Morenikeji Lasisi, 'Baba Kekere' olórí ẹrú Ọba Alaafin Oyo ti jáde láyé

Morenikeji Lasisi, to jẹ olori gbogbo ẹru ni aafin Ọba Oyo to si ti sin Ọba mẹta ti jade laye.
Isẹlẹ naa waye ni alẹ ana niluu Oyo lẹyin oṣu mẹwaa ti Ọba Lamidi Adeyemi, alaafin ilu Oyo waja.
Ọkan lara awọn ọmọ aafin Oyo amọ ti ko fẹ darukọ ara rẹ lo fidi ọrọ naa mulẹ fun BBC Yoruba.
Iroyin ni wọn yoo gbe e wọ kaa ilẹ loni ni ilana ẹsin Musulumi.
Kini a mọ́ nipa Lasisi Morenikeji?

Ohun ti BBC ri kojọ nipa oloogbe Morenikeji Lasisi ni pe baba agba yii ti lè ni ẹni ọgọ́fà ọdún bo tilè jẹ wí pé a ko tii le fidi ọjọ ori rẹ ni pato mulẹ lasiko ti a n kọ iroyin yii.
Sugbon Lasisi ni wọn n pe ni Baba Kekere laafin Oyo.
O ti n sin gẹgẹ bi ẹru lati ọdun 1945 titi di akoko yii.
Awọn Alaafin wo ni Lasisi ti ba ṣisẹ ni Aafin Oyo?
Baba Kekere Aafin Oyo ni ọpọ maa n pe Lasisi Morenikeji.
O ti ba Oba Adeniran Adeyemi keji ṣiṣẹ laarin ọdun 1945 si ọdun 1956.
Bakan naa ni Lasisi ba Oba Gbadegeshin Ladigbolu keji ṣiṣẹ laarin ọdun 1956 si ọdun 1968 sise.
Leyin naa lo tun jẹ olori gbogbo ẹru ni aafin ni asiko Oba Lamidi Adeyemi kẹta laarin ọdun 1970 si ọdun 2022.
















