Ta ló fá irun ọmọ ọdún méjì nípàkọ́, sín ní gbẹ́rẹ́ nílé ẹ̀kọ́ kan n‘Ibadan?

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ní ọjọ́ mélòó kan sẹ́yìn ni ìyá kan fi gbe ta lórí ayélujára láti ké gbàjarè lórí ohun kàyéfì kan tó rí nípa ọmọ rẹ̀.
Ohun tí ìyá ọmọ náà sọ ni pé òun gbé ọmọ òun, tó jẹ́ ọmọ ọdún méjì lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Sunshine School ní agbègbè Ire-Akari ní ìlú Ibadan, láìsí nǹkankan tó ṣe ọmọ náà nígbà tí òun gbe débẹ̀.
Ó ṣàlàyé pé bí òun ṣe gbé ọmọ náà kalẹ̀ ni òun gba ilé ìjọsìn lọ, tí òun sì padà láti lọ gbé ọmọ náà ní nǹkan bíi aago márùn-ún ku ogún ìṣẹ́jú.
Ó ní bí òun ṣe gba ọmọ náà padà ni òun ṣàkíyèsí pé wọ́n ti fa irun ọmọ òun ní ìpàkọ́, tí nǹkan tó jọ bíi gbẹ́rẹ́ méjì sì wà níbi ìpàkọ́ rẹ̀ ọ̀hún.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
"Mo béèrè fún àyẹ̀wò CCTV tó wà nílé ẹ̀kọ́ náà àmọ́ wọ́n ní kò ṣiṣẹ́ lọ́jọ́ náà"
Ìyá ọmọ náà tó ń rawọ́ rasẹ̀ sí gbogbo ọmọ Nàìjíríà láti gba òun sílẹ̀, ní òun bèèrè fún ẹ̀rọ àyàwòrán CCTV ilé ẹ̀kọ́ Sunshine náà láti lè mọ̀ ẹni tó ṣiṣẹ́ náà ṣùgbọ́n wọ́n ní CCTV àwọn kò ṣiṣẹ́ lọ́jọ́ náà.
Ó ní CCTV ọ̀hún ń ṣiṣẹ́ ní gbogbo ọjọ́ mìíràn àmọ́ ọjọ́ tí wọ́n fá irun ọmọ òun nìkan ni kò sí nínú CCTV nígbà tí àwọn jọ ṣe àyẹ̀wò rẹ̀ papọ̀.
Bákan náà ló tún fẹ̀sùn kan pé ilé ẹ̀kọ́ náà ń fi ọwọ́ bo ọ̀rọ̀ náà mọ́lẹ̀ tí wọn kò sì ṣe ohunkóhun láti fojú ẹni tó ṣe iṣẹ́ náà hàn.
Láti ìgbà náà ni orí ayelujára ti ń gbóná, tí ọ̀pọ̀lopọ̀ ènìyàn sì ń sọ pé kí ìyá ọmọ náà bá ilé ẹ̀kọ́ náà wọ ìyá ìjàkadì.

Oríṣun àwòrán, Instagram
A ti gbe ikọ iwadi alagbara kalẹ lati sawari ẹni to sisẹ ibi naa – Ile ẹkọ Sunshine
Wayi o, awọn alasẹ ile ẹkọ Sunshine Schools, Ibadan nibi ti isẹlẹ yii ti waye ti fesi lori isẹlẹ to sẹlẹ nipa ọmọ naa eyi to gba ori ayelujara naa.
Atẹjade kan ti ile ẹkọ naa fisita fawọn akọroyin salaye pe ailakakun olukọ kan lo se okunfa bi wn se ge irun ọmọde naa.
Atẹjade naa fikun pe ile ẹkọ naa ti gunle aayan lati ri daju pe oun fi oju asebi nidi isẹlẹ naa han, ko si koju idajọ to ba yẹ.
Ile ẹkọ naa wa fi ọwọ idaniloju sọya pe oun ti se agbekalẹ ikọ oluwadi alagbara kan lori isẹlẹ naa, ti oun yoo si kede abọ iwadii naa fun araye laipẹ.
“Epo bẹntirolu to wọn lo mu ka pa ẹrọ amunawa lọsan ọjọ ti isẹlẹ yii waye”
Bakan naa ni ile ẹkọ Sunshine kede pe yatọ si iroyin eke to n lọ kaakiri ori ayelujara, kii se pe oun mọọmọ fi ẹrọ ayaworan CCTV to wa nile ẹkọ naa pamọ ni.
Amọ o ni ọwọn gogo epo bẹntirolu to n waye lọwọ lorilẹede yii lo mu ki wọn pa ẹrọ gẹnẹretọ amunawa tile ẹkọ naa n lo lọsan ọjọ naa.
O ni idi ree ti ẹrọ ayaworan CCTV ko fi sisẹ lasiko naa lati ka gbogbo ohun to n waye
Ile ẹkọ Sunshine wa mu da awọn obi , akẹkọọ ati gbogbo awujọ loju pe isẹlẹ naa ko dara rara, ti iru rẹ ko si waye ri nibẹ.
Bakan naa lo ni ọga agba ile ẹkọ naa ko mọ ohunkohun nipa isẹlẹ naa.
A ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ẹ̀sùn náà - Ọlọ́pàá Oyo
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oyo ti sọ̀rọ̀ sókè lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, tó sì kéde pé àwọn ti gbọ́ sí ọ̀rọ̀ ọmọ ọdún méjì tí wọ́n fá irun rẹ̀ nílé ẹ̀kọ́ kan ní agbègbè Ire-Akari ní ìlú Ibadan.
Àtẹ̀jáde kan tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Oyo fi sórí Twitter rẹ̀ ṣàlàyé pé ẹ̀ka tó ń mójútó ìwà ọ̀daràn ti wà lórí ẹ̀sùn náà.
Ó ní kété tí àwọn bá ti ní ohunkóhun láti sọ lórí ọ̀rọ̀ náà ni àwọn yóó fi léde.
Bákan náà ni wọ́n sọ àrídájú rẹ̀ pé àwọn yóò rí dájú pé ìyá ọmọ náà rí ìdájọ́ òdodo gbà.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2















