Ọjọ́ méjìlá lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ ìlẹ̀ rìrì Turkey, bí wọ́n ṣe rí òkú àgbàbọọlu Ghana Christian Atsu

Oríṣun àwòrán, ChristianAtsu/Facebook
Agbabọọlu ọmọ orilẹede Ghana, Christian Atsu ni wọn ti kede pe o ti padanu ẹmi rẹ ninu isẹlẹ ile riri to waye ni Turkey.
Wọn ri oku Christian Atsu yọ ninu palapala ile rẹ to dawo lẹyin bi ọsẹ meji ti iṣẹlẹ ilẹ riri waye ni Turkey.
Agbenusọ fun Christian, Nana Sechere lo fi iroyin naa lẹde.
Atsu ọmọ ọkanlelọgbon ọdun lo ti fi igba kan ri gba bọọlu fun ẹgbẹ agbabọlu Everton, Chealsea ati Newcastle.
Lati ọjọ kẹfa oṣu keji ọdun yi ni Atsu ti di awati lẹyin iṣẹlẹ ilẹ riri nibi ti ile rẹ ti dawo ni agbegebe Antakya, Hatay.
Ikọ agbabọọlu rẹ Hatayspor ninu ọrọ idaro wọn ni ”ẹnu ko le ṣakawe bi inu wa ṣe bajẹ si, ao ni gbagbe rẹ Atsu, ki alafia o ba o”.
Agbẹnusọ rẹ Nana Sechere to ti wa ni Hatay lo fi iroyin naa lede lori ẹrọ ayelujara Twitter rẹ lẹyin ti wọn gbe oku Christian Atsu jade.
Nana dupe lọwọ gbogbo awọn to ti n gba adura fun Atsu.
Gbogbo awọn ẹgbe agbabọọlu ti Atsu gba bọọlu fun lo ti daro iku rẹ.
Iṣẹlẹ ilẹ riri naa gba ẹmi eeyan to le ni ọkẹ meji.
A wá gbogbo inú yàrá Christian Atsu, ẹsẹ̀ bàtà méjì la rí, a kò fojú gáání Christian rárá - Agbẹnusọ

Oríṣun àwòrán, christianAtsu/facebook
Awọn agbẹnusọ agbabọọlu ọmọ orilẹ-ede Ghana nni, Christian Atsu ni awọn ṣi n wa a lẹyin ọjọ mẹwa ti iṣẹlẹ ilẹ riri Turkey waye.
Agbenusọ rẹ Nana Sechere ni awọn ti o n doola ẹmi ti wọ yara Atsu ti wọn si ri bata ẹsẹ rẹ meji nibẹ ṣugbọn Christian Atsu ko si ninu yara naa.
Nana Sechere ni aworan ile na fihan pe eeyan marun ṣi wa labẹ ile to dawo ti wọn gbiyanju lati doola ẹmi wọn.
Agbenusọ rẹ ni oun wa nibi ile ti Atsu ngbe ṣaaju iṣẹlẹ ilẹ riri na, ó kabamọ aisi irinṣe idoola ẹmi to lati tete yọ awọn to wa ninu palapala awoku ile.
O ni aisi awọn to le ṣe oungbifo fún awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi ṣe akude fun iṣẹ idoola ẹmi
Ẹgbẹ agbabọọlu rẹ Hatayspor ti ṣaaju sọ wi pe awọn ti ri Atsu yọ ninu palapala ile to dawo kí wọn to pahunda lẹyin wakati diẹ pe awọn ko tii ri i.
O le ni ọkẹ meji eeyan to ti gbẹmi mi ninu iṣẹlẹ na.
Ṣaaju, aarẹ orilẹ-ede Ghana Nana Akufo Addo ninu iwe ikẹdun rẹ,rọ awọn ọmọ orilẹ-ede Ghana lati gbadura fun awọn ti iṣẹlẹ ilẹ riri ṣakoba fun papajulọ Christian Atsu ọmọ orilẹ-ede Ghana.
Bí wọ́n ṣe dóòlà ẹ̀mí ẹ̀gbọ́n àti àbúrò obìnrin nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ ríri Turkey rèé...

‘’Marvel. Irem, Mervel! Irem nibo lẹ wa? ṣe ẹ le gbọ mi?. ‘’
Bayii ni awọn oṣiṣẹ pajawiri ṣe n kigbe lohun rara, ti gbogbo awọn oluworan si pa lọlọ lati gbọ ohun awọn ẹgbọn ati aburo to ha naa.
Awọn ẹgbọn ati aburo obinrin yii lo ha lasiko iṣẹlẹ ilẹ riri ni gbegbe Antakya, ti ile wọn alaja marun un si wo palẹ.
Pẹlu ohun elo igbalode ti yoo sọ ti ẹnikẹni ba wa nibẹ ni wọn fi n tẹti lejo, ti gbogbo ibẹ si palọlọ.
Laipẹ ni ọkan lara awọn adoola ẹmi naa, Mustapha n pariwo orukọ ọkan lara awọn ọmọ iya naa, Irem mi ọwọn, mo wa pẹlu rẹ, njẹ o le gbọ mi?
Bio tilẹ jẹpe awa onworan ko le gbọ ọrọ awọn ọmọbinrin mejeeji naa, amọ o ti han gbangba pe awọn mejeeji n da awọn adoola ẹmi lohun.
‘’O kare lai, oya ẹ fi ara balẹ ki ẹ si dami lohun, o daa bẹẹ Merve. Oya Merve, oya da mi lohun.’’

