Ninu ọrọ ti awọn kan lara wọn ba awọn oniroyin sọ, idajọ ododo lawọn n wa lori ọrọ naa ati pe awọn ko fẹ ki ẹnikẹni fi ọwọ agbara bo abajade iwadi lori ohun to ṣokunfa iku akẹkọọ naa mọlẹ.
‘Irọ ni gbogbo ọrọ ti ile ẹkọ Chrisland n sọ lori iku Whitney Adeniran’.

Awọn mọlẹbi akẹkọọ to ku naa, Whitney Adeniran, sọ pe gbogbo ohun ti awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa n sọ pe ṣe ni Whitney ṣubululẹ ku ati pe iku rẹ nii ṣe pẹlu aisan ọkan.
Ọkan lara awọn mọlẹbi naa kan to ba awọn akọroyin sọrọ ṣalaye pe, ipo ti oku ọmọ naa wa ko daju pe aisan ọkan lo ṣokunfa iku rẹ.
“To ba jẹ ohun ti wọn n sọ ni pe ọmọ naa ṣubululẹ ku ni, ki lo wa de ti ahọn rẹ yọ sita gelete ti yoo si dudu nigba to ku? Ṣe ete ọmọ naa yoo dudu? Ṣe gbogbo ara rẹ yoo dudu?
Arabinrin naa ni awọn ko gba nnkan ti wọn n sọ gbọ rara, idajọ ododo lawọn n beere fun lori iku Whitney Adeniran.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti iléẹ̀kọ́ Chrisland tí Whitney Adeniran ti fò ṣánlẹ̀ kú

Oríṣun àwòrán, Lagos State Government
Ijọba ipinlẹ Eko ti paṣẹ ki wọn ti ileẹkọ Chrisland School to wa ni agbegbe Opebi-Ikeja pa fun saa yii.
Eyi ko ṣẹyin iṣẹlẹ laabi to waye nibẹ nibi ti akẹkọọ ileẹkọ naa, Whitney Adeniran ti fo ṣanlẹ ku.
Ninu atẹjade ti ipinlẹ Eko fi sita latọwọ kọmiṣọnna fun eto ẹkọ, Abilekọ Folasade Adefisayo lo fi aṣẹ naa lede.
Abilekọ Adefisayo ni o pọn dandan lati ti ileẹkọ naa lasiko yii titi iwadii yoo fi pari lori iṣẹlẹ naa.
A o rii pe idajọ ododo jọba lori iṣẹlẹ naa.
Ninu atẹjade naa ni ijọba ipinlẹ Eko ti ni awọn ba iya ati baba Whitney Adeniran ati awọn mọlẹbi rẹ kẹdun iṣẹlẹ naa.
Bakan naa ni wọn gbadura pe ki Edua tẹ ọmọ naa si afẹfẹ rere.
‘’A ri ipa ti iṣẹlẹ yii ni lori awọn ọrẹ, ẹbi ati awọn to mọ Whitney, ti a si ba wọn kẹdun.’’
Amọ a n fi asiko yii rọ awọn eniyan lati gba alaafia laaye titi iwadii yoo fi pari.
Ijọba ipinlẹ Eko fikun un pe awọn yoo ripe gbogbo ofintoto to yẹ ki awọn ṣe nitori iṣẹlẹ naa ni wọn yoo ṣe.
Wọn si fi da awọn eniyan loju pe otitọ yoo jọba lori iṣẹlẹ naa.
Ohun ti a mọ nipa bi akẹkọọ Chrisland, Whitney Adeniran ṣe ku?

Oríṣun àwòrán, Dr Adeniran
Iya ọmọ naa, Blessing Adeniran ninu fidio to fi lede lori Instagram ni ọmọ oun darapọ mọ awọn akẹkọọ to ku lati lo ṣe ere idaraya inter House sport ileẹkọ naa ni papa iṣere Agege nipinlẹ Eko.
Amọ iya naa ni ara bẹrẹ si ni fun oun lẹyin ti ko ri ọmọ naa lati darapọ mọ rinrin ologun, iyẹn marchpast bi awọn ẹgbẹ rẹ.
Iya naa ni eyi lo mu oun lọ si ita lati lọ wa ọmọ naa, ti oun si rin lọ si ibi ti wọn ti ọmọ kan ṣubu to si daku.
Lẹyin naa ni wọn sọ fun iya naa pe ọmọ rẹ ni ati wipe wọn ti gbe lọ si ileewosan to sunmọ tosi.
Amọ iya ọmọ naa ni oku ọmọ ni oun ba ni ileewosan ti wọn ti n gba abẹrẹ ajẹsara fun awọn ọmọde .
Iya naa ni oun ti ri ni pe ahọn ati ẹnu ọmọ naa dudu.
Amọ baba ọmọ naa ni awọn ti oun ba sọrọ lati ṣewadii iku ọmọ naa ni o ṣeeṣe ki o gbẹṣe le ina nibi ti ọmọ naa ti lọ ra nkan ipanu nibi ayẹyẹ inter-house sport ọhun.
Ninu ọrọ ti wọn, ileẹkọ ni niiṣe ni ọmọ naa dede daku silẹ to si gba ibẹ lọ amọ ti awọn gbiyanju lati doola ẹmi rẹ nipa gbigbe lọ si ileewosan to sunmọ tosi.













