Ìdí rèé tí o fi ní ìpèníjà fífi owó ránṣẹ́ lórí ẹ̀rọ ayélujára

Aworan fonu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lati igba ti ijọba orilẹede Naijiria ti bẹrẹ pasiparọ owo tuntun ọpọ ọmọ orilẹede yii lo ti n sọrọ lori bi nẹtiwọki ẹrọ ibani,sọrọ ti n ṣe ṣegeṣege nigba ti wọn ba n fi owo ransẹ nipasẹ ẹrọ intanẹti.

Nigba miran idaduro ma n wa ti wọn ba n fi owo ransẹ,igba miran itakun Ifowo ransẹ awọn banki ma n dasẹsilẹ.

Eyi ti o ti mu ki ọpọ awọn ọmọ orilẹede yii ni isoro, papajulọ, lati igba ti Banki apapọ ti gba ida ọgọrin owo naira ẹgbẹrun kan naira,ẹẹdẹgbẹta naira ati igba naira atijọ lọwọ awọn ara ilu.

Mustapha Muhammed Garba, akọsẹ mọsẹ nipa eto ẹnawo, to ti fi igba kan ri jẹ ọga agba banki Unity lorilẹede yii,ṣalaye awọn idi ti ṣegeṣege fi ba fifi owo ransẹ.

Garba ni banki apapọ orilẹede yii gbiyanju lati ṣe nkan meji papọ.

Akọkọ ni wi pe wọn gbe owo tuntun jade.

Ikeji ni wi pe wọn gbiyanju lati ṣi oju awọn ọmọ orilẹede yi si fifi owo ransẹ nipa ẹrọ ayelujara.

O ni isoro ti awọn banki ni lọwọlọwọ ko sẹyin ipenija ati yanju awọn isoro yii.

Garba ni ọpọ eeyan ro wi pe ti awọn ba ko milliọnu mẹwa si banki owo atijọ, awọn yoo ri milliọnu mẹwa owo naira tuntun gba pada.

Sugbọn banki apapọ gbe gbadeke owo ti oni kaluku le gba jade lojojumọ.

O ni tẹlẹtẹlẹri, ida ọgọrin owo orilẹede yii lo wa lọwọ awọn onisowo, ki banki apapọ to kede ki wọn da wọn pada lati wa paarọ wọn.

Bakan naa, wọn si fẹ ki wọn ma se okoowo wọn pẹlu fifi owo ransẹ nipa ẹrọ ayelujara.

O ni eleyi lo mu ki gbogbo nẹtiwọọki ja papọ, ti ko si fi bẹẹ si ojutu, paapaa pẹlu bi ọwọn gogo Naira se wa nita.

Aworan Banki

Oríṣun àwòrán, BBC YORUBA

Ọnà Àbáyọ

Garba ni yoo dara ki banki apapọ yara ṣe amulo lilo ẹro ayelujara lati fi owo ranṣẹ gẹgẹ bi igbesẹ ti Gomina banki apapọ tẹlẹri Sanusi Lamido se ni ọdun 201.

O ni Sanusi faaye silẹ fun lilo ẹrọ ayelujara lati fowo ransẹ ni awọn ipinlẹ kọọkan bi Eko, Abuja ati Port Harcourt.

O teṣiwaju pe ọpọ ero lori awọn itakun ifowo ransẹ tun se akoba fun ilana naa nitori awọn to fẹ lo itakun ifoworansẹ naa lẹkansoso pọ pupọ.

Mustapha ni oṣeṣe ki iṣoro lilo itakun ayelujara lati fi owo ransẹ tẹsiwaju nitori, awọn banki gbogbo ṣetan lati tun itakun ẹrọ fifi owo ranṣe wọn ṣe.

Aworan Ero ATM

Oríṣun àwòrán, Ero ATM

Wàhálà dé báwọn òṣìṣẹ́ báńkì ṣe ń fo ògiri jáde, àwọn báńkì kan tí ẹ̀ka wọn kan pa l‘Eko torí ìkọlù

Banki Zenith

Ile ifowopamọ Zenith atawọn banki kan ti sọ agadagodo sẹnu ọna awọn ẹka banki wọn kakari orilẹede Naijira.

Eyi ko si sẹyin bi awọn onibara kan ṣe n dunkoko lati ṣe ikọlu si awọn osisẹ Banki naa.

Iwadii ileeṣẹ BBC fihan pe lootọ nipe awọn osisẹ banki kan fo ogiri jade kuro ninu awọn ẹka Banki naa lẹyin ti ọpọ awọn onibara ṣe ikọlu si wọn.

Ọkan lara awọn osisẹ banki Zenith to ba ileeṣẹ BBC sọrọ ni awọn alasẹ gbe igbesẹ naa nitori bi kudiẹ kudiẹ ṣe ba ọpọ oju opo ayelujara banki naa ati bi owo Naira tuntun ṣe safẹrẹ lorilẹede Naijiria.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ile ifowopamọ Zenith

Awọn onibara n pariwo nita Banki Zenith pẹlu omije loju tori wọn ko ri owo gba

Osisẹ ọhun ti ko nifẹ lati da orukọ rẹ salaye pe ọpọ awọn osisẹ banki ni wọn la ọpọ ijamba kọja lati ọwọ awọn onibara ti wọn ko ri owo wọn gba jade.

Akọroyin ileeṣẹ BBC to kakiri ipinlẹ Eko ri pe awọn ẹka banki Zenith ni agbegbe Ikeja, Ikorodu, Yaba, Onipanu, Somolu ati Agege ni o wa ni titi pa, ti ọpọ eeyan si wa nita.

Bakan naa ni pupọ ninu awọn onibara n pariwo nita Banki ọhun pẹlu Omije loju lẹyin ti wọn ko anfani lati gba owo sita.

Ọpọ lo kigbe pe awọn ọmọ awọn wa nile ti wọn ko ri nkan jẹ nitori ko si owo lọwọ lati ra ounjẹ.

Ọpọlọpọ aworan lo fi fihan lori ayelujara bi awọn osisẹ Banki naa ṣe n fo fereṣe jade kuro ni ayika ẹka Banki.

Yatọ si fọran bi awọn osisẹ n sara kuro ni ileesẹ wọn, ọpọlọpọ fọran lo wa lori lori ayelujara bi awọn onibara ṣe n faraya ni ile fowopamọ nitori wọn ko ri owo wọn gba jade.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ki ni awọn eeyan n sọ nipa Ile fowopamọ Zenith Banki lori Ayelujara?

Ọpọ awọn onibara ile fowopamọ Zenith ni wọn ti tu sita lori opo ayelujara Twitter lati bu ẹnu atẹlu bi ile fowopamọ naa ṣe pinnu lati ṣe awọn onibara wọn ni ka.

@ Ellacious_berry ni, “Zenith Bank kopa fifi iya jẹ araalu.

“Lati ibi ọjọ mẹta si asiko yii, n ko le lọ ẹrọ app ile fowopamọ mi. Ti n ko si le fi owo ramsẹ jade si ẹnikẹni. Mo ma ti apo owo mi pẹlu Zenith.”

@ambi 255 lori Twitter, ni isoro ti awọn onibara Zenith n la kọja ni lẹnu ọjọ mẹta bayi ni ko dara rara.

“Asiko ti to lati ti apo owo mi pẹlu Zenith.”