‘Láti kékeré ni Adolisa ti ń ṣe bí obìnrin àmọ́...- Àwọn tó mọ Adolisa bá BBC sọ̀rọ̀

Adolisa Emmanuel

Oríṣun àwòrán, Instagram

Àwọn ènìyàn tó mọ arákùnrin Emmanuel Adaolisa tí ọ̀pọ̀ rò bóyá obìnrin ni tó papòdà ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ti ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣe rẹ̀ kí ọlọ́jọ́ tó dé ba.

Láti ìgbà tí ìròyìn ikú rẹ̀ ti gbòde ni àwọn ènìyàn tí wọ́n ní àjọṣepọ̀ kan tàbí òmíràn pẹ̀lú rẹ̀ ti ń sọ irú ènìyàn tó jẹ́ àti ìwà rẹ̀ láti ìgbà tó wà ní kékeré.

Àwọn ènìyàn tó mọ Adaolisa nígbà tó ṣì wà ní Olisa sọ fún BBC Igbo pé láti ìgbà tí Adolisa ti ń dàgbà ló ti máa ń ṣe bíi obìnrin.

Wọ́n ní ó fẹ́ràn láti máa jó, kọrin pẹ̀lú lílo ohùn obìnrin àti láti máa ṣe ìṣe obìnrin lápapọ̀.

Bí Nwolisa ṣe di Adaolisa rèé

Àwọn tí wọ́n mọ Adaolisa láti ìgbà tó wà ní kékeré ní Olisa Ogoegbunam ni orúkọ tó ń jẹ́ látilẹ̀.

Ẹnìkan tó ń jẹ́ Ogoo ní agbègbè American Quarters ní ìlú Onitsha, ìpínlẹ̀ Anambra ni àwọn òbí Adaolisa ń gbé níbẹ̀ sì ni òun àti àwọn àbúrò rẹ̀ ti dàgbà.

Ogoo ní ọmọ ìjọ Kátólíìkì tọkàntọkàn ni Adaolisa ń ṣe.

Ó ní ó wà nínú ẹgbẹ́ akọrin tó mọ ijó jó, tí ó sì ní ohùn obìnrin èyí tó dùn dáradára.

Ó fi kun pé obìnrin ni àwọn máa ń pè é lásìkò náà àmọ́ àwọn kò mọ̀ wí pé ó le lọ paradà sí obìnrin.

Ó ní àwọn kàn máa ń wò ó nígbà náà gẹ́gẹ́ bí ẹni tó kàn fẹ́ gbé ìgbé ayé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bó ṣe wù ú àti pé ó kàn fẹ́ràn orin kíkọ àti ijó jíjó lásán.

Ẹlòmíràn tó tún sọ̀rọ̀ nípa Adaolisa ní ó jẹ́ ẹni tó fẹ́ràn ẹ̀dá ẹgbẹ́ rẹ̀, tí kìí fa wàhálà, ènìyàn dáadáa

Adolisa pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nínú ìjàmbá ọkọ̀ ni àṣírí bá tú pé ọkùnrin ni

Emmanuella Adolisa

Oríṣun àwòrán, Instagram

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn ọmọ ijọ Katoliiki St. John’s Catholic Church, Rumuolumeni ni Iwofe ni ilu Port Harcourt nipinlẹ Rivers lẹkun gusu Naijiria, ṣi n yanu lẹyin isẹlẹ aramnda kan to waye ninu ijọ naa.

Ọmọ ijọ naa kan, ti wọn mọ si omidan Emmanuella Adaolisa, to jẹ ọmọ ijọ wọn, ni asiri tu pe kii ṣe obinrin ati pe ọkunrin to n ṣe iṣe obinrin ni.

Awọn oṣiṣẹ ile igbokusi lo tu aṣiri yii sita nigba ti wọn fẹ bẹrẹ si ni ṣe iṣẹ itọju lara oku rẹ nigba ti alufa ijọ naa atawọn ọmọ ijọ rẹ gbe oku rẹ wa gẹgẹ bi obinrin laimọ pe ọkunrin to n ṣe iṣe obinrin ni.

Gẹgẹ bi iroyin ti a gbọ ṣe sọ, akẹkọgboye imọ nipa ogun pipo ni Emmanuella Adaolisa, ile ẹkọ giga fasiti ilu Port Harcourt lo si ti kẹkọgboye, ṣugbọn obinrin lo n pe ara rẹ fun gbogbo eniyan.

