Àwọn Wòlìí kan ń sọtẹ́lẹ̀ torí àwọn tó ti fún wọn lówó ni, a ní láti tọrọ ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ Ọlọ́run – Oyedepo

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Gẹgẹ bi eto idibo orilẹede Naijiria ṣe ti n sunmọ, ọrọ ti jade pe ayafi ki awọn ọmọ Naijiria tọrọ fun aanu ati idariji ẹsẹ tori ikilọ waye ṣaaju nipa ohun ti wọn n la kọja lọwọlọwọ amọ wọn kọ eti ikun.
Biṣọọpu David Oyedepo to jẹ oludari ijọ Living Faith lagbaye lo sọ eyi ninu iwaasu owurọ kutu to ṣe ni ọjọ Aiku ọjọ Kejila ọdun 2023.
Isin naa waye ni gbọngan ijọ Living Faith to wa ni ilu Ota nipinlẹ Ogun.
Oyedepo ni “Mo pariwo ti ti ti lọdun 2015, ẹ o gbọ ..., Ilẹ Naijiria ti bajẹ, a ni lati gbadura, a ni lati tọrọ fun aanu Ọlọrun.”
Oyedepo ni nnkan ti awọn Pasitọ ati Wolii ijọ da silẹ bayii ni awọn wa ninu rẹ ni Naijiria.
O mẹnu ba ọrọ awọn Pasitọ mii to ti n sọ oriṣiriṣi iran nipa eto idibo to n bọ lorilẹede Naijiria.
“Wọn o riran to tọ mọ, afi ki Ọlọrun ṣaanu.”
O tẹsiwaju pe “oo ni lati kede pe Wolii ni ọ, ibaṣepọ rẹ pẹlu Ọlọrun ni yoo jẹ ko maa fi ohun ti o ba fẹ ṣe han ọ.”
Sibẹ, ọpọ ti jẹ iya jina fun isọkusọ ti wọn ti sọ si awọn wolii.
“Awọn Wolii kii ṣe aworawọ, ọkan ọlọrun ni wọn maa n gbe jade.”
O ni ohun ti awọn Pasitọ ijọ ti da silẹ ninu iṣoro ti Naijiria wa ninu rẹ lọwọ lọwọ, Ọlọrun nikan lo mọ.
“Ọpọ wọn, Wolii fun awọn oloṣelu ni wọn, wọn o ki n ṣe Wolii Ọlọrun.
“A o ni aṣẹ lati maa paṣẹ lai yi ibinu Ọlọrun kuro.”
"Ọdun 2015 ni mo ti mọ pe ogun ara ẹni ni Naijiria fẹ lọ doju kọ yii"

Oríṣun àwòrán, Bishop David Oyedepo
Biṣọọbu Oyedepo ni oun wo awọn fidio ori amohunmaworan ti oun si ri bi awọneeyan ṣe wa ninu inira to pọ ni Naijiria.
O tẹnumọ bo ṣe sọ ọ ni gbangba lọdun 2015 pe oun kilọ fun awọn ọmọ Naijiria nipa iru adari ti wọn ba yan ati atubọtan rẹ.
“A o ke pe ibinu Ọlọrun lati gbẹsan ẹjẹ awọn alaiṣẹ ti wọn ti ta silẹ lorilẹede Naijiria.”
Ibeere Oyedepo nipa Naijiria
* Oyedepo kọ Episteli si awọn ọmọ ijọ rẹ pẹlu awọn ibeere to fi ni o yẹ ki wọn gbadura fun Naijiria.
* “Eeyan melo lo fẹ rii ki abo to daju lori aye ati dukia awọn eeyan pada bọ sipo ni Najiria?
* Eeyan melo lo fẹ ri orilẹede ti awọn obi yoo le ran ọmọ wọn lọ ile ẹkọ lai foya, ijinigbe tabi iku buruku?
* Ilu ti rinrin irinajo lati ibi kan lọ sibomii ko ni mu ibẹru lọwọ, ilu ti a o ti ri awọn adari to yẹ ni gbogbo ipele?
* Ta lo fẹ ri ilu ti irẹpọ wa ti gbogbo ẹya, ede ati ẹsin yoo maa gbe pọ lalafia?
Biṣọọbu Oyedepo ni “Ọlọrun ba mi sọrọ, a o le la oju silẹ ki idarudapọ mii tun ṣẹlẹ ni Naijiria.
Bẹẹ si ni ọlọrun ko ni ṣe nkankan ayafi bi a ba dide gbadura”.
Torinaa lo ṣe kede akanse eto adura ati awẹ ọlọjọ mẹta fun aanu lori orilẹede Naijiria ati idibo to n bọ lọna.
O fi kun un wipe ọlọrun ni a kan n paṣẹ, wọn n gbadura, lai tọrọ fun idariji ẹṣẹ Naijiria ati ti ijọ paapaa.
“Ọpọlọpọ lo ti gba ọjẹgẹ, awọn eeyan n gbe owo kaakiri latara owo jiji, awọn adari ijọ, wọn n sọtẹlẹ lati ba ifẹ awọn to n fun wọn lowo mu”.
A ni lati ronupiwada lati yi ibinu Ọlọrun kuro lori Naijiria.
Lori ọrọ owo Naira, Oyedepo ni ko le jẹ oju lasan ni ki awọn eeyan maa wa owo kiri bayi lati le ri lo ti wọn tun n jo banki kaakiri.
O ni gbogbo nnkan to n ṣẹlẹ ni Naijiria yii kii ṣe ọrọ ana, “gbogbo awọn oloṣelu to n pariwo kiri yii, nibo ni wọn wa nigba yẹn?”
“A o le maa rẹrin, a ni lati dide gbadura”.















