'Irọ́ ni iléẹ̀kọ́ Chrisland ń pa nípa ikú ọmọ mí, ńkan tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹgbẹ́ rẹ̀ sọ fún mi rèé...'

Oríṣun àwòrán, Others
Baba Whitney Adeniran, Micheal Adeniran ti sọ ni gbangba pe irọ ni ileẹkọ Chrisland n pa lori ohun to fa iku ọmọ rẹ.
Baba Whitney sọ eyi lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ lori iku ọmọ rẹ.
O ni ọmọ ohun to jẹ ẹni ọdun mejila lo ku lasiko ti wọn n ṣe ere idaraya ‘’Inter-house sports’’ ni agbegbe papa iṣere Agege stadium, ni ipinlẹ Eko.
Awọn akẹgbẹ Whitney sọ ohun to ṣẹlẹ fun wa – Baba Whitney
Ninu ọrọ ti baba rẹ sọ fun awọn oniroyin lo ti ni awọn ileẹkọ naa n tiraka lati bo otitọ ọrọ naa mọlẹ.
O ni ileẹkọ naa, ati dokita ati nọọsi ileewosan ti wọn gbe ọmọ naa lọ lo kọkọ sọ fun wọn pe ki wọn ma ṣe ayẹwo oku naa nitori ohun to ti ṣẹlẹ ti ṣẹlẹ.
‘’Lasiko ti a wa ni ileewosan ni mo sọ fun wọn pe mo fẹ mọ bi ọmọ mi ṣe papoda amọ awọn lo sọ fun mi pe ki n gba kadara.
‘’Mo ni rara mo gbọdọ mọ ohun to ṣẹlẹ si ọmọ mi, nibi ti a ti n ba awọn akẹkọọ to wa nibẹ nigba ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni wọn ti n sọ pe kilo de ti awọn adari ileẹkọ Chrisland n parọ nipa ohun to ṣẹlẹ?’’
‘’Awọn ọmọ naa ni gbogbo awọn lo ri ohun to ṣẹlẹ nibẹ pe kilo de ti awọn olukọ ko jade lati sọ otitọ?’’
Bakan naa ni Baba Whitney fikun un pe lẹyin igba ti awọn olukọ wa si ile awọn ni ọjọ keji iṣẹlẹ naa, ti gbogbo igbiyanju wọn lati fa wọn ṣẹyin nipa ọrọ ayẹwo oku ko wọle si wọn leti ni wọn wa kede pe awọn naa fẹ ṣe Autopsy.
‘’Emi ni mo sọ pe mo fẹ ṣe autopsy ọmọ mi lati mọ iru iku to paa, amọ ileẹkọ wa n sọ bayii pe awọn yoo ṣe.’’
‘’Eyi tunmọ si pe ọwọ ti wẹ ọwọ, ohun lo si mu mi lọ si ileewosan Lasuth lati lọ ba awọn olori ẹka ileewosan naa sọrọ ki wọn sọ otitọ nipa iṣẹlẹ naa.’’
Baba Whitney wa pe fun idajọ ọdọ lori iṣẹlẹ naa ki awọn le sin ọmọ wọn.
Iyabo Ojo, Mercy Johnson sọ̀rọ̀ lórí ikú Whitney Adeniran, akẹ́kọ̀ọ́ Chrisland School

Oríṣun àwòrán, iyaboojofespris/mercyjohnsonokojie/instagram
Nnkan ko rọrun fun ile ẹkọ Chrisland lati nnkan bii wakati mejidinlaadọta sẹyin bayii lẹyin ti iroyin iku akẹkọbinrin Whitney Adeniran jade si igboro aye.
Nibayii awọn gbajumọ oṣere ati ilumọọka lawujọ pẹlu ti n sọrọ soke lori iṣẹlẹ naa.
Gbajumọ oṣere sinima, Iyabọ Ojo ti ke si awọn alaṣẹ ile ẹkọ Chrisland pe asiko to lati na tan fun awọn obi Whitney Adeniran, akẹkọọ ile ẹkọ naa to jade laye l’Ọjọbọ to kọja.
Ninu atẹjade kan to fi sita loju opo Instagram rẹ, Iyabọ Ojo sọ pe pẹlu awuyewuye ẹsun baba ọmọ naa ati ohun akasilẹ kan ti awọn kan fura pe o jẹ ti akẹkọọ kan ni ile ẹkọ naa to n lọ kiri bayii pe ina ẹlẹntiriki lo ṣokunfa iku ọmọdebinrin naa.
Lootọ awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa fi sita pe ojojo ti n ṣe ọmọ naa fun igba diẹ, eyi tako ohun ti awọn obi ọmọ naa n sọ.
Christland gbọdọ ṣalaye okodoro ọrọ nipa iku Whitney fun awọn obi rẹ -Iyabọ Ojo