Ni ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kini ọdun 2023, lẹyin ipade irọlẹ ni ile ijọsin naa, Emmanuella, ti oun pẹlu wa nibi ipade adura naa n pada lọ sile, lo ba ko agbako ijamba ọkọ, nibi to ti jabọ ninu kẹkẹ maruwa to wọ, bọ sinu gọta.

Ẹjẹ bẹrẹ si nii da lara rẹ, paapaa julọ oju rẹ. Ohun nikan si lo ku ninu ijamba naa.

Lẹyin asiko diẹ, iroyin kan awọn ọmọ ẹgbẹ akọrin ijọ lara pe ọkan lara awọn ọmọ ijọ wọn ni ijamba, eleyi lo si mu ki alufa ijọ naa sare tete lọ sibẹ, ti wọn si gbe e lọ si ile iwosan.

Ileewosan akọkọ ti wọn gbe e de kọ lati gba a wọle, ni wọn fi gbe e lọ si ile iwosan awọn ologun to wa ni opopona Aba road, nibi ti awọn dokita ti fidi rẹ mulẹ pe o ti ku, ki o to de ọdọ awọn.

Wọn gbe oku rẹ lọ si ile igbokupamọ si nibi ti awọn oṣiṣẹ ibẹ ti jẹ ko di mimọ pe ọkunrin to n ṣe iṣe obinrin, ti awọn oloyinbo n pe ni ‘transgender’ ni Emmanuella to ku

Àwọn nǹkan tí a mọ̀ nípa Adolisa Emmanuel

Adolisa Emmanuella

Oríṣun àwòrán, ALIYAHLAKSHMI/INSTAGRAM

Ilé ẹ̀kọ́ girama tó jẹ́ ti àwọn ọkùnrin nìkan ìyẹn Metropolitan Secondary School, Onitsha èyí tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Metro ni Adolisa lọ.

Ó kọ́ ẹ̀kọ́ nípa oògùn pípò ní ilé ẹ̀kọ́ gíga University of Port Harcourt.

Ó jẹ́ ẹni tó ní ìgbàgbọ́ nínú ìjọ Àgùdà gẹ́gẹ́ bó ṣe hàn nínú ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan tó ń fi sórí ayélujára rẹ̀.

Bákan náà ló ní ìmọ̀ púpọ̀ orin kíkọ, tó sì mọ àwọn ohun èlò orin bíi gìtá àti violin lò dada.

Àkáǹtì Facebooko méjì ló ní ìkan pẹ̀lú orúkọ rẹ̀ tó ń jẹ́ tẹ́lẹ̀, Emmuel Nwolisa, ọdún 2021 ló ti fi àwòrán síbẹ̀ kẹ́yìn.

Àkáǹtì kejì ni èyí tó ti ń jẹ́ Emmanuel Adaolisa tó ṣí ní ọdún 2022 nígbà tó paradà di obìnrin.

Kí ọkùnrin máa ṣe bíi abo tàbí kí abo máa ṣebí akọ ní Nàìjíríà

Idris Okuneye, ọkpunrin tó máa ń múra bíi obìnrin

Oríṣun àwòrán, BOBRISKY222/INSTAGRAM

Kí ọkùnrin máa ṣebí obìnrin tàbí kí obìnrin máa ṣe bíi ọkùnrin jẹ́ ohun tí àwọn ènìyàn máa korò ojú sí ní Nàìjíríà.

Ọ̀pọ̀ tilẹ̀ máa ń gbà pé ẹ̀mí àìrí kan tí kò dára ló ń bá ẹni tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ ṣiṣẹ́.

Lọ́pọ̀ ìgbà àwọn tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ máa ń gbé ara wọn pamọ́ nítorí bí wọ́n ṣe máa ń bu ẹnu àtẹ́ lù wọ́n, tí wọ́n sì máa ń gbé ara wọn pamọ́ fún ẹbí àti ọ̀rẹ́.

Bákan náà ni ìgbéyàwó láàárín akọ sí akọ tàbí abo sí abo jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó ní ìjìyà lábẹ́ òfin Nàìjíríà, ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rìnlá ni ẹni tí wọ́n bá gbámú yóò fi jura.

Àmọ́ òfin Nàìjíríà kò ní kí ọkùnrin tàbí obìnrin má múra bó ṣe wù wọ́n ìbáà ṣe wí pé ọkùnrin fẹ́ máa múra bí obìnrin tàbí obìnrin fẹ́ máa múra bíi ọkùnrin.