Èèyàn mẹ́ta yé nínú ilé 15 tó dàwó lásìkò ilẹ̀ rìrì ní Turkey

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Odidi agbegbe kan ti dawati labẹ ilẹ ni Turkey
Lori awoku ile ni apa gusu Turkey, a ri fireemu ferese pẹlu asọ alawọ labalaba ti afẹfẹ tutu ngbe.
"O jẹ yara Ceyda."
Ṣaaju iṣẹlẹ ilẹ riri, Ceyda Ocan, ọmọ ọdun mọkandinlogun [19], wo oju ferese yẹn ati aṣọ tí a ta si, lati wo opopona rẹ nilu Iskenderun.
Bayi Ọrẹ minu rẹ, Damla, wa ni opopona pẹlu awọn ẹbi rẹ lati ṣẹ aisun nibi ile Ceyda ti o dawo.
Ireti rẹ ni pe Ceyda o ye, bi awọn oṣiṣẹ adola ẹmi ati awọn aja ti n kẹfin awọn to n wa labẹ awọn ile to dawo.
Damla ati Ceyda pade ni adugbo nigbati o jẹ ọmọ ọdun mẹfa ti Ceyda jẹ ọmọ ọdun mẹjọ,ti wọn si di ọrẹ latigba na, Wọn ra awọn aṣọ-ikele alawọ labalaba papọ nigba ti wọn ririn-ajo papọ laipẹ.
"Awa mejeji fẹran labalaba," Damla, fi aworan ẹbun ti Ceyda fun lọjọ ibi rẹ han lori fonu rẹ. o jẹ aworan akara oyinbo ọjọ-ibi ti Ceyda ṣeto fun Damla pẹlu aburo rẹ, ti wọn ṣe lọṣọ pẹlu awọran labalaba.
Ile Ceyda,ni wọn pe ni Orcan wa ni arin gbungbun Iskenderu ti o si ni awọn ile itaja labẹ rẹ’
Nigba ti isẹlẹ ilẹ riri akọkọ sẹlẹ ni bi ago 04:17 arọ ọjọ ajẹ Ceyda yoo ti sunpẹlu awọn olugbe Orcan miiran.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Gbogbo ile wọn lo ri ninu isẹlẹ naa.
Ọpọlọpọ ile ni gusu Turkey lo ti dawo patapata,ni Orcan idile marundinlogun lo n gbe be,ṣajuu iṣẹlẹ ilẹ riri ọpọ olugbe Orcan lo ni ireti igbe aye tuntun ti wọn si ma n sọrọ nipa awọn ololufẹ wọn.
A jẹri akoko idunnu kukuru kan ni Ọjọru nigbati a ti fa ẹnikan jade ninu ile to dawo lẹyin ọjọ kan ti a n sawari awọn to wa labẹ ilẹ riri Orcan,ọkan lara awọn alabagbe Ceyda.
A pada si Orcan fun ọjọ mẹta gbako lati wo akitiyan awọn adola ẹmi,awọn to n lo si ibomiranati awọn ile iwosan ti a ṣeto lati tọju awọn to farapa.
Awon to dola ẹmi ni Orcan ni awọn mẹta nikan lakọsilẹ rẹ wa pe wọn ye.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ní àgbàyé fẹ́ gba ọmọ tuntun tó há sábẹ́ àwókù ilé tọ́

Oríṣun àwòrán, Getty Image
"Baba, iya ati awọn ẹgbọn mẹrẹẹrin to saaju ọmọ tuntun naa lo padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ ilẹ riri"
Ogunlọgọ eeyan lo ti fifẹ han lati gba itọju ọmọ oojọ ti wọn fa yọ ninu ọkan lara awọn ile to da wo ninu iṣẹlẹ ilẹ riri Syria.
Nigba ti wọn n gbe e jade ninu ile to dawo naa, ọmọ naa ni wọn sọ ni Aya, eyi to tumọ si ‘isẹ Iyanu’ lede Arabic.
Aya ni wọn ri pẹlu olubi ọmọ nikun rẹ, eyi to so o pọ mọ iya rẹ, bo tilẹ jẹ wi pe oun nikan lo ye ninu isẹlẹ naa.
Baba rẹ, iya ati awọn ẹgbon rẹ mẹrẹẹrin lo padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ naa.
Aworan ọkurin kan to gbe Aya lọwọ, lẹyin igba ti wọn yọ ninu ile kan lagbegbe Jindayris, lo gba ori ẹrọ ayelujara kan.
Khalil al-Suwadi, to jẹ ibatan rẹ to gbe lẹyin ti wọn fa a yọ ninu iṣẹlẹ ilẹ riri, lo gbe lọ fun Dokita Hani Marouf ,ni ilu Afrin lorilẹede Syria.
Hani Marouf ni igba ti wọn kọkọ gbe Aya de, gbogbo ara rẹ kun fun ọgbẹ, otutu si ti rọ si laya ṣugbọn lẹyin itọju, ara rẹ ti bọ pada sipo.

Oríṣun àwòrán, Getty Image
"Iyawo mi lo n fun Aya lọyan pẹlu ọmọ tiwa to n tọ lọwọ àmọ gbogbo agbaye lawọn eeyan ti n fifẹ han lati gba ọmọ naa tọ"
Ọpọ eeyan lo ti fifẹ han lori ẹrọ ayelujara lati gba itọju ọmọ naa, ninu wọn ni Onsọrọ ori tẹlifisan Kuwaiti kan.
Alakoso ile iwosan naa, Khalid Attiah ni ọpọ ipe ni oun ti gba lati ọwọ ọpọlọpọ eeyan jake jado agbaye, ti wọn fifẹ han lati gba itọju Aya.
Dọkita Attiah, ẹni ti iyawo rẹ naa ni ọmọbinrin, ọmọ oṣu mẹrin lọwọ ni iyawo oun lo n fun Aya yan rẹ pẹlu ọmọbinrin tawọn to n tọ lọwọ.
Attiah ni titi awọn mọlẹbi Aya yoo fi de, awọn ko ni yọnda ọmọ naa fun ẹnikeni.
Ni ilu Jindayris, ida aadọrun awọn ile lo ba iṣẹlẹ ilẹ riri lọ, ti isẹ idoola ẹmi ṣi n tẹsiwaju.
Mohammed al-Adnan sọ fun BBC wi pe ọpọ eeyan lo si wa labẹ awọn awoku ile naa.
Ẹgbẹ white Helmets, to ti n ṣe iranlọwọ fun awọn to wa labẹ ile nibi iṣẹlẹ ile riri naa, ti wa kede pese ni ẹru n ba awọn, ki ile ma wotan le awọn lori.
O le ni ẹgbẹrun mẹta eeyan to ti padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ ilẹ riri ni Syria papajulọ awọn agbegbe to jẹ ti ijọba.
Ko si tii si akọsilẹ pato nipa iye awọn to padanu ẹmi wọn ni agbegbe to wa labẹ awọn alakatakiti ẹsin lorilẹede Syria.

Oríṣun àwòrán, Getty Images