Oríṣun àwòrán, iyaboojofespris/instagram
Ilumọọka oṣere naa ṣalaye peasiko to fun ile ẹkọ naa lati ṣalaye otitọ ohun to ṣẹlẹ gangan.
“#chrislandinsta ẹ nilo lati jade wa ṣalaye fun awọn obi Whitney otitọ ọrọ nipa iṣẹlẹ ikun ọmọdebinrin wọn. Iwa aibikita ti ile ẹkọ yin n hu kọja bẹẹ gbaa.”
Bakan naa ni Iyabọ Ojo tun beere awọn ibeere kan ninu atẹjade rẹ naa eleyi to ni o kan dandan ki awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa pese idahun si.
“akasilẹ ohun kan lori Whatsapp n sọ pe ina ẹlẹntiriki lo pa ọmọ yii. Ṣe lootọ ni abi irọ? Ṣ ẹ ṣe ayẹwo ohun elo ti awọn ọlọja ti ẹ pe fun eto naa gbe wa lati rii pe ko ni ewu fun awọn ọmọde? Ẹ mọ pe ọmọ naa ti jalaisi ki ẹ to gbe e lọ si ile iwosan alabọde ti ẹ si wa n jẹ ki iya rẹ maa sa kijokijo kiri lai wa pẹlu rẹ.”
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
Mercy Johnson ni Christland gbọdọ gba aṣiṣe rẹ
Ninu ọrọ tirẹ, gbajumọ oṣere sinima Mercy Johnson ṣalaye ni tirẹ rọ awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa lati gba aṣiṣe wọn lori iṣẹlẹ naa ki wọn si ṣalaye lẹkunrẹrẹ bi iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ.
O ni irora to pọ julọ ti iya le la kọja ni ki iku ojiji wọle mu ọmọ rẹ lọ
“Lati igba ti mo ri fidio yi laarọ yii ni mo ti n ke si @chrislandinsta lati ṣe ohun ti iya Whitney beere fun ki wọn si ṣe alaye lẹkunrẹrẹ ohun to ṣẹlẹ si ọmọ rẹ. Gbogbo wa la n reti.”
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2

Oríṣun àwòrán, others
Awọn alasẹ ileẹkọ Chrisland College ti sọrọ jade lori iṣẹlẹ kan to waye ni ileẹkọ naa, eyi to mu ẹmi ọkan lara awọn akẹkọọ wọn Whitney Adeniran lọ.
Arabinrin Blessing Adeniran to jẹ iya ọmọbinrin naa lo salaye bi ọmọ rẹ, Adesola Adeniran sẹ di oloogbe lasiko ere idaraya ojule-si-ojule, inter-house sport ti ileẹkọ Chrisland College.
Arabinrin Blessing naa kegbajare lori ẹrọ ayelujara nibi to ti sọ iriri rẹ ni Ọjọ Kẹsan an, Oṣu Keji, ọdun 2023.
Ninu atẹjade ti ileẹkọ naa gbejade loni, wọn ni pẹlu ibanujẹ ọkan ni awọn fi n kede ipapode ọkan lara akẹkọọ wọn, ẹni to jade laye lọjọbọ, Ọjọ kẹsan, oṣu keji, ọdun 2023.
“Inu wa bajẹ nitori ọkan lara ọmọ wa ni Whitney to ni ko wu ohun lati kopa ninu ere idaraya ojule-si-ojule nitori idi kan tabi omiran ti a ko mọ.
“Lọgunjọ, oṣu kini ọdun yii, a pe akiyesi awọn obi ọmọ yii nigba to sọ fun wa pe oun ko mọ bi o ṣe ṣe oun ni ago ara.
“Baba ọmọ, Michael Adeniran, wa si ileẹkọ lati wa mu ọmọ naa lọ si ile. A rọ awọn obi lati tọ ju ọmọ naa.”
Ileẹkọ naa ni oloogbe naa sa dede suubu ni itagbangba, ti wọn si sure gbe lọ si ilewosan to sumọ ileẹkọ naa fun itọju.
A rọ awọn obi ọmọ naa lati ṣe ayẹwo lati mọ iru iku to pa Whitney
Ileẹkọ Chrisland ti wa rọ awọn mọlẹbi Adeniran lati ṣe ayẹwo lori iku to pa ọmọ wọn ki wọn to gbe lọ sin.
“A ti fi to awọn akọsẹmọsẹ leti lori bi iwadi lori ayẹwo naa yo ṣe waye, ti a ko si fi iroyin mii lede nitori ọmọ kekere ni oloogbe naa, ti a si gbọdọ bọwọ fun oun ati mọlẹbi rẹ.
“A ba mọlẹbi Adeniran kẹdun, ibanujẹ nla lo jẹ fun wa, ti a si gba ladura pe Ọlọrun duro ti wọn lasiko ti wọn wa yii.”
Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ọmọ mi tó fò ṣàńlẹ̀ kú ní iléẹ̀kọ́ Chrisland? – Iya Whitney Adeniran

