Wó báwọn gbajúmọ̀ òsèré tíátà ti ṣé àjọyọ̀ ọjọ́ olólùfẹ́

Ọpọ awọn gbajugbaja osere tiata lo bọ sori ayelujara lati ṣe ajọyọ ọjọ ololufẹ pẹlu ọkọ tabi aya wọn lonii, koda, awọn mii fi ifẹ ran si ọmọ wọn.
Ọjọ Kẹrinla, oṣu keji, lọdọun ni Ajọyọ awọn ololufẹ kaakiri agbaye, to si jẹ asiko ti tọkọtaya ati awọn ololufẹ meji maa n fi ifẹ han si ara wọn niyi.
Gbajugbaja oṣere tiata, Muyiwa Ademola pẹlu awọn eeyan miran lọ sori Ayelujara lati kan sara si iyawo rẹ lori ipa to n ko ninu idagbasoke igbeyawo wọn.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
Igbesi aye mi jẹ apẹẹrẹ ifẹ, ireti, iyipada ọtun ati ibẹrẹ igbe aye ọtun - Olori Silekunola Ogunwusi
Naomi Silekunola Ogunwusi, tii se olori tẹlẹ ni aafin Ooni ti ilu Ile Ife naa fi ọrọ ati aworan ransẹ soju opo ayelujara rẹ.
Awọn ọrọ ati aworan yii to fi asọ pupa ya, si lo fi n sami ayajọ ololufẹ tiẹ.
Ninu ọrọ to kọ sabẹ aworan naa, Olori Silekunola ni igbesi aye oun jẹ apẹẹrẹ ifẹ, ireti, iyipada ọtun ati ibẹrẹ igbe aye ọtun.
O ki awọn mọlẹbi rẹ pe wọn ku ajọyọ ayẹyẹ ifẹ naa.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
Mo n jaye ori mi lasiko ayajọ ololufẹ - Mercy Aigbe
O han gbangba pe Mercy Aigbe n jẹ aye ori rẹ, paapa julọ, lasiko ayajọ ololufẹ yii pẹlu ọkọ rẹ, Kazeem Adeoti.
Aigbe bọ sori ayelujara lati kan saara si ọkọ rẹ, to si ni oun nifẹ rẹ pupọ.
Bakan naa, o fi ọpọ aworan ti wọn ya lasiko ti wọn n gbafẹ sita, eyi to fi n sami ayajọ ololufẹ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 3
Ojoojumọ lọjọ ololufẹ nile tiwa, iyawo mi maa n di mi mọra ni - Rotimi Salami
Rotimi Salami naa bọ sori ayelujara lati pọn iyawo rẹ pẹlu awọn ohun to n dun mọni lọkan ti obinrin naa n se.
Salami wa afihan awọn aworan bi irinajo ifẹ wọn ṣe ri lati ọdun 2013 si 2023, eyi tii se ọdun mẹwa gbako.
Salami ni ko iyatọ lori ọna tawọn n gba fi ifẹ han lọdun mẹwa sẹyin ati ni ọdun yii, ojoojumọ si ni ọjọ ololufẹ lọdọ tawọn.
Bakan naa lo sọ pe pẹki pẹki ni iyawo oun maa n sun mọ oun lai ya ara awọn.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 4
Nkechi Blessing Sunday n sami ọjọ ololufẹ pẹlu ọjọ ibi rẹ
Yatọ si pe o jẹ ajọyọ ololufẹ, apapọ ọjọbi lo jẹ Nkechi Blessing, ẹni to n se ajọyọ ọjọ ibi loni.
Ololufẹ rẹ ati awọn akẹgbẹ rẹ lo bọ sori ayelujara lati ki ku ọjọbi rẹ.
Osere tiata naa si lo wọ asọ pupa, to si ko ẹbu lọwọ ninu aworan to fi soju opo ayelujara rẹ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 5
Ọrọ ifẹ naa ko gbẹyin lọdọ gbajugbaja onkorin takasufe, Florence Otedola, ti ọpọ mọ si Dj Cuppy, ẹni to ni ọjọ gbogbo ni ayajọ ololufẹ lọdọ toun pẹlu ololufẹ rẹ. Cuppy bọ sori ayelujara lati safihan awọnb ẹbun to gba lọwọ ọkọ afẹsọna rẹ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 6