Arabinrin Merve jẹ ẹni ọdun mẹrinlelogun, ti aburo rẹ obinrin si jẹ ẹni ọdun mọkandinlogun, ti wọn si ti wa ni abẹ fun ọjọ meji amọ niiṣe lo dabi ọjọ mẹrinla.
‘’Rara kii ṣe ọjọ mẹrinla ni ẹ ti ha sibẹ, ọjọ meji ṣẹyin ni, ọya fun ni iṣẹju marun un, a o yọ yin jade.
Amọ Mustafa mọ pe yoo to wakati melo kan ki wọn to doola ẹmi wọn,amọ ko fẹ ki wọn ronu.
‘’Ti wọn ko ba ni ireti, o ṣeeṣe ki wọn ma le yee.’’
Lẹyin naa ni arabinrin Merve ati Irem bẹrẹ si ni tage ti wọn si n rẹrin.
Ninu ọrọ rẹ, Mustapha ni kani wọn ri aaye awọn mejeeji yoo maa jo.
Lẹyin naa ni wọn bẹrẹ si ni gbe awọn okuta naa kuro, ti wọn si bẹrẹ si ni tọ ipaṣẹ lati le de ọdọ wọn.
‘’Ẹrọ camera lo ṣafihan ibi ti wọn wa, ti wọn si tọpaṣẹ ina naa jade’’

Lẹyin ọpọlọpọ wakati, ni ilẹ tun bẹrẹ si ni mi, ti wọn si kuro nibẹ amọ ti wọn pada sibẹ lẹyin ọgbọn iṣeju, ti awọn aburo naa ti ro wipe wọn ti fi wọn silẹ lati ku.
Amọ wọn pada si ọdọ wọn, ti wọn fi da wọn loju pe ko si ewu fun wọn, ti awọn si wa pẹlu wọn.
Lẹyin naa ni wọn wa ọna de ibi ti wọn ti wọn si ran ẹrọ kamẹra si wọn, ti inu awọn oluworan si dun lẹyin ti wọn dahun pe awọn ri ọna.
‘’O rẹwa lobinrin, ma yi ara rẹ popọ, fi ero naa si apa ibi ti a ti le ri ikeji rẹ.’’
Lẹyin bii wakati mẹwaa ni awọn mejeeji jade ti ariwo si sọ, ti ọkan lara wọn si n bere pe ṣe aye ni awọn ṣi wa.
Se lootọ aye ni mo ṣi wa? mi o tii ku?

Awọn mejeeji naa ni wọn jajabọ, amọ iya wọn ku ninu iṣẹlẹ naa, ti wọn si wa pẹlu rẹ nibẹ fun ọjọ mejeeji ọhun.
Wọn ni awọn ko lee mi daadaa nitori ara iya wọn ti bẹrẹ si ni jẹra, ti oorun rẹ ko si jẹ ki awọn mi daradara.
Awọn mejeeji awọn ko lero pe asiko kan yoo wa ni aye awọn ti awọn ko ni fẹ duro si ibi ti iya wọn wa.
‘’ Se lootọ aye ni mo ṣi wa? mi o tii ku?’’
Hmmn, lẹyin ti wọn doola ẹmi awọn mejeeji tan ni awọn ẹṣọ alaabo ke kera pe ki ẹnikẹni to ba ha to si wa laaye ki wọn fi ami han, amọ ko si ohun kankan.
Lẹyin naa ni wọn kọ akọsilẹ wi pe awọn ko ni lee wo ile alaja marun un to wo palẹ naa mọ, ti wọn si kọja lọ si ibomiran.
Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́rin, wọ́n rí ọmọ tuntun jòjòló àtí ìyá rẹ̀ tó há nínú ilẹ̀ ríri Turkey

