Ìdìbò 2023 kò ni lulẹ̀, a ti yanjú àwọn ìṣòro tó kojú wa - INEC

mahmood yakubu

Oríṣun àwòrán, Mahmoodyakubu/facebook

Ajọ to ṣakoso eto idibo orile-ede yii (INEC) ti ṣe idaniloju pe eto idibo gbogboogbo ọdun 2023 yoo waye gẹgẹbi ajọ naa ti la kalẹ.

Alaga ajọ INEC, Ojogbon Mahmood Yakubu, lo sọ ọrọ idaniloju yii lakoko ti o n ba awọn akọroyin sọrọ, lẹhin ti o ti ṣe ipade pẹlu Igbimọ Alasẹ ijọba apapọ (FEC) nilu Abuja.

O sọ pe ajọ INEC ti yanju awọn iṣoro to le ṣe akoba fun lakoko owongogo epo yii.

Ọpọ ọmọ orilẹede yii ni o ti n se aniyan lori bi eto idibo ọdun yii yoo ṣe kẹsẹ jari nitori owongogo epo bẹntiro ati iṣoro aito naira tuntun

Mahmood ni ajọ INEC ti ni idahun si awọn iṣoro ti o le dojukọ.

"NNPC yoo fun wa ni epo lati ra, a ti ba ẹgbẹ awakọ ero se ipade"

Alaga ajọ INEC ni "iṣoro akọkọ ti ajọ naa doju kọ ni aisi epo bẹntiro, ṣugbọn ati ṣe ipade pẹlu awọn ẹgbẹ awakọ ti wọn sọrọ lori aisi epo.

Sugbọn lọwọlọwọ bayii, ajọ to risi ọrọ epo bentiro ti gbe ẹgbẹ kan kalẹ ti yoo risi bi opin yo se de ba aisi epo bẹntiro".

Ọjọgbọn Mahmood ni "ile iṣẹ NNPC yoo fun awọn ni anfani lati ra epo ni awọn ile iṣe NNPC to wa jakejado orilẹ-ede yii, ko le rọrun lati gbe awọn ohun elo idibo ".

Nipa iṣoro aisi owo "Ajo INEC ati Gomina banki apapọ CBN ti ṣe ipade, ti wọn si fi da wa loju pe ajọ INEC ko ni ni idaduro kankan".

Mahmood ni gbogbo akanti ajọ INEC lo wa labẹ akoso banki apapọ CBN nitorina, ko si idi ti eto idibo ọdun yii ko ni fi waye.

Emefiele, tó ò bá ṣọ́ra, àfàìmọ̀ kí ẹ̀hónú òͅwóngógó Naira àti epo má dabarú ìbò 2023 - INEC sòͅròͅ sókè

Ifẹhonuhan

Oríṣun àwòrán, screenshot

Alaga ajoͅ eto idibo lorileͅede Naijiria, Mahmood Yakubu ti ni o seese ki rogbodiyan to gbode kan nitori oͅwoͅngogo naira ati beͅntirol dabaru eto idibo oͅdun 2023 lorileͅede Naijiria.

Eyi waye lasiko to ku oͅjoͅ meͅrindinlogun ki eto idibo sipo aareͅ waye kaakiri Naijiria.

Alaga ajoͅ INEC lo soͅ beͅeͅ lasiko to n sepade poͅ peͅlu gomina ileesͅeͅ banki apapoͅ Naijiria, Godwin Emefiele ni ilu Abuja.

O fikun un pe oͅpoͅloͅpoͅ awoͅn osͅisͅeͅ INEC ni ko ni apo isuna peͅlu banki Kankan.

‘’Ọwọngogo naira gboͅdoͅ dopin ki idibo naa ba le waye.’’

O wa kesi CBN lati sͅisͅeͅ peͅlu awoͅn araalu ati INEC lati fopin si oͅwoͅngogo to gbode kan naa.

Ninu oͅroͅ reͅ o ni eto idibo Niajiria jeͅ eleyii to lagbara ti o si nilo gbogbo eͅka ijoͅba lati baa sͅisͅeͅ peͅlu eto idibo ki o le kͅeͅsͅeͅjari.

‘’Oͅkan lara awoͅn eͅka to se koko naa ni eto irinna ni Naijiria ati awoͅn eniyan to jeͅ bi oluranloͅwoͅ Pataki si woͅn.’’

