Àwọn gómìnà APC ló gbàwọn ọmọ Nàíjíríà kalẹ̀ lọ́wọ́ ìṣòro pẹ̀lú ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ - Tinubu

Olùdíje sípò ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, ti kan sáárá sí àwọn gómìnà mẹ́rìndínlógójì orílẹ̀ èdè yìí fún bí wọ́n ṣe dúró ti àwọn ènìyàn láti mú àdínkù bá wàhálà tí àwọn ènìyàn ń kojú lórí ọ̀wọ́ngógó owó Náírà.
Bákan náà ló tún yin àwọn gómìnà ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC lákin fún ìgbésẹ̀ wọn láti gbé ilé ìfowópamọ́ àgbà lọ sí ilé ẹjọ́ lórí gbèdéke ọjọ́ tó wà lórí owó Náírà àtijọ́ èyí tó yẹ kọ kásẹ̀ nílẹ̀ lọ́jọ́ Kẹwàá oṣù Kejì, ọdún 2023.
Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ìpolongo ìbò Tinubu, Bayo Onanuga fi léde ní àwọn gómìnà náà gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ láti jà fún àwọn ọmọ Nàìjíríà tí kò le jà fún ara wọn lórí ìpèníjà tí owó tuntun tí CBN gbé jáde ń kó bá wọn.
Awọn gomina APC ti gbawọn ọmọ Naijiria kalẹ lọwọ ọrọ aje àti oselu - Tinubu
Ní òwúrọ̀ ọjọ́rú ni ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà gbé ìdájọ́ kalẹ̀ pé kí àwọn ènìyàn máa ná owó ₦200, ₦500 àti ₦1,000 tí à ń ná tẹ́lẹ̀ kọjá gbèdéke tí CBN gbé kalẹ̀.
Àwọn gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi, Zamfara àti Kaduna ló gbé CBN lọ sí ilé ẹjọ́ lórí gbèdéke tí ilé ìfowópamọ́ àgbà náà gbé lé ọjọ́ tí àwọn owó náà kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà mọ́.
Tinubu lẹ́yìn ìdájọ́ náà ní àwọn gómìnà náà ti gba orílẹ̀ èdè yìí kalẹ̀ lọ́wọ́ làásìgbò ètò ọrọ̀ ajé àti ti òṣèlú èyí tí ètò ti CBN náà gbé kalẹ̀ ti ń fà ní àwọn ìpínlẹ̀ kan ní orílẹ̀ èdè yìí.
Ó ní òun ní ìgbàgbọ́ pé ètò tí CBN gbé kalẹ̀ lórí pípààrọ̀ àwọn owó kan àmọ́ àsìkò tó wáyé yìí àti bí wọ́n ṣe ń gbe kalẹ̀ ti ń fa àwọn awuyewuye káàkiri Nàìjíríà.
Ìdájọ́ ilé ẹjọ́ Supreme wà ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn IMF
Tinubu wòye pé ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ náà gbé kalẹ̀ wà ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn tí àjọ International Monetary Fund (IMF), tó ní kí CBN fi ọjọ́ kún gbèdéke ọjọ́ tí wọ́n fún àwọn ènìyàn.
“Orílẹ̀ èdè wa ti ń lọ sí oko ogun lórí ìṣòro tí àwọn ènìyàn ń kojú láti rí owó ná, tó sì tún ti ń fẹ́ dá wàhálà òṣèlú sílẹ̀.”
“Àmọ́ ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ yìí máa mú àyípadà bá èyí, a dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ ilé ẹjọ́ Supreme fún ìdájọ́ yìí”
Ó fi kun pé àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ nílò láti wá ọ̀nà tí wọn yóò gbà láti gbé ètò owó pípáàrọ̀ gbà lọ́nà tí kò ní mú wàhálà tàbí ìnira dání fún àwọn ọmọ Nàìjíríà.
Tinubu ní CBN nílò láti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè tó ti pààrọ̀ owó wọn síwájú lọ́nà tí kò mú ìnira bá àwọn ará ìlú àti pé ní àwọn orílẹ̀ èdè náà ó máa ń tó ọdún kan tí wọ́n máa ń fún àwọn ènìyàn dà láti pààrọ̀ owó wọn.
“Ó ti hàn gbangba pé ètò tó bá dára le fa wàhálà fún àwọn ènìyàn tí wọ́n ń ṣe é fún tí wọn kò bá ṣe àmúlò rẹ̀ dáadáa.”
Bákan náà ló rọ CBN láti tẹ̀lé ìdájọ́ ilé ẹjọ́ náà nípa pípèsè owó náírà lọ́pọ̀ yanturu yálà owó ti àtijọ́ tàbí tuntun àti pé kí wọ́n ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó péye fún àwọn ènìyàn lórí ìgbà tí owó àtijọ́ le kásẹ̀ nílẹ̀.
Ẹ fọkàn balẹ̀, ẹ gba ìjọba láàyè láti fòpin sí rògbòdìyàn yìi - Tinubu