Oríṣun àwòrán, Others
Arabinrin Blessing Adeniran ti sọ bi ọmọ rẹ, Adesola Adeniran sẹ di oloogbe ni asiko ere idaraya ojule-si-ojule, inter-house sport ti ileẹkọ Chrisland College.
Arabinrin Blessing naa kegbajare lori ẹrọ ayelujara nibi to ti sọ iriri rẹ ni Ọjọ Kẹsan an, Oṣu Keji, ọdun 2023.
Abilekọ Blessing ni oun ti ṣeleri fun ọmọ oun pe oun yoo wa nibẹ lasiko ti wọn ba n ṣe ayẹyẹ ere idaraya ti ọdun yii nitori oun ko si nibẹ ni ọdun to kọja.
‘’Ki wọn to bẹrẹ ere idaraya ni mo ti wa nibẹ, ti mo si ki awọn olukọ ọmọ mi to fi mọ olukọ agba ati awọn obi to wa nibẹ.
Lẹyin naa ni wọn bẹrẹ yiyan bi ologun ‘’March past’’ ti mo si bẹrẹ si ni fi oju wa ọmọ mi amọ mi o ri’’.
Gbogbo awọn eniyan yan kọja, to fi mọ Pine(Green) House to sọ fun mi pe oun wa amọ mi o ri i.
Aya mi bẹrẹ si ni ja ni mo ba lọ si ibi ti wọn ti n ra ipapanu , ti wọn si sọ fun mi pe Winifred kan subu lulẹ nibi yii, ti wọn si rọ omi le lori.
Lẹyin ọpọ igbiyanju arabinrin naa ni oun tẹ ọkọ leti lọ si ileewosan ti wọn sọ fun oun pe ọmọ ọhun wa.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 3
‘’Oku ọmọ ni mo ba ti ahọn ati ete rẹ ti dudu’’
Arabinrin Blessing ni kete ti oun de ileewosan naa ni oun bere ibi ti ọmọ oun wa, ti wọn si juwe ibẹ.
‘’Oku ọmọ mi ni mo ba ti oun sun omi lati ori de eekanna ẹṣẹ’’.
Ibanujẹ mi nipe awọn ileẹkọ Chrisland ko ṣeto iwosan pajawiri kankan silẹ fun awọn akẹkọọ to le ni ẹẹdẹgbẹta ti wọn n ṣere idaraya.’’
‘’Mo mi ọmọ mi titi ko dide, mo kigbe, mo faraya, ọmọ mi ko mi mọ’’
‘’Mo bere lọwọ dokita pe ki lo ṣe ọmọ mi, dokita naa ni boya aisan ọkan, amọ ọmọ mi ko ni aisan kankan.’’
‘’Awọn dokita nibẹ ni wọn gbe ọmọ naa wa si ileewosan pe o si ti ku.’’
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 4
Ibeere mi ni pe ki ileẹkọ Chrisland ṣalaye fun mi ki lo pa ọmọ mi Whitney Adeniran?
Iya Whitney Adeniran ni ọmọ oun ko ṣe aisan tẹlẹ, pe ki lo ṣe ọmọ oun.
O ni ibeere ti oun fẹ ki awọn olukọ ileẹkọ naa da wọn lohun pe ki lo ṣẹlẹ.
‘’Kilo ṣẹlẹ si ọmọ mi,ki lo ṣẹlẹ si Whitney Adeniran? Wọn o gbe ọmọ mi lọ si ileewosan, immunisation centre ni wọn gbe ọmọ mi lọ.’’
Arabinrin naa wa kesi ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, awọn alẹnulọrọ ni ilu ati lori ẹrọ ayelujara ki wọn wa dasi ọrọ yii
O ni awọn obi ti n pe oun pe ileẹkọ naa ni ọmọ naa n ṣe aisan amọ o ni kosi nkankan to ṣe ọmọ oun.
Iya ọhun ni oun ko ni dakẹ titi ti oun yoo fi mọ otitọ nipa isẹlẹ naa.
Arabinrin naa wa kesi awọn obi, ọmọ ileẹkọ lati gbogbo awọn eniyan to wa nibẹ nigba ti iṣẹlẹ naa waye lati wa sọ fun wọn ohun to ṣẹlẹ
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 5