O ni awoͅn woͅnyii ni awoͅn maa san owo fun leͅyin ti awakoͅ ba gbe woͅn de ibi ojuko idibo nitori naa o se koko ki ajoͅ INEC gbe yeͅwo.

‘’Bakan naa ni isͅeͅleͅ pajawiri lee waye to le fa ki awoͅn nilo owo lati fi san nkan, ti oͅpoͅ ninu awoͅn ti woͅn n ba woͅn sͅisͅeͅ yii ko si ni apo isuna Kankan ni ile ifowopamoͅsi.’’

‘’Nitori naa owongogo naira yii gboͅdoͅ dopin ni asiko yii ki idibo naa ba le waye.’’

A sa ipa wa lati ri pe owo beba wa fun INEC lati na - CBN fesi

Ninu oͅroͅ reͅ, gomina banki apapoͅ Naijiria, Godwin Emefiele ni gbogbo igbiyanju ajoͅ INEC ni awoͅn ri, ti awoͅn yoo si sa ipa woͅn lati ri pe owo wa fun ajoͅ INEC lasiko idibo yii.

Emefiele ni awoͅn yoo gbiyanju lati ri pe banki apapoͅ Naijiria ko se okunfa fun ifaseͅyin eto idibo gbogboogbo ni Naijiria.

O ni awon yoo sa ipa woͅn lati ri pe INEC ri owo naa lasiko idibo, ti woͅn yoo si lee loͅ lati ibi kan si omiran.

Emefiele ni awoͅn ko fi igba Kankan ja Naijiria kuleͅ ri, ko si ni waye lasiko idibo oͅdun yii.

Adari CBN naa fi da INEC loju pe owo ko ni fa inira fun awoͅn osͅisͅeͅ INEC lasiko eto idibo naa ti yoo waye ni oͅseͅ meji si isinyii.

Àkọlé fídíò, Joy Adekunle Adejare: Torí òkìkí tí mo ní nídìí iṣẹ́ àgbo ni wọ́n ṣe jí ọkọ mí gbé, pa á

Wàhálà bẹ̀rẹ̀ lórí àtúnṣe Naira tí CBN ṣe, gómìnà mẹ́ta ní APC àtàwọn ẹgbẹ́ òṣèlú mẹ́tàlá gbógun tira wọn

Aworan owo ati oolu

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Pẹlu bi ọrọ ayipada owo lorilẹede Naijiria ti ṣe di eyi ti gbogbo awọn olugbe Naijiria n pariwo le lori bayii, ile ẹjọ ti gbalejo igun oselu meji lori ọrọ naa.

Ile ẹjọ giga apapọ kan nilu Abuja ti fọwọ si ẹbẹ awọn igun oṣelu kan to n beere fun iwe aṣẹ lati so aarẹ lọwọ kọ pe ko gbọdọ yi ipinnu pada lori gbedeke ayipada owo tuntun lorilẹede Naijiria.

Awọn wo lo gba idajọ to so aarẹ lọwọ kọ pe ko gbọdọ yin ohun pada lori gbedeke ayipada owo?

Awọn wo lo gba idajọ to so aarẹ lọwọ kọ pe ko gbọdọ yin ohun pada lori gbedeke ayipada owo?

Awọn oludije fun ipo aarẹ, ipo gomina ati aga ile aṣofin apapọ pẹlu awọn alaga ẹgbẹ oṣelu marun un kan lorilẹede Naijiria ni wọn gba ile ẹjọ giga apapọ lọ nilu Abuja nibi ti wọn ti rọ ile ẹjọ naa pe ko paṣẹ fun aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari, banki apapọ Naijiria, CBN ati gomina banki apapọ naa pe wọn ko gbọdọ fọwọ kan gbedeke ọjọ ti wọn fi lelẹ fun ayipada owo Naira lorilẹede Naijiria.

Aworan iwe igbejo

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn wo lo gba idajọ to so aarẹ lọwọ kọ pe ko gbọdọ yin ohun pada lori gbedeke ayipada owo?

Awọn oludije fun ipo aarẹ, ipo gomina ati aga ile aṣofin apapọ pẹlu awọn alaga ẹgbẹ oṣelu marun un kan lorilẹede Naijiria ni wọn gba ile ẹjọ giga apapọ lọ nilu Abuja nibi ti wọn ti rọ ile ẹjọ naa pe ko paṣẹ fun aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari, banki apapọ Naijiria, CBN ati gomina banki apapọ naa pe wọn ko gbọdọ fọwọ kan gbedeke ọjọ ti wọn fi lelẹ fun ayipada owo Naira lorilẹede Naijiria.