Oríṣun àwòrán, Twitter
Awọn ẹṣọ alaabo ti doola ẹmi ọmọ tuntun jojolo ati iya rẹ lẹyin ti wọn ha lasiko iṣẹlẹ ilẹ riri to waye ni Turkey.
Ọmọ tuntun jojolo naa ati iya rẹ ti ha fun odidi aadọrun wakati ki wọn to ṣẹṣẹ ri wọn yọ ni agbegbe Hatay.
Awọn fọtọ ṣafihan ọmọ ọjọ mẹwaa naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Yagiz ni wọn gbejade ninu ibi to ha si.
Awọn ẹṣọ alaabo ati awọn oniroyin sẹ apejuwe idoola ẹmi naa gẹgẹ bi iṣẹlẹ iyanu.
Igbiyanju lati doola ẹmi awọn eniyan n dinku nitori oju ọjọ to tutu bii yinyin lẹyin ọjọ mẹrin ti iṣẹlẹ naa waye.
Amọ awọn ẹṣọ alaabo ṣi n tiraka lati doola ẹmi awọn eniyan ni orilẹede Turkey ati agbegbe Syria to faragba ninu iṣẹlẹ naa.
Ọmọtuntun jojolo naa ni wọn gbe sinu aṣọ thermal Blanket ti yoo da abo bo ọmọ naa ninu otutu.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Lẹyin naa ni wọn gbe wọn lọ si ileewosan lati lọ gba itọju.
Iya ikọkọ naa ni wọn gbe jade lori stretcher amọ ko si iroyin mọ nipa awọn mejeeji.
Awọn ileeṣẹ pajawiri to doola ẹmi ọmọ naa lati iya rẹ ni ilu Samandag ni iṣẹlẹ naa ti waye.
Aworan miran ṣafihan ọkunrin miran ti wọn tun gbe jade ninu ile naa, amọ wọn ko lee sọ boya mọlẹni ni wọn.
O kere tan ẹniyan ẹgbẹrun lọna mọkanlelogun lo ti ba iṣẹlẹ naa lọ, ti ọpọ si jẹ ara ilẹ Turkey.
Ohun to fa ọgọọrọ eniyan to ku naa ni pe lẹyin ilẹ riri ti iwọn rẹ kọja ẹṣẹ meje, ni awọn ilẹ miran tun bẹrẹ si ni mi.
Aarẹ ilẹ Turkey, Recap Tayyip Erdogan ṣapejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi ibanujẹ ti wọn ko tii ri iru rẹ rii lati bi ọgọrun ọdun sẹyin.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ń gbarata lórí ipò tí Christian Atsu, agbábọ́ọ̀lù tó há sábẹ́ àwókù ilé wà

Oríṣun àwòrán, christianatsu/facebook
Agbẹnusọ fun agbabọọlu Christian Atsu, ti se ọmọ ilẹ Ghana to wa nibi isẹlẹ ilẹ riri ni Turkey ti sọrọ lori ipo ti ọga rẹ wa.
Agbẹnusọ naa ni oun ko ti ri Christian Atsu lẹyin iroyin kan to jade pe wọn ti ri yọ kuro ninu ile to dawo nibi isẹlẹ ilẹ riri Turkey.
O le ni eeyan ẹgbẹrun mọkanla to ti padanu ẹmi wọn nibi isẹlẹ ilẹ riri to waye ni Turkey ati Syria naa.
Christian Atsu lo n gba bọọlu fun Hatayspor, ti igbakeji aarẹ fun Hatayspor si ti ṣaaju kede wi pe wọn ti doola ẹmi Atsu ninu ọkan lara ile to dawo naa.
Agbẹnusọ Atsu, Nana Sechere ni gbogbo ọna ni oun gba lati ri wi pe wọn ṣawari Atsu.
Alakoso ẹgbẹ agbabọọlu Hatayspor, Volkan Demirel sọ fun ile isẹ akọroyin Turkish Sport wi pe ‘’ Ko ti si iroyin kankan nipa Atsu tabi Oludari Hatayspor Taner Savut, ẹniti wọn ti ri lẹyin isẹlẹ ilẹ riri Turkey.

Oríṣun àwòrán, Christian Atsu/facebook
"Ọpọlọpọ idaru dapọ lo ti wa lori ibiti Atsu wa"
Volkan Demirel sọ siwaju pe ‘’Ti wọn ba wa ni ile iwosan, o di dandan ki n kede rẹ’’.
Aṣoju Ghana ni Turkey Francisca Ashiety-Odunton ni ọpọlọpọ idaru dapọ lo ti wa lori ibiti Atsu wa.
Francisca ni ile isẹ to risi ọrọ ilẹ okere ni Ghana ti ransẹ si oun lori ipo ti Atsu wa, ṣugbọn pẹlu bi idarudapọ ṣe wa, o ṣeṣe ki wọn ti gbe lọ si ile iwosan, ṣugbọn ko si aridaju iroyin nipa ile iwosan ti wọn gbe lọ.
Atsu ọmọ ọdun ọkanlelọgbọn ti gba bọọlu fun ẹgbẹ agbabọọlu Newcastle, Chelsea, Everton ati Bournemouth.
Bakan naa lo ti gba bọọlu fun orilẹede rẹ fun igba marundinlaarin.
Atsu wa darapọ mọ ẹgbẹ agba bọọlu Hatayspor ninu oṣu kẹsan ọdun to lọ lẹyin to lo ọdun kan pẹlu Al-Raed ni Saudi Arabia.