Oríṣun àwòrán, AsiwajuBolaTinubu/Facebook
Oludije sipo Aarẹ ti ẹgbẹ APC , Asiwaju Bola Tinubu, ni ọjọ iṣegun rawọ ẹbẹ si awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria lati gba Ijọba apapọ laaye lati wa ojutu si iṣoro ọwọngogo epo ati aito Naira tuntun.
Aito owo naira tuntun ati gbedeke kukuru ti banki apapọ orilẹ-ede yii gbe jade ti da wahala silẹ lorileede yii.
Laarin ọsẹ to kọja, ọpọlọpọ awọn ipinlẹ ni ifẹhonuhan ti waye, ti ọpọlọpọ eniyan kerora nitori inira ti wọn dojuko .
Nigba ti Tinubu n ba awọn akọroyin sọrọ nilu Abuja, o bẹ awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria, papa julọ awọn ti wọn n koju iṣoro nitori aisi epo ati aito owo naira tuntun.
Bakan naa lo gboriyin fun ajọ Nigeria National Petroleum Corporation Limited fun ipese epo ti awọn olugbe Abuja ri, o si rọ ile-iṣẹ naa lati gbe igbesẹ ati mu idẹrun ba awọn ipinlẹ miiran kaakiri orilẹ-ede yii.
Tinubu tun rọ banki apapọ orilẹ-ede yii CBN, lati maṣe lekoko mọ gbedeke ọjọ to la silẹ fun fifopin si nina owo naira atijọ, nitori inira ti awọn ọmọ orilẹ-ede yii lakọja.
Ninu ọrọ rẹ Tinubu ni " Bí ijọba apapọ ṣẹ n wa ojutu si awọn iṣoro wọnyi, ẹ jẹ ka fara balẹ, ka si mase faye gba iwa janduku.
Ohun ti awọn alatako wa ati awọn ọta ijọba awarawa n fẹ ni kí rogbodiyan ko wa, eyi to seeṣe ko ṣakoba fun eto idibo.
A ko gbọdọ faye gba, a gbọdọ ri wi pe eto idibo lọ ní alafia ".
APC ṣàlàyé ìdí tí ìpolongo ìbò Tinubu tó yẹ kó wáyé ní Ibadan, kò fi le wáyé mọ́

Oríṣun àwòrán, @BATofficial
Ẹgbẹ oṣelu APC tí sun ìpolongo ibo aarẹ to yẹ ko waye loni nilu Ibadan, tii se olu ilu ipinlẹ Oyo siwaju.
Eyi ko sẹyin bí iwọde ṣe n waye lori ọwọn gogo epo ati bi owo naira to safẹrẹ ni agbegbe naa.
Ikede naa waye lọjọ Aje, ọjọ kẹfa oṣu kinni ọdun 2023.
Tinubu lo yẹ ko gbe ìpolongo ibo aarẹ wa siluu Ibadan loni sugbọn bii nnkan ṣe lọ ní ìpínlẹ naa lọwọ lọwọ bayi, ni igbagbọ wa pe o sokunfa idi ti ẹgbẹ oṣelu APC fi sun ipolongo ibo naa siwaju.
A sun ipolongo ibo Tinubu siwaju tori laasigbo tí Naijiria n la kọja lasiko yii - APC
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu APC, Wasiu Sadare, fi lede fun awọn akọroyin, ó salaye idi ti APC se sun ipolongo ibo naa siwaju.
APC ni torí bi ọwọn gogo epo bentiro ati bí owo naira ṣe nira lati ni fun awọn ọmọ Orilẹede Naijiria lo fa tí awọn fi gbe igbesẹ naa.
"Ẹgbẹ oselu APC tí sun ìpolongo ibo aarẹ tí ipinlẹ Oyo siwaju.
"A gbe igbesẹ yii nítorí gbogbo laasigbo tí awọn eeyan ipinlẹ naa ati Orilẹede Naijiria n la kọja lasiko yii.
"Aarẹ Muhammadu Buhari nilo akoko lati wa ojutu sì gbogbo rogbodiyan naa, kí alaafia sì pada."
















