Ìpínyà lé dé bá Nàìjíríà tí Peter Obi bá pàdánù ìbò Ààrẹ – Adebanjo

Oríṣun àwòrán, Collage
Adari kan ninu ẹgbẹ Afenifere, Oloye Ayo Adebanjo ti ni orilẹede Naijiria le e ma si mọ, ti ipinya yoo si de ba a, ti oludije sipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi, ko ba bori ninu idibo aarẹ to n bọ.
Adebanjo sọ eleyii nibi ipade to ṣe pẹlu awọn agbaagba lati guusu ati aarin gbogbo orilẹede Naijiria to waye niluu Abuja.
O ni yoo nira fun ẹnikẹni lati ẹkun ariwa Naijiria lati ṣejọba lori Naijiria, ti Obi ba padanu ipo aarẹ ninu idibo to n bọ.
Amọ ọpọlọpọ awọn eniyan lo ti n tako iwoye Adebanjo yii paapaa awọn agbaagba nilẹ Yoruba.
Adebanjo ni didi ibo fun Obi lo le fihan pe Naijiria nifẹ lati ko gbogbo ẹya ati ẹsin papọ ni.
"Gbogbo ọna ni wọn saa lati ri pe agbara ko kuro lọwọ wọn, idi niyẹn ti wọn ko fi tẹle oludije ẹgbẹ oṣelu wọn"
Adebanjo tẹsiwaju pe “A n rọ awọn ọmọ Naijria ati awọn ololufẹ Peter Obi lati ma ṣe jẹ ko rẹ wọn ninu igbinyanju wọn nitori awọn alatako wọn ko duro rara."
“Gbogbo ọna ni wọn saa lati ri pe agbara ko kuro lọwọ wọn, idi niyẹn ti wọn ko fi tẹle oludije ẹgbẹ oṣelu wọn.
“Gbogbo nnkan to gba ni a ma fun. Ti Obi ko ba wọle, ẹ gbagbe pe orilẹede kan n jẹ Naijiria.
“Ti a ba ri ijakulẹ ninu eto idibo yii, ko ni si anfani fun ẹni ti ko ki n ṣe Kristẹni tabi ki ko wa lati ariwa lati di aarẹ orilẹede Naijiria.”
Kò sí ìdánilójú pé Peter Obi lé gbọ́ òórùn ipò Ààrẹ - Olawale Oshun
Ọkan lara agbagba ilẹ Yoruba, Olawale Oshun ti tako ọrọ ti Ayo Adebanjo ṣọ lori isọkan Naijiria lẹyin idibo aarẹ.
Oshun, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni ko si idaniloju pe oludije ti Baba nifẹ si yoo gborun ipo naa, gẹgẹ bi aarẹ orilẹede Naijria.
Oshun ni kii se Adebanjo nikan ni yoo dibo aarẹ ninu oṣu yii ati pe awọn kan ninu awọn oludije naa yoo ri ijakulẹ, ti wọn ko si ni fi imu gboorun ipo naa.
O tẹsiwaju pe ko ni si rogbodiyan kankan ti yoo waye lẹyin ibo nitori awọn ajọ eleto idibo ti fi to awọn ọmọ Naijiria leti pe ko ni si aburu kankan lẹyin idibo.
"Ẹni ti ko ba wọle loni, le wọle lọla, kii ṣe dandan ki rogbodiyan bẹ silẹ tabi pe aarẹ gbọdọ wa lati ibi kan"
Oshun ni “Bi a ṣe n wo gbogbo awọn to jade fun ipo aarẹ, ko si idaniloju pe oludije aarẹ ti Adebanjo n pọn lẹyin rẹ, yoo gboorun ipo naa tabi oun ni yoo di aarẹ.
“A fi ti wọn ba sọ pe o jẹ oun ko jẹ oun, a fẹ da orilẹede Naijiria ru, ti ko ba ti si iyẹn, ki gbogbo wa lọ ṣe eto idibo, o ti di dandan pe ki eeyan kan wọle gẹgẹ bi aarẹ.
“Ti a ba ti n dije, dandan ni pe ki ẹnikan wọle. Ko le si rogbodiyan kankan lẹyin eto idibo .
Awọn ọmọ Naijiria nikan lo lanfani lati yan ẹni to wu wọn gẹgẹ bi aarẹ.
“Ẹni ti ko ba wọle loni, le wọle lọla, ko ki n ṣe dandan ki rogbodiyan bẹ silẹ tabi aarẹ gbọdọ wa lati ibi kan."
















