Gbogbo ìlérí tí mo ṣe fún ọmọ Nàìjíríà ni mo ti mú ṣẹ - Ààrẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, Muhammadu Buhari/twitter
“Gbogbo ileri ti mo ṣe fun ọmọ Naijiria lọdun 2015 ti mo fẹ gba ijọba ni mo ti mu ṣẹ”.
Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari lo sọ eyi lọjọ Abamẹta ninu ọrọ to fi ranṣẹ si ibi ayẹyẹ ikẹkọgboye fasiti apapọ to wa nilu Ọyẹ Ekiti ni ipinlẹ Ekiti.
Aarẹ Buhari ni iṣejọba oun ti pegede lawọn ẹka bii ọrọ aje, ipenija abo ati gbigbogun ti iwa ajẹbanu gẹgẹ bi ileri to ṣe nigba to de ori oye.
Aarẹ ni awọn nnkan mẹta yii ni oun gbe awọn ileri ti oun ṣe lasiko ipolongo ibo oun le, oun si ti ṣe aṣeyọri nlanla lawọn ẹka naa.
Buhari ni lootọ orilẹede Naijiria ko tii de ilẹ ileri, sibẹ ijọba oun ti fi ẹsẹ Naijiria le ọna idagbasoke ti ko ṣee yipada mọ bayii nipasẹ awọn eto idagbasoke to mu igbayegbadun araalu lọkunkundun.
Aarẹ Buhari sọ pe, “Mo fẹ ran gbogbo yin leti pe lasiko ti mo n ṣe ipolongo ibo lati di aarẹ lọdun 2015, mo ṣeleri lati mu atunṣe ba eto abo, mu ọrọ aje gbopọn sii ati didojukọ iwa ajẹbanu. Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe mo lee fi ọwọ sọya pe mo ti pegede lawọn ileri mẹtẹẹta yii.

Oríṣun àwòrán, muhammadu buhari/twitter
“Nigba ti mo gba ijọba, irọkẹkẹ awọn agbesunmọmi atawọn ipenija eto abo miran ti ṣu bo orilẹede yii. Laifọtape, mo lee sọ pe a ti gbogun ti iwa igbesunmọmi, a si ti bori rẹ, pẹlu bi a ṣe gba gbogbo awọn ilu ti awọn agbesunmọmi gba pada. Lọwọ yii asiko ikẹyin ni fun iwa igbesunmọmi lorilẹede Naijiria.”
Bakan naa l'aarẹ Buhari ni iṣejọba oun tun ti ṣe gudugudu meje yaayaa mẹfa lẹka eto ẹkọ nipa mimu afikun ba iye owo iyasọtọ fun eto ẹkọ ninu eto iṣuna ọdọọdun.