Aworan iwe igbejo

Lọjọ Aje ni ile ẹjọ naa gbe idajọ rẹ kalẹ eyi to fi pa aṣẹ fun aarẹ, banki apapọ Nijiria, gomina banki apapọ Naijiria atawọn banki mẹta dinlọgbọn kan pe onyẹ kan ko gbọdọ yẹ gbedeke ọjọ kẹwaa oṣu keji ọdun 2023.

Bakan naa ni ile ẹjọ naa paṣẹ fun awọn adari agba banki lorilẹede Naijiria pe ki wọn sọ idi ti wọn ko fi ni foju ba ile ẹjọ fun ẹsun lilodi si ofin iṣuna nipa kiko awọn owo tuntun pamọ.

Gomina ipinlẹ Mẹta labẹ ẹgbẹ oṣelu APC naa gbe Buhari lọ si ile ẹjọ lati sun gbedeke siwaju

Awọn agbẹjọro agba lawọn ipinlẹ mẹtẹẹta lo pe ẹjọ naa nigbati Abubakar Malami to jẹ agbẹjọro agba fun ijọba apapọ yoo jẹ olujẹjọ.

Aworan Gomina Zamfara,YayaBello,Gomina Kaduna

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn gomina mẹtẹtẹta naa n jiyan pe afikun ọjọ mẹwaa ti ijọba fi lelẹ ko lee tan inira ti eto ayipada owo naa n mu ba araalu.

Awọn gomina mẹtẹta n fẹ ki ijọba apapọ jawọ lori fifi gbedeke le ayipada owo naa.

Wọn ni labẹ ofin to de idasilẹ banki apapọ Naijiria, CBN Act, abala ogun ẹsẹ kẹta rẹ fihan pe Banki apapọ ko ni agbara tabi aṣẹ kankan lati fi gbedeke ọjọ si ori ayipada owo si tuntun.

Kí ló fà tí ẹgbẹ́ òṣèlú 13 fí ń dúnkokò láti má kópa nínú ètò ìdìbò?

Aworan Nigeria

Oríṣun àwòrán, Others

Ẹgbẹ oṣelu mẹtala ninu ẹgbẹ oṣelu mejidinlogun to fẹ kopa ninu eto ìdibo lorilẹede Naijiria ti leri pe awọn ko ni kopa ninu eto ìdibo lọjọ Kẹdogun, oṣu kejì ati ọjọ kẹtala, oṣu kẹta ti banki apapọ Orilẹede Naijiria ba fikun ọjọ ti wọn yoo ko owo naira tẹlẹ nilẹ, ìyẹn ọjọ kẹwaa oṣu kejì ọdun yii.

Apapọ awọn alaga ẹgbẹ oselu naa kan sara sì Aarẹ Muhammadu Buhari lori atunṣe owo Orilẹede Naijiria, ti wọn lodi si ki mimi kankan mi asẹ naa.

Bakan naa ni awọn ẹgbẹ oselu naa bu ẹnu atẹlu bi ìjọba ìpinlẹ Kaduna,Kogi ati Zamfara ṣe wọ ìjọba apapọ lọ ileẹjọ lori afikun gbedeke ọjọ ti wọn yoo ko owo naira tẹlẹ nilẹ.

Alaga ẹgbẹ oṣelu Acton Alliance, Kenneth Udeze, ẹni to ba awọn akọroyin sọrọ ni, "A ṣe ikede pe ẹgbẹ oṣelu mẹtala ninu ẹgbẹ oṣelu mejidinlogun to fẹ kopa ninu eto ìdibo gbogbo gbo ninu oṣu yii ko ni kopa mọ ninu eto ìdibo ti ijọba apapọ ba yín ìpinnu wọn lori owo naira pada."

Ọsẹ to kọja ni Gomina Banki Naijiria, Godwin Emefiele kede pe ijoba ti fi kun gbendeke asiko ti won yoo ko owo atijo kuro nile.

Emefiele ṣalaye pe lẹyin ọpọlọpọ ipade pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari ni wọn pinnu lati fi kun iye ọjọ ti wọn yoo ko owo naa kuro nilẹ.

Saaju ni wọn ti kede ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kinni, ọdun 2023 gẹgẹ bi ọjọ to gbẹyin ṣugbọn bayii, wọn ti sun un siwaju di ọjọ kẹwaa, oṣu keji, ọdun 2023.