Ìdí tí PDP fi wọ́gilé ìpolongo ìdíbò Atiku ní ìpínlẹ̀ Rivers àti ohun tí Wike sọ!

Oríṣun àwòrán, Others
Ẹgbẹ alatako lorilẹede Naijiria, Peoples Democratic Party ti wọgile ipolongo idibo sipo aarẹ to yẹ ko waye ni Ọjọ Iṣẹgun, Ọjọ Kẹrinla, Oṣu Keji, ọdun 2023.
Alaga ajọ ipolongo idibo sipo aarẹ ni Rivers, Senetọ Lee Maeba lo sọ fun awọn oniroyin ni Port Harcourt pe idi ti awọn ko fẹ ki ẹmi awọn eniyan ṣofo ni wọn ṣe gbe igbeṣẹ naa.
Maeba ni iṣesi gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike si awọn araalu ati si eto ipolongo oludije sipo aarẹ, Atiku Abubakar lo mu wọn wọgile ipolongo naa.
O ni awọn ẹṣọ alaabo nipinlẹ naa ni awọn ko lee da awọn eniyan loju pe aabo to peye yoo waye lasiko ipolongo idibo naa.
‘’Awa ajọ eto ipolongo idibo sipo aarẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ti woye pe eto aabo to peye ko ni lee wa fun awọn araalu ni asiko ipolongo idibo naa lo mu wa gbegile eto naa.’’
‘’A si woye pe ko dara ki ẹnikẹni sọ ẹmi rẹ nu lasiko ipolongo nitori oludije wa.’’
‘’Nitori naa a kesi aarẹ Buhari lati ri pe awọn ẹṣọ alaabo ṣiṣẹ wọn bi iṣẹ, ti wọn ko si ni fi si apa kan ju ibi kan lọ lasiko eto idibo naa.’’
Ọjọ Kẹrinla, Oṣu Keji, ọdun 2023 ni o yẹ ki eto ipolongo naa waye ni ipinlẹ Rivers.
‘’Igba akọkọ kọ niyii ti wọn n fagile ipolongo idibo sipo aarẹ ti ẹgbẹ oṣelu PDP ni Rivers’’
Ni Ọjọ Kọkanla, Oṣu Kini, ọdun 2023 ni ipinlẹ Rivers kọkọ fun awọn ẹgbẹ oṣelu PDP ni papa iṣere Amiesimaka lati lọ fun ipolongo idibo ni Ọjọ Kọkanla, Oṣu Keji, ọdun 2023.
Lẹyin ti awọn igbimọ lo ṣe ayẹwo papa iṣere naa ni ijọba fi ofin de wọn pe wọn ko ni anfaani lati wọ ibẹ titi di wakati mejidinlaadọta ki eto ipolongo naa to waye.
Amọ ni ọgbọnjọ, oṣu kini ni ijọba wa kede pe wọn ko ni ni anfaani lati lo ibẹ mọ nitori ẹgbẹ osẹlu APC naa fẹ lo ibẹ.
Bakan naa ni wọn fi ẹsun kan gomina naa pe oun lo awọn alakatakiti lati dabaru lasiko eto idibo naa.
‘’Ẹ o ni awọn eniyan to kunjuwọn lati ṣeto ipolongo idibo nipinlẹ Rivers’’- Nyesom Wike

Oríṣun àwòrán, Others
Amọ gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike ni idi ti PDP fi wọgile eto ipolongo idibo nipinlẹ naa ni pe wọn ko ni awọn eniyan lọgọọrọ lati wa si ibi gbagede naa.
Oni ajọ PCC ti ẹgbẹ oṣelu PDP ni ilu Abuja ti kesi wọn lati fun wọn ni ibi ti wọn yoo lo fun ipolongo naa ti awọn si ti buwọluu.
Amọ o ni nitori wọn ko ni ọpọ ero ti yoo kun ibi ti wọn fẹ lo ni papa iṣere Amiesimaka ni wọn sẹ n wa agbegbe miran lati lo.
O ni idunkokomọni lori asan ni ẹsun ti igbimọ ipolongo PDP fi kan oun nitori oun ti buwọlu gbagede fun wọn amọ nitori wọn ko ni ero to pọ ni wọn ṣe n wa ọrọ lori asan.
Bakan naa lo ni ko si ẹnikẹni to n gbero lati da eto idibo naa ru amọ ẹgbẹ oṣelu PDP naa ni ko ṣe iṣẹ wọn bi iṣẹ ki wọn le ni awọn eniyan lọgọọrọ lati kun inu ibẹ.












