Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá tí bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí àwọn afurasí jàǹdùkú tó kọlù èèyàn mẹ́rin níbi iponlogo ìbò Peter Obi l'Eko

Peter Obi

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Naijiria fi idi isẹlẹ naa mulẹ pe awọn janduku kan ṣe ikọlu si awọn ololufẹ Peter Obi, oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party nipinlẹ Eko.

Eyi waye lẹyin ti ọpọlọpọ fọnran lori ikọlu naa bọ sori ayelujara Twitter, eyi to ṣafihan bi awọn janduku naa ṣe kọlu ọkan lara awọn ololujẹ Peter Obi nigba to n lọ sibi iponlogo ibo naa.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa fun ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin ni alaga ẹgbẹ oṣelu naa ni ijọba ibilẹ Jakande ti isẹlẹ to ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ni Ilasan lẹti.

O tẹsiwaju pe eeyan mẹrin lo farapa nibi ikọlu naa, ti wọn si ti gbe wọn lọ ilewosan. Hundeyin ni ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadi lori ikọlu naa.

aworan Peter Obi

Oríṣun àwòrán, Rinu/Twitter

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ninu alaye rẹ to gbe sori opo ayelujara Twitter, o ni ikọlu naa waye ni bii kilomita mẹẹdogun sibi ti iponlogo ibo ti waye.

“Ohun to bani ninujẹ ni pe ikọlu naa waye ni kilometa mẹẹdogun si ibi ti iponlogo ọhun ti waye. A ti bẹrẹ iwadii lori ikọlu naa, ti ọwọ yoo si tẹ awọn janduku to ṣe iṣẹ laabi naa ni aipẹ.

“Awọn to farapa ati awọn osojumikoro ti n ran wa lọwọ pẹlu awọn iroyin ti yoo ṣe wa ni anfani lati mu awọn janduku.

“Lati ana ni a ti wa ni gbọngan ti Tafawa Balewa lati moju to bi nnkan ṣe n lọ ati lati rii pe rogbodiyan kan ko waye nibẹ.